Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Gẹnẹsisi 12:3 - Bibeli Mimọ

3 Emi o bukun fun awọn ti nsúre fun ọ, ẹniti o nfi ọ ré li emi o si fi ré; ninu rẹ li a o ti bukun fun gbogbo idile aiye.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

3 N óo súre fún àwọn tí wọ́n bá súre fún ọ, bí ẹnikẹ́ni bá sì fi ọ́ bú, n óo fi òun náà bú. Nípasẹ̀ rẹ ni n óo bukun gbogbo ìdílé ayé.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

3 Èmi yóò bùkún fún àwọn tí ó súre fún ọ, ẹni tí ó fi ọ́ ré ni Èmi yóò fi ré; nínú rẹ ni a ó bùkún gbogbo ìdílé ayé.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Gẹnẹsisi 12:3
27 Iomraidhean Croise  

Bi iwe-mimọ́ si ti ri i tẹlẹ pe, Ọlọrun yio dá awọn Keferi lare nipa igbagbọ́, o ti wasu ihinrere ṣaju fun Abrahamu, o nwipe, Ninu rẹ li a o bukún fun gbogbo orilẹ-ède.


Ati ninu irú-ọmọ rẹ li a o bukún fun gbogbo orilẹ-ède aiye: nitori ti iwọ ti gbà ohùn mi gbọ́.


Ki enia ki o mã sìn ọ, ki orilẹ-ède ki o mã tẹriba fun ọ: mã ṣe oluwa awọn arakunrin rẹ, ki awọn ọmọ iya rẹ ki o tẹriba fun ọ: ifibú li awọn ẹniti o fi ọ bú, ibukún si ni fun awọn ẹniti o sure fun ọ.


O ba, o dubulẹ bi kiniun, ati bi abo-kiniun: tani yio lé e dide? Ibukún ni fun ẹniti o sure fun ọ, ifibú si ni ẹniti o fi ọ bú.


Emi o si mu irú-ọmọ rẹ bisi i bi irawọ oju-ọrun, emi o si fi gbogbo ilẹ wọnyi fun irú-ọmọ rẹ; ati nipasẹ irú-ọmọ rẹ li a o bukún gbogbo orilẹ-ède aiye;


Irú-ọmọ rẹ yio si ri bi erupẹ̀ ilẹ, iwọ o si tàn kalẹ si ìha ìwọ-õrùn, ati si ìha ìla-õrùn, ati si ìha ariwa, ati si ìha gusù: ninu rẹ, ati ninu irú-ọmọ rẹ li a o bukún fun gbogbo ibatan aiye.


Njẹ fun Abrahamu ati fun irú-ọmọ rẹ̀ li a ti ṣe awọn ileri na. On kò wipe, Fun awọn irú ọmọ, bi ẹnipe ọ̀pọlọpọ; ṣugbọn bi ẹnipe ọ̀kan, ati fun irú-ọmọ rẹ, eyiti iṣe Kristi.


Nitori pe, Abrahamu yio sa di orilẹ-ède nla ati alagbara, ati gbogbo orilẹ-ède aiye li a o bukun fun nipasẹ rẹ̀?


O si gbà àmi ikọla, èdidi ododo igbagbọ́ ti o ni nigbati o wà li aikọla: ki o le ṣe baba gbogbo awọn ti o gbagbọ́, bi a kò tilẹ kọ wọn ni ilà; ki a le kà ododo si wọn pẹlu:


Ṣugbọn bi iwọ o ba gbà ohùn rẹ̀ gbọ́ nitõtọ, ti iwọ si ṣe gbogbo eyiti mo wi; njẹ emi o jasi ọtá awọn ẹniti nṣe ọtá nyin, emi o si foró awọn ti nforó nyin.


Kò le si Ju tabi Hellene, ẹrú tabi omnira, ọkunrin tabi obinrin: nitoripe ọ̀kan ni gbogbo nyin jẹ ninu Kristi Jesu.


Orukọ rẹ̀ yio wà titi lai: orukọ rẹ̀ yio ma gbilẹ niwọn bi õrun yio ti pẹ to: nwọn o si ma bukún fun ara wọn nipaṣẹ rẹ̀: gbogbo awọn orilẹ-ède ni yio ma pè e li alabukúnfun.


Lẹhin na, mo ri, si kiyesi i, ọ̀pọlọpọ enia ti ẹnikẹni kò le kà, lati inu orilẹ-ède gbogbo, ati ẹya, ati enia, ati lati inu ède gbogbo wá, nwọn duro niwaju itẹ́, ati niwaju Ọdọ-Agutan na, a wọ̀ wọn li aṣọ funfun, imọ̀-ọpẹ si mbẹ li ọwọ́ wọn;


Olubukún li Ọlọrun ati Baba Jesu Kristi Oluwa wa, ẹniti o ti fi gbogbo ibukún ẹmí ninu awọn ọrun bukún wa ninu Kristi:


Ọba yio si dahùn yio si wi fun wọn pe, Lõtọ ni mo wi fun nyin, niwọn bi ẹnyin ti ṣe e fun ọkan ninu awọn arakunrin mi wọnyi ti o kere julọ ẹnyin ti ṣe e fun mi.


Labani si wipe, Duro, emi bẹ̀ ọ, bi o ba ṣepe emi ri ore-ọfẹ li oju rẹ, joko: nitori ti mo ri i pe, OLUWA ti bukún fun mi nitori rẹ.


Nibiti kò le si Hellene ati Ju, ikọla ati aikọla, alaigbede, ara Skitia, ẹrú ati omnira: ṣugbọn Kristi li ohun gbogbo, ninu ohun gbogbo.


O si ṣe lati ìgba ti o ti fi Josefu jẹ́ olori ile rẹ̀, ati olori ohun gbogbo ti o ní, ni OLUWA busi ile ara Egipti na nitori Josefu: ibukún OLUWA si wà lara ohun gbogbo ti o ní ni ile ati li oko.


Diẹ ni iwọ sá ti ní ki nto dé ọdọ rẹ, OLUWA si busi i li ọ̀pọlọpọ fun ọ lati ìgba ti mo ti dé: njẹ nisisiyi nigbawo li emi o pèse fun ile mi?


Ṣugbọn nipasẹ rẹ̀ li ẹnyin wà ninu Kristi Jesu, ẹniti Ọlọrun fi ṣe ọgbọ́n, ati ododo, ati isọdimimọ́, ati idande fun wa:


Nigbana ni yio da wọn lohun wipe, Lõtọ ni mo wi fun nyin, niwọn bi ẹnyin kò ti ṣe e fun ọkan ninu awọn ti o kere julọ wọnyi, ẹnyin kò ṣe e fun mi.


O si bẹ̀rẹ lati Mose ati gbogbo awọn woli wá, o si tumọ̀ nkan fun wọn ninu iwe-mimọ gbogbo nipa ti ara rẹ̀.


Nitoriti mo mọ̀ ọ pe, on o fi aṣẹ fun awọn ọmọ rẹ̀ ati fun awọn ara ile rẹ̀ lẹhin rẹ̀, ki nwọn ki o ma pa ọ̀na OLUWA mọ́ lati ṣe ododo ati idajọ; ki OLUWA ki o le mu ohun ti o ti sọ fun Abrahamu wá fun u.


OLUWA si ti bukún fun oluwa mi gidigidi; o si di pupọ̀: o si fun u li agutan, ati mãlu, ati fadaka, ati wurà, ati iranṣẹkunrin, ati iranṣẹbinrin, ati ibakasiẹ, ati kẹtẹkẹtẹ.


O si ṣe lẹhin ikú Abrahamu li Ọlọrun bukún fun Isaaki, ọmọ rẹ̀; Isaaki si joko leti kanga Lahai-roi.


Pe iwọ ki yio ṣe wa ni ibi, bi awa kò si ti fọwọkàn ọ, ati bi awa kò si ti ṣe ọ ni nkan bikoṣe rere, ti awa si rán ọ jade li alafia: nisisiyi ẹni-ibukún OLUWA ni iwọ.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan