Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Gẹnẹsisi 11:3 - Bibeli Mimọ

3 Nwọn si wi, ikini si ekeji pe, Ẹ wá na, ẹ jẹ ki a mọ briki, ki a si sun wọn jina. Briki ni nwọn ni li okuta, ọ̀da-ilẹ ni nwọn si nfi ṣe ọ̀rọ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

3 Wọ́n sọ fún ara wọn pé, “Ẹ jẹ́ kí á ṣe bíríkì, kí á sì sun wọ́n jiná dáradára.” Bíríkì ni wọ́n lò dípò òkúta, wọ́n sì lo ọ̀dà ilẹ̀ dípò ọ̀rọ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

3 Wọ́n sì wí fún ara wọn pé, “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a mọ bíríkì kí a sì sún wọ́n jìnà.” Bíríkì ni wọ́n ń lò ní ipò òkúta, àti ọ̀dà-ilẹ̀ tí wọn ń lò láti mú wọn papọ̀ dípò ẹfun (òkúta láìmù tí wọ́n fi ń ṣe símẹ́ńtì àti omi).

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Gẹnẹsisi 11:3
19 Iomraidhean Croise  

Nwọn si wipe, Ẹ wá na, ẹ jẹ ki a tẹ̀ ilu kan dó, ki a si mọ ile-iṣọ kan, ori eyiti yio si kàn ọrun; ki a si li orukọ, ki a má ba tuka kiri sori ilẹ gbogbo.


Ẹ wá na, ẹ jẹ ki a sọkalẹ lọ, ki a dà wọn li ède rú nibẹ̀, ki nwọn ki o máṣe gbedè ara wọn mọ́.


Afonifoji Siddimu si jẹ kìki kòto ọ̀da-ilẹ; awọn ọba Sodomu ati ti Gomorra sá, nwọn si ṣubu nibẹ̀; awọn ti o si kù sálọ si ori oke.


On si kó awọn enia na ti o wà ninu rẹ̀, o si fi wọn si iṣẹ ayùn, ati si iṣẹ nkan iwọlẹ ti a fi irin ṣe, ati si iṣẹ ãke irin, o si fi wọn si iṣẹ biriki mímọ: bẹ̃na li on si ṣe si gbogbo ilu awọn ọmọ Ammoni. Dafidi ati gbogbo awọn enia na si pada si Jerusalemu.


Nwọn gba ara wọn niyanju li ọ̀ran buburu: nwọn gbìmọ ati dẹkun silẹ nikọ̀kọ; nwọn wipe, Tani yio ri wọn?


Nwọn si fi ìsin lile, li erupẹ ati ni briki ṣiṣe, ati ni oniruru ìsin li oko mu aiye wọn korò: gbogbo ìsin wọn ti nwọn mu wọn sìn, asìnpa ni.


Nigbati kò si le pa a mọ́ mọ́, o ṣe apoti ẽsu fun u, o si fi ọ̀da ilẹ ati oje igi ṣán a; o si tẹ́ ọmọ na sinu rẹ̀; o si gbé e sinu koriko odò li ẹba odò na.


Bi nwọn wipe, Wá pẹlu wa, jẹ ki a ba fun ẹ̀jẹ, jẹ ki a lugọ ni ikọkọ de alaiṣẹ̀ lainidi.


EMI wi ninu mi pe, wá na! emi o fi iré-ayọ̀ dan ọ wò, nitorina mã jẹ afẹ! si kiyesi i, asan li eyi pẹlu!


Njẹ nisisiyi, ẹ wá na, emi o sọ ohun ti emi o ṣe si ọ̀gba àjara mi fun nyin: emi o mu ọ̀gba rẹ̀ kuro, a o si jẹ ẹ run, emi o wo ogiri rẹ̀ lu ilẹ, a o si tẹ̀ ẹ mọlẹ.


Awọn enia ti o nṣọ́ mi ni inu nigbagbogbo kàn mi loju; ti nrubọ ninu agbàla, ti nwọn si nfi turari jona lori pẹpẹ briki.


Briki wọnni ṣubu lu ilẹ, ṣugbọn awa o fi okuta gbigbẹ́ mọ ọ: a ke igi sikamore lu ilẹ, ṣugbọn a o fi igi kedari pãrọ wọn.


Iwọ pọn omi de ihamọ, mu ile iṣọ rẹ le: wọ̀ inu amọ̀, ki o si tẹ̀ erupẹ̀, ki o si ṣe ibiti a nsun okuta-amọ̀ ki o le.


Ẹ jẹ ki a yẹ ara wa wo lati rú ara wa si ifẹ ati si iṣẹ rere:


Ṣugbọn ẹ mã gbà ara nyin niyanju li ojojumọ́, niwọn igbati a ba npè e ni Oni, ki a má bã sé ọkàn ẹnikẹni ninu nyin le nipa ẹ̀tan ẹ̀ṣẹ.


Ẹ wá nisisiyi, ẹnyin tí nwipe, Loni tabi lọla awa ó lọ si ilu bayi, a o si ṣe ọdún kan nibẹ, a o si ṣòwo, a o si jère:


Ẹ wá nisisiyi, ẹnyin ọlọrọ̀, ẹ mã sọkun ki ẹ si mã pohunréré ẹkun nitori òṣi ti mbọ̀wá ta nyin.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan