Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Gẹnẹsisi 10:2 - Bibeli Mimọ

2 Awọn ọmọ Jafeti; Gomeri, ati Magogu, ati Madai, ati Jafani, ati Tubali, ati Meṣeki, ati Tirasi.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

2 Àwọn ọmọ Jafẹti ni: Gomeri, Magogu, Madai, Jafani, Tubali, Meṣeki ati Tirasi.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

2 Àwọn ọmọ Jafeti ni: Gomeri, Magogu, Madai, Jafani, Tubali, Meṣeki àti Tirasi.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Gẹnẹsisi 10:2
16 Iomraidhean Croise  

IRAN awọn ọmọ Noa ni wọnyi, Ṣemu, Hamu, ati Jafeti: ati fun wọn li a si bí ọmọ lẹhin kíkun-omi.


Fun Ṣemu pẹlu, baba gbogbo awọn ọmọ Eberi, ẹgbọn Jafeti ati fun on li a bimọ.


Ọlọrun yio mu Jafeti gbilẹ, yio si ma gbé agọ́ Ṣemu; Kenaani yio si ma ṣe iranṣẹ wọn.


Li ọdun kẹsan Hoṣea, ni ọba Assiria kó Samaria, o si kó Israeli lọ si Assiria, o si fi wọn si Hala ati si Habori, leti odò Gosani, ati si ilu awọn ara Media.


Egbe ni fun mi, ti mo ṣe atipo ni Meṣeki, ti mo joko ninu agọ Kedari!


Emi o si fi àmi kan si ãrin wọn, emi o si rán awọn ti o salà ninu wọn si awọn orilẹ-ède, si Tarṣiṣi, Puli, ati Ludi, awọn ti nfà ọrun, si Tubali, on Jafani, si awọn erekuṣu ti o jina rére, ti nwọn kò ti igbọ́ okiki mi, ti nwọn kò si ti iri ogo mi; nwọn o si rohin ogo mi lãrin awọn Keferi.


Dani pẹlu ati Jafani lati Usali ngbé ọjà rẹ: irin didán, kassia, ati kalamu wà li ọjà rẹ.


Ọ̀gbọ daradara iṣẹ-ọnà lati Egipti wá li eyiti iwọ ta fi ṣe igbokun rẹ; aṣọ aláro ati purpili lati erekusu Eliṣa wá li eyiti a fi bò ọ.


Meṣeki ati Tubali wà nibẹ, ati gbogbo ọ̀pọlọpọ enia rẹ̀: awọn ibojì rẹ̀ yi i ka: gbogbo wọn alaikọlà ti a fi idà pa, bi nwọn tilẹ dá ẹ̀ru wọn silẹ ni ilẹ alãye.


Iwọ o si ti ipò rẹ wá lati iha ariwa, iwọ, ati ọ̀pọ enia pẹlu rẹ, gbogbo wọn li o ngùn ẹṣin, ẹgbẹ nla, ati ọ̀pọlọpọ ogun alagbara:


Ọmọ enia, kọ oju rẹ si Gogu, ilẹ Magogu, olori Roṣi, Meṣeki, ati Tubali, si sọtẹlẹ si i,


Gomeri, ati gbogbo ogun rẹ̀; ile Togarma ti ihà ariwa, ati gbogbo ogun rẹ̀: enia pupọ̀ pẹlu rẹ̀.


NITORINA, iwọ ọmọ enia, sọtẹlẹ si Gogu, si wipe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Kiye si i, emi dojukọ́ ọ, iwọ Gogu, olori ọmọ-alade Meṣeki ati Tubali:


Yio si jade lọ lati mã tàn awọn orilẹ-ède ti mbẹ ni igun mẹrẹrin aiye jẹ, Gogu ati Magogu, lati gbá wọn jọ si ogun: awọn ti iye wọn dabi iyanrìn okun.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan