Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Gẹnẹsisi 1:7 - Bibeli Mimọ

7 Ọlọrun si ṣe ofurufu, o si yà omi ti o wà nisalẹ ofurufu kuro lara omi ti o wà loke ofurufu: o si ri bẹ̃.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

7 Ọlọrun dá awọsanma, ó fi ya omi tí ó wà lábẹ́ rẹ̀ kúrò lára èyí tí ó wà lókè rẹ̀, ó sì rí bẹ́ẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

7 Ọlọ́run sì dá òfúrufú láti ya omi tí ó wà ní òkè òfúrufú kúrò lára omi tí ó wà ní orí ilẹ̀. Ó sì rí bẹ́ẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Gẹnẹsisi 1:7
15 Iomraidhean Croise  

Ọlọrun si wipe, Ki ilẹ ki o hù oko, eweko ti yio ma so eso, ati igi eleso ti yio ma so eso ni irú tirẹ̀, ti o ni irugbin ninu lori ilẹ: o si ri bẹ̃.


Ki nwọn ki o si jẹ́ imọlẹ li ofurufu ọrun, lati mọlẹ sori ilẹ: o si ri bẹ̃.


Ọlọrun si wipe, Ki ilẹ ki o mu ẹdá alãye ni irú rẹ̀ jade wá, ẹran-ọ̀sin, ati ohun ti nrakò, ati ẹranko ilẹ ni irú rẹ̀: o si ri bẹ̃.


Ọlọrun si pè ofurufu ni Ọrun. Ati aṣalẹ ati owurọ̀ o di ọjọ́ keji.


Ọlọrun si wipe, Ki omi abẹ ọrun ki o wọjọ pọ̀ si ibi kan, ki iyangbẹ ilẹ ki o si hàn: o si ri bẹ̃.


O di omiyomi pọ̀ ninu awọsanma rẹ̀ ti o nipọn; awọsanma kò si ya nisalẹ wọn.


Iwọ ran orisun si afonifoji, ti nṣàn larin awọn òke.


Fun ẹniti o fi ọgbọ́n da ọrun: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai.


Ẹ fi iyìn fun u, ẹnyin ọrun awọn ọrun, ati ẹnyin omi ti mbẹ loke ọrun.


AWỌN ọrun nsọ̀rọ ogo Ọlọrun; ati ofurufu nfi iṣẹ ọwọ rẹ̀ han.


Ọjọ de ọjọ nfọhùn, ati oru de oru nfi ìmọ hàn.


Bi awọsanma ba kún fun òjo, nwọn a si tu dà si aiye: bi igi ba si wó sìha gusu tabi siha ariwa, nibiti igi na gbe ṣubu si, nibẹ ni yio si ma gbe.


Ṣugbọn ẹnu yà awọn ọkunrin na, nwọn wipe, Irú enia wo li eyi, ti afẹfẹ ati omi okun gbọ tirẹ̀?


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan