Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Gẹnẹsisi 1:1 - Bibeli Mimọ

1 Ní atetekọṣe Ọlọrun dá ọrun ati aiye.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

1 Ní ìbẹ̀rẹ̀, nígbà tí Ọlọrun dá ọ̀run ati ayé,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

1 Ní ìbẹ̀rẹ̀ ohun gbogbo Ọlọ́run dá àwọn ọ̀run àti ayé.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Gẹnẹsisi 1:1
67 Iomraidhean Croise  

Hesekiah si gbadura niwaju Oluwa, o si wipe: Oluwa Ọlọrun Israeli, ti ngbe ãrin awọn kerubu, iwọ li Ọlọrun, ani iwọ nikanṣoṣo, ninu gbogbo awọn ilẹ-ọba aiye; iwọ li o dá ọrun on aiye.


Nitori pe gbogbo oriṣa awọn enia, ere ni nwọ́n: ṣugbọn Oluwa li o da awọn ọrun.


Nigbana ni Huramu, ọba Tire, kọwe dahùn o si ranṣẹ si Solomoni pe, Nitori ti Oluwa fẹran awọn enia rẹ̀ li o ṣe fi ọ jọba lori wọn.


Iwọ, ani iwọ nikanṣoṣo li Oluwa; iwọ li o ti dá ọrun, ọrun awọn ọrun pẹlu gbogbo ogun wọn, aiye, ati ohun gbogbo ti mbẹ ninu rẹ̀, okun, ati ohun gbogbo ti mbẹ̀ ninu rẹ̀, iwọ si pa gbogbo wọn mọ́ lãyè, ogun ọrun si nsìn ọ.


Nipa ẹmi rẹ li o ti ṣe ọrun li ọ̀ṣọ, ọwọ rẹ̀ li o ti da ejo-wiwọ́ nì.


Nibo ni iwọ wà nigbati mo fi ipilẹ aiye sọlẹ? wi bi iwọ ba moye!


On nikanṣoṣo li o na oju ọrun lọ, ti o si nrìn lori ìgbì okun.


Lati igba atijọ ni iwọ ti fi ipilẹ aiye sọlẹ: ọrun si ni iṣẹ ọwọ rẹ,


Oluwa, iṣẹ rẹ ti pọ̀ to! ninu ọgbọ́n ni iwọ ṣe gbogbo wọn: aiye kún fun ẹ̀da rẹ.


Iwọ rán ẹmi rẹ jade, a si da wọn: iwọ si sọ oju ilẹ di ọtun.


Ẹnyin li ẹni-ibukún Oluwa, ti o da ọrun on aiye.


Iranlọwọ mi yio ti ọwọ Oluwa wá, ti o da ọrun on aiye.


Iranlọwọ wa mbẹ li orukọ Oluwa, ti o da ọrun on aiye.


Oluwa ti o da ọrun on aiye, ki o busi i fun ọ lati Sioni wá.


Fun ẹniti o fi ọgbọ́n da ọrun: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai.


Ẹniti o da ọrun on aiye, okun ati ohun ti o wà ninu wọn: ẹniti o pa otitọ mọ́ titi aiye:


Nipa ọ̀rọ Oluwa li a da awọn ọrun, ati gbogbo ogun wọn nipa ẽmí ẹnu rẹ̀.


Nitori ti o sọ̀rọ, o si ti ṣẹ; o paṣẹ, o si duro ṣinṣin.


Nigbati mo rò ọrun rẹ, iṣẹ ika rẹ, oṣupa ati irawọ, ti iwọ ti ṣe ilana silẹ.


Kili enia, ti iwọ fi nṣe iranti rẹ̀? ati ọmọ enia, ti iwọ fi mbẹ̀ ẹ wò.


Ki a to bí awọn òke nla, ati ki iwọ ki o to dá ilẹ on aiye, ani lati aiye-raiye, iwọ li Ọlọrun.


Nitori pe gbogbo oriṣa orilẹ-ède asan ni nwọn: ṣugbọn Oluwa li o da ọrun.


Nitori ni ijọ́ mẹfa li OLUWA dá ọrun on aiye, okun ati ohun gbogbo ti mbẹ ninu wọn, o si simi ni ijọ́ keje: nitorina li OLUWA ṣe busi ijọ́ keje, o si yà a si mimọ́.


O si fi walã ẹrí meji, walã okuta, ti a fi ika Ọlọrun kọ, fun Mose, nigbati o pari ọ̀rọ bibá a sọ tán lori oke Sinai.


Oluwa ti ṣe ohun gbogbo fun ipinnu rẹ̀: nitõtọ, awọn enia buburu fun ọjọ ibi.


Ọgbọ́n li Oluwa fi fi idi aiye sọlẹ, oye li o si fi pese awọn ọrun.


RANTI ẹlẹda rẹ nisisiyi li ọjọ ewe rẹ, nigbati ọjọ ibi kò ti ide, ati ti ọdun kò ti isunmọ etile, nigbati iwọ o wipe, emi kò ni inudidùn ninu wọn;


Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli, ti ngbe ãrin awọn kerubu, iwọ li Ọlọrun, ani iwọ nikan, ninu gbogbo ijọba aiye: iwọ li o dá ọrun on aiye.


Ẹnyin kò ti mọ̀? ẹnyin kò ti gbọ́? a kò ti sọ fun nyin li atètekọṣe? kò iti yé nyin lati ipilẹṣẹ aiye wá?


Gbe oju nyin soke sibi giga, ki ẹ si wò, tali o dá nkan wọnyi, ti nmu ogun wọn jade wá ni iye: o npè gbogbo wọn li orukọ nipa titobi ipá rẹ̀, nitoripe on le ni ipá; kò si ọkan ti o kù.


Iwọ kò ti imọ? iwọ kò ti igbọ́ pe, Ọlọrun aiyeraiye, Oluwa, Ẹlẹda gbogbo ipẹkun aiye, kì iṣãrẹ̀, bẹ̃ni ãrẹ̀ kì imu u? kò si awari oye rẹ̀.


Bayi ni Ọlọrun Oluwa wi, ẹniti o dá ọrun, ti o si nà wọn jade; ẹniti o tẹ̀ aiye, ati ohun ti o ti inu rẹ̀ wá; ẹniti o fi ẽmi fun awọn enia lori rẹ̀, ati ẹmi fun awọn ti o nrin ninu rẹ̀:


Bayi ni Oluwa, Olurapada rẹ wi, ati ẹniti o mọ ọ lati inu wá: emi li Oluwa ti o ṣe ohun gbogbo; ti o nikan nà awọn ọrun; ti mo si tikara mi tẹ́ aiye.


Nitori bayi li Oluwa wi, ẹniti o dá awọn ọrun; Ọlọrun tikararẹ̀ ti o mọ aiye, ti o si ṣe e; o ti fi idi rẹ̀ mulẹ, kò da a lasan, o mọ ọ ki a le gbe inu rẹ̀: Emi ni Oluwa; ko si ẹlomiran.


Ti iwọ si gbagbe Oluwa Elẹda rẹ ti o ti nà awọn ọrun, ti o si ti fi ipilẹ aiye sọlẹ; ti iwọ si ti mbẹ̀ru nigbagbogbo lojojumọ nitori irúnu aninilara nì, bi ẹnipe o ti mura lati panirun? nibo ni irúnu aninilara na ha gbe wà?


Emi si ti fi ọ̀rọ mi si ẹnu rẹ, mo si ti bò ọ mọlẹ ni ojiji ọwọ́ mi, ki emi ki o le gbìn awọn ọrun, ki emi si le fi ipilẹ aiye sọlẹ, ati ki emi le wi fun Sioni pe, Iwọ ni enia mi.


Sa wò o, emi o da ọrun titun ati aiye titun: a kì yio si ranti awọn ti iṣaju, bẹ̃ni nwọn kì yio wá si aiya.


On ti da aiye nipa agbara rẹ̀, on ti pinnu araiye nipa ọgbọ́n rẹ̀, o si nà awọn ọrun nipa oye rẹ̀.


A! Oluwa Ọlọrun! wò o, iwọ ti o da ọrun on aiye nipa agbara nla rẹ ati ninà apa rẹ: kò si ohun-kohun ti o ṣoro fun ọ.


On ti da aiye nipa agbara rẹ̀, on ti ṣe ipinnu araiye nipa ọgbọ́n rẹ̀, o si tẹ́ awọn ọrun nipa oye rẹ̀.


Ọ̀RỌ-ÌMỌ ọ̀rọ Oluwa fun Israeli, li Oluwa wi, ẹni ti o nnà awọn ọrun, ti o si fi ipilẹ aiye sọlẹ, ti o si mọ ẹmi enia ti mbẹ ni inu rẹ̀.


Lakokò na ni Jesu dahùn, o si wipe, Mo dupẹ lọwọ rẹ Baba, Oluwa ọrun on aiye, nitoriti iwọ pa nkan wọnyi mọ́ kuro li oju awọn ọlọ́gbọn ati amoye, iwọ si fi wọn hàn fun awọn ọmọ-ọwọ́.


Nitori ọjọ wọnni, yio jẹ ọjọ ipọnju irú eyi ti kò si lati igba ọjọ ìwa ti Ọlọrun da, titi fi di akokò yi, irú rẹ̀ ki yio si si.


Nwọn si nwipe, Ará, ẽṣe ti ẹnyin fi nṣe nkan wọnyi? Enia oniru ìwa kanna bi ẹnyin li awa pẹlu ti a nwasu ihinrere fun nyin, ki ẹnyin ki o yipada kuro ninu ohun asan wọnyi si Ọlọrun alãye, ti o da ọrun on aiye, ati okun, ati ohun gbogbo ti mbẹ ninu wọn:


Ọlọrun na ti o da aiye ati ohun gbogbo ti mbẹ ninu rẹ̀, on na ti iṣe Oluwa ọrun on aiye, kì igbé ile ti a fi ọwọ́ kọ́;


Nigbati nwọn si gbọ́, nwọn fi ọkàn kan gbé ohùn wọn soke si Ọlọrun nwọn si wipe, Oluwa, ìwọ ti o da ọrun on aiye, ati okun, ati ohun gbogbo ti mbẹ ninu wọn:


Nitori lati ọdọ rẹ̀, ati nipa rẹ̀, ati fun u li ohun gbogbo: ẹniti ogo wà fun lailai. Amin.


Ṣugbọn fun awa Ọlọrun kan ni mbẹ, Baba, lọwọ ẹniti ohun gbogbo ti wá, ati ti ẹniti gbogbo wa iṣe; ati Oluwa kanṣoṣo Jesu Kristi, nipasẹ ẹniti ohun gbogbo wà, ati awa nipasẹ rẹ̀.


Ati lati mu ki gbogbo enia ri kini iṣẹ-iriju ohun ijinlẹ na jasi, eyiti a ti fi pamọ́ lati aiyebaiye ninu Ọlọrun, ẹniti o dá ohun gbogbo nipa Jesu Kristi:


Ati Iwọ, Oluwa, li atetekọṣe li o ti fi ipilẹ aiye sọlẹ; awọn ọrun si ni iṣẹ ọwọ́ rẹ:


Ni ikẹhin ọjọ wọnyi o ti ipasẹ Ọmọ rẹ̀ ba wa sọ̀rọ, ẹniti o fi ṣe ajogun ohun gbogbo, nipasẹ ẹniti o dá awọn aiye pẹlu;


Nipa igbagbọ́ li a mọ̀ pe a ti da aiye nipa ọ̀rọ Ọlọrun; nitorina ki iṣe ohun ti o hàn li a fi dá ohun ti a nri.


Lati ọwọ́ enia kan li a sá ti kọ́ olukuluku ile; ṣugbọn ẹniti o kọ́ ohun gbogbo ni Ọlọrun.


Nitori eyi ni nwọn mọ̃mọ ṣe aifẹ̃mọ, pe nipa ọ̀rọ Ọlọrun li awọn ọrun ti wà lati ìgba atijọ, ati ti ilẹ yọri jade ninu omi, ti o si duro ninu omi:


EYITI o ti wà li àtetekọṣe, ti awa ti gbọ́, ti awa ti fi oju wa ri, ti awa si ti tẹjumọ, ti ọwọ́ wa si ti dìmu, niti Ọrọ ìye;


O si fi ẹniti mbẹ lãye lai ati lailai búra, ẹniti o dá ọrun, ati ohun ti mbẹ ninu rẹ̀, ati ilẹ aiye, ati ohun ti mbẹ ninu rẹ̀, ati okun, ati ohun ti mbẹ ninu rẹ̀, pe ìgba kì yio si mọ́:


O nwi li ohùn rara pe, Ẹ bẹ̀ru Ọlọrun, ki ẹ si fi ogo fun u; nitoriti wakati idajọ rẹ̀ de: ẹ si foribalẹ fun ẹniti o dá ọrun, on aiye, ati okun, ati awọn orisun omi.


O si wi fun mi pe, O pari. Emi ni Alfa ati Omega, ipilẹṣẹ ati opin. Emi ó si fi omi fun ẹniti ongbẹ ngbẹ lati orisun omi ìye lọfẹ̃.


Emi ni Alfa ati Omega, ẹni iṣaju ati ẹni ikẹhin, ipilẹṣẹ̀ ati opin.


Ati si angẹli ijọ ni Laodikea kọwe: Nkan wọnyi li ẹniti ijẹ Amin wi, ẹlẹri olododo ati olõtọ, olupilẹṣẹ ẹda Ọlọrun.


Oluwa, iwọ li o yẹ lati gbà ogo ati ọlá ati agbara: nitoripe iwọ li o dá ohun gbogbo, ati nitori ifẹ inu rẹ ni nwọn fi wà ti a si dá wọn.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan