Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Filipi 4:3 - Bibeli Mimọ

3 Mo si bẹ ọ pẹlu, bi alajọru-ajaga mi tõtọ, ran awọn obinrin wọnni lọwọ, nitori nwọn mba mi ṣiṣẹ pọ̀ ninu ihinrere, ati Klementi pẹlu, ati awọn olubaṣiṣẹ mi iyoku pẹlu, orukọ awọn ti mbẹ ninu iwe ìye.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

3 Bẹ́ẹ̀ ni mo bẹ ìwọ náà, ẹlẹgbẹ́ mi tòótọ́, ran àwọn obinrin wọnyi lọ́wọ́, nítorí wọ́n ti bá mi ṣiṣẹ́ pọ̀ ninu iṣẹ́ ìtànkálẹ̀ ìyìn rere pẹlu Kilẹmẹnti ati gbogbo olùbáṣiṣẹ́ mi yòókù, àwọn tí orúkọ wọn wà ninu ìwé ìyè.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

3 Mo sì bẹ̀ yin pẹ̀lú bí alájọru àjàgà mi tòótọ́, ran àwọn obìnrin wọ̀nyí lọ́wọ́, nítorí wọn bá mi ṣiṣẹ́ pọ̀ ní ìfẹ̀gbẹ́-kẹ̀gbẹ́ nínú ìhìnrere, àti Klementi pẹ̀lú, àti àwọn olùbáṣiṣẹ́ mi yòókù pẹ̀lú, orúkọ àwọn tí ń bẹ nínú ìwé ìyè.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Filipi 4:3
28 Iomraidhean Croise  

Nù wọn kuro ninu iwe awọn alãye, ki a má si kọwe wọn pẹlu awọn olododo.


Nisisiyi, bi iwọ o ba dari ẹ̀ṣẹ wọn jì wọn; bi bẹ̃ si kọ, emi bẹ̀ ọ, pa mi rẹ́ kuro ninu iwé rẹ ti iwọ ti kọ.


Yio si ṣe, pe, ẹniti a fi silẹ ni Sioni, ati ẹniti o kù ni Jerusalemu, li a o pè ni mimọ́, ani orukọ olukuluku ẹniti a kọ pẹlu awọn alãye ni Jerusalemu.


Ọwọ́ mi yio si wà lori awọn woli, ti nwọn ri asan, ti nwọn si nfọ àfọṣẹ eke; nwọn kì yio si ninu ijọ awọn enia mi, bẹ̃ni a kì yio kọwe wọn sinu iwe ile Israeli; bẹ̃ni nwọn kì yio wọ̀ ilẹ Israeli, ẹnyin o si mọ̀ pe emi li Oluwa.


LI akoko na ni Mikaeli, balogun nla nì, ti yio gbeja awọn ọmọ awọn enia rẹ yio dide, akokò wahala yio si wà, iru eyi ti kò ti isi ri, lati igba ti orilẹ-ède ti wà titi fi di igba akokò yi, ati ni igba akokò na li a o gbà awọn enia rẹ la, ani gbogbo awọn ti a ti kọ orukọ wọn sinu iwe.


Ṣugbọn ki ẹ máṣe yọ̀ si eyi, pe, awọn ẹmi nforibalẹ fun nyin; ṣugbọn ẹ kuku yọ̀, pe, a kọwe orukọ nyin li ọrun.


NITORINA mo fi iyọ́nu Ọlọrun bẹ̀ nyin, ará, ki ẹnyin ki o fi ara nyin fun Ọlọrun li ẹbọ ãye, mimọ́, itẹwọgbà, eyi ni iṣẹ-isìn nyin ti o tọ̀na.


Ẹ kí Trifena ati Trifosa, awọn ẹniti nṣe lãlã ninu Oluwa. Ẹ kí Persi olufẹ, ti o nṣe lãlã pipọ ninu Oluwa.


Ẹ kí Urbani, alabaṣiṣẹ wa ninu Kristi, ati Staki olufẹ mi.


Njẹ emi fẹ ki ẹnyin ki o mọ̀, ará, pe nkan wọnni ti o de bá mi, o kuku yọri si ilọsiwaju ihinrere;


Awọn kan nfi ìja wasu Kristi, kì iṣe pẹlu õtọ inu, nwọn ngbèro lati fi ipọnju kún ìde mi:


Kìki ki ẹ sá jẹ ki ìwa-aiye nyin ki o mã ri gẹgẹ bi ihinrere Kristi: pe yala bi mo tilẹ wá wò nyin, tabi bi emi kò si, ki emi ki o le mã gburó bi ẹ ti nṣe, pe ẹnyin duro ṣinṣin ninu Ẹmí kan, ẹnyin jùmọ njijakadi nitori igbagbọ́ ihinrere, pẹlu ọkàn kan;


Nitori ìdapọ nyin ninu ihinrere lati ọjọ kini wá titi fi di isisiyi.


Gẹgẹ bi o ti tọ́ fun mi lati rò eyi fun gbogbo nyin, nitoriti ọkàn nyin wà lọdọ mi, niwọn bi o ti ṣepe gbogbo nyin ni iṣe alabapin ore-ọfẹ pẹlu mi ninu idè mi ati ninu idahùn-ẹjọ mi ati ifẹsẹmulẹ ihinrere.


Emi mbẹ̀ Euodia, mo si mbẹ̀ Sintike, ki nwọn ni inu kanna ninu Oluwa.


Ani bi ẹnyin ti kọ́ lọdọ Epafra iranṣẹ ẹlẹgbẹ wa olufẹ, ẹniti iṣe olõtọ iranṣẹ Kristi nipo wa,


Gbogbo awọn ti ngbe ori ilẹ aiye yio si mã sin i, olukuluku ẹniti a kò kọ orukọ rẹ̀ sinu iwe iyè Ọdọ-Agutan ti a ti pa lati ipilẹṣẹ aiye.


Ẹranko ti iwọ ri nì, o ti wà, kò si sí mọ́: yio si ti inu ọgbun gòke wá, yio si lọ sinu egbé: ẹnu yio si yà awọn ti ngbé ori ilẹ aiye, orukọ awọn ẹniti a kò ti kọ sinu iwe ìye lati ipilẹṣẹ aiye, nigbati nwọn nwò ẹranko ti o ti wà, ti kò si sí mọ́, ti o si mbọ̀wá.


Mo si ri awọn okú, ati ewe ati àgba, nwọn duro niwaju itẹ; a si ṣi awọn iwe silẹ; a si ṣí awọn iwe miran kan silẹ ti iṣe iwe ìye: a si ṣe idajọ fun awọn okú lati inu ohun ti a ti kọ sinu awọn iwe na, gẹgẹ bi iṣẹ wọn.


Bi a ba si ri ẹnikẹni ti a kò kọ orukọ rẹ̀ sinu iwe ìye, a sọ ọ sinu adagun iná.


Ohun alaimọ́ kan kì yio si wọ̀ inu rẹ̀ rara, tabi ohun ti nṣiṣẹ irira ati eke; bikoṣe awọn ti a kọ sinu iwe ìye Ọdọ-Agutan.


Ẹniti o ba ṣẹgun, on na li a o fi aṣọ funfun wọ̀; emi kì yio pa orukọ rẹ̀ rẹ́ kuro ninu iwe ìye, ṣugbọn emi o jẹwọ orukọ rẹ̀ niwaju Baba mi, ati niwaju awọn angẹli rẹ̀.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan