Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Filipi 2:3 - Bibeli Mimọ

3 Ẹ máṣe fi ìja tabi ogo asan ṣe ohunkohun: ṣugbọn ni irẹlẹ ọkàn ki olukuluku ro awọn ẹlomiran si ẹniti o san ju on tikararẹ̀ lọ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

3 Ẹ má ṣe ohunkohun pẹlu ẹ̀mí àṣehàn tabi láti gba ìyìn eniyan, ṣugbọn pẹlu ọkàn ìrẹ̀lẹ̀, ẹ máa fi ẹnìkejì yín ṣiwaju ara yín.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

3 Ẹ má ṣe ohunkóhun nínú ìlépa ara tàbí ògo asán, ṣùgbọ́n ní ìrẹ̀lẹ̀ ọkàn kí olúkúlùkù ro àwọn ẹlòmíràn sí ẹni ti ó sàn ju òun lọ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Filipi 2:3
24 Iomraidhean Croise  

Nipa kiki igberaga ni ìja ti iwá; ṣugbọn lọdọ awọn ti a fi ìmọ hàn li ọgbọ́n wà.


Mo wi fun nyin, ọkunrin yi sọkalẹ lọ si ile rẹ̀ ni idalare jù ekeji lọ: nitori ẹnikẹni ti o ba gbé ara rẹ̀ ga, on li a o rẹ̀ silẹ; ẹniti o ba si rẹ̀ ara rẹ̀ silẹ on li a o gbéga.


Niti ifẹ ará, ẹ mã fi iyọ́nu fẹran ara nyin: niti ọlá, ẹ mã fi ẹnikeji nyin ṣaju.


Jẹ ki a mã rìn ìrin titọ, bi li ọsán; kì iṣe ni iréde-oru ati ni imutipara, kì iṣe ni iwa-ẽri ati wọbia, kì iṣe ni ìja ati ilara.


Ṣugbọn fun awọn onijà, ti nwọn kò si gbà otitọ gbọ́, ṣugbọn ti nwọn ngbà aiṣododo gbọ́, irunu ati ibinu yio wà.


Nitori emi li ẹniti o kere jùlọ ninu awọn Aposteli, emi ẹniti kò yẹ ti a ba pè li Aposteli, nitoriti mo ṣe inunibini si ijọ enia Ọlọrun.


Nitori ẹnyin jẹ ti ara sibẹ: nitori niwọnbi ilara ati ìja ati ìyapa ba wà larin nyin, ẹnyin kò ha jẹ ti ara ẹ kò ha si nrìn gẹgẹ bi enia?


Nitori ẹru mba mi pe, nigbati mo ba de, emi kì yio bá nyin gẹgẹ bi irú eyi ti mo fẹ, ati pe ẹnyin ó si ri mi gẹgẹ bi irú eyi ti ẹnyin kò fẹ: ki ija, owu-jijẹ, ibinu, ipinya, isọrọ-ẹni-lẹhin, ijirọsọ, igberaga, irukerudo, ki o má ba wà:


Ṣugbọn bi ẹnyin ba mbù ara nyin ṣán, ti ẹ si njẹ ara nyin run, ẹ kiyesara ki ẹ máṣe pa ara nyin run.


Ẹ máṣe jẹ ki a mã ṣogo-asan, ki a má mu ọmọnikeji wa binu, ki a má ṣe ilara ọmọnikeji wa.


Pẹlu irẹlẹ gbogbo ati inu tutù, pẹlu ipamọra, ẹ mã fi ifẹ farada a fun ẹnikeji nyin;


Ẹ mã tẹriba fun ara nyin ni ìbẹru Ọlọrun.


Ẹ mã ṣe ohun gbogbo li aisi ikùnsinu ati ijiyan.


Nitorina, bi ayanfẹ Ọlọrun, ẹni mimọ́ ati olufẹ, ẹ gbé ọkàn ìyọ́nu wọ̀, iṣeun, irẹlẹ, inu tutù, ipamọra;


Ṣugbọn nisisiyi, ẹ fi gbogbo wọnyi silẹ pẹlu; ibinu, irunu, arankàn, ọrọ-odi, ati ọrọ itiju kuro li ẹnu nyin.


O gberaga, kò mọ nkan kan, bikoṣe ifẹ iyan-jija ati ìja-ọ̀rọ ninu eyiti ilara, ìya, ọrọ buburu ati iro buburu ti iwá,


Lakotan, ki gbogbo nyin ṣe oninu kan, ẹ mã ba ará nyin kẹdun, ẹ ni ifẹ ará, ẹ mã ṣe ìyọnú, ẹ ni ẹmí irẹlẹ.


Bẹ̃ pẹlu, ẹnyin ipẹ̃rẹ, ẹ tẹriba fun awọn àgba. Ani, gbogbo nyin, ẹ mã tẹriba fun ara nyin, ki ẹ si fi irẹlẹ wọ̀ ara nyin li aṣọ: nitori Ọlọrun kọ oju ija si awọn agberaga, ṣugbọn O nfi ore-ọfẹ fun awọn onirẹlẹ.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan