Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Filemoni 1:9 - Bibeli Mimọ

9 Ṣugbọn nitori ifẹ emi kuku bẹ̀bẹ, iru ẹni bi emi Paulu arugbo, ati nisisiyi ondè Kristi Jesu pẹlu.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

9 ṣugbọn nítorí ìfẹ́ tí ó wà láàrin wa, ẹ̀bẹ̀ ni n óo kúkú bẹ̀. Èmi Paulu, ikọ̀ Kristi, tí mo di ẹlẹ́wọ̀n nisinsinyii nítorí ti Kristi Jesu,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

9 Síbẹ̀ nítorí ìfẹ́ èmí kúkú bẹ̀ ọ́. Èmi gẹ́gẹ́ bí Paulu, arúgbó, àti nísinsin yìí òǹdè Jesu Kristi.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Filemoni 1:9
17 Iomraidhean Croise  

Pẹlupẹlu, nigbati emi di arugbo tan ti mo hewu, Ọlọrun máṣe kọ̀ mi; titi emi o fi fi ipá rẹ hàn fun iran yi, ati agbara rẹ fun gbogbo awọn ara ẹ̀hin.


Máṣe ṣa mi ti ni ìgba ogbó; máṣe kọ̀ mi silẹ nigbati agbara mi ba yẹ̀.


Ade ogo li ori ewú, bi a ba ri i li ọ̀na ododo.


Ani titi de ogbó emi na ni; ani titi de ewú li emi o rù nyin; emi ti ṣe e, emi o si gbe, nitõtọ emi o rù, emi o si gbàla.


NITORINA mo fi iyọ́nu Ọlọrun bẹ̀ nyin, ará, ki ẹnyin ki o fi ara nyin fun Ọlọrun li ẹbọ ãye, mimọ́, itẹwọgbà, eyi ni iṣẹ-isìn nyin ti o tọ̀na.


Nitorina awa ni ikọ̀ fun Kristi, bi ẹnipe Ọlọrun nti ọdọ wa ṣipẹ fun nyin: awa mbẹ̀ nyin nipò Kristi, ẹ ba Ọlọrun làja.


NJẸ bi alabaṣiṣẹpọ pẹlu rẹ̀, awa mbẹ̀ nyin ki ẹ máṣe gbà ore-ọfẹ Ọlọrun lasan.


Nitoripe ọmọ Ọlọrun ni gbogbo nyin, nipa igbagbọ́ ninu Kristi Jesu.


NITORI eyina, emi Paulu, ondè Jesu Kristi nitori ẹnyin Keferi,


NITORINA emi ondè ninu Oluwa, mbẹ̀ nyin pe, ki ẹnyin ki o mã rìn bi o ti yẹ fun ìpe na ti a fi pè nyin,


Nitori eyiti emi jẹ ikọ̀ ninu ẹ̀wọn: ki emi ki o le mã fi igboiya sọ̀rọ ninu rẹ̀, gẹgẹ bi o ti tọ́ fun mi lati mã sọ.


Mo dupẹ lọwọ Ẹniti o fun mi li agbara, ani Kristi Jesu Oluwa wa, nitoriti o kà mi si olõtọ ni yiyan mi si iṣẹ rẹ̀;


Ki awọn àgba ọkunrin jẹ ẹni iwọntunwọnsin, ẹni-ọ̀wọ, alairekọja, ẹniti o yè kõro ni igbagbọ́, ni ifẹ, ni sũru.


Ṣugbọn emi mbẹ̀ nyin gidigidi si i lati mã ṣe eyi, ki a ba le tète fi mi fun nyin pada.


Olufẹ, mo bẹ̀ nyin, bi alejò ati bi èro, lati fà sẹhin kuro ninu ifẹkufẹ ara, ti mba ọkàn jagun;


Yio si ṣe, nigbati awọn baba wọn tabi awọn arakunrin wọn ba tọ̀ wa wá lati wijọ, awa o si wi fun wọn pe, Ẹ ṣãnu wọn nitori wa: nitoriti awa kò mú aya olukuluku fun u li ogun na: bẹ̃ni ki iṣe ẹnyin li o fi wọn fun wọn; nigbana ni ẹnyin iba jẹbi.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan