Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Filemoni 1:6 - Bibeli Mimọ

6 Ki idapọ igbagbọ́ rẹ le lagbara, ni imọ ohun rere gbogbo ti mbẹ ninu nyin si Kristi.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

6 Adura mi ni pé kí àjọṣepọ̀ tàwa-tìrẹ ninu igbagbọ lè ṣiṣẹ́, láti mú kí òye rẹ pọ̀ sí i nípa gbogbo ohun rere tí a ní ninu Kristi.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

6 Èmi ń gbàdúrà pé, bí ìwọ ti ń ṣe alábápín nínú ìgbàgbọ́ rẹ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn, pé kí ìgbàgbọ́ náà lè mú ọkàn wọn dúró gbọingbọin, gẹ́gẹ́ bí wọn ti rí àwọn ọ̀rọ̀ ohun rere tí ó ń bẹ nínú ayé rẹ, èyí tí ó ti ọ̀dọ̀ Kristi wá.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Filemoni 1:6
18 Iomraidhean Croise  

Nigbana li eyi ti o gbà talenti marun lọ, ọ fi tirẹ̀ ṣòwo, o si jère talenti marun miran.


Ẹ jẹ ki imọlẹ nyin ki o mọlẹ tobẹ̃ niwaju enia, ki nwọn ki o le mã ri iṣẹ rere nyin, ki nwọn ki o le ma yìn Baba nyin ti mbẹ li ọrun logo.


Bẹ̃li a si fi aṣiri ọkàn rẹ̀ hàn; bẹ̃li on o si dojubolẹ yio si sin Ọlọrun, yio si sọ pe, nitotọ Ọlọrun mbẹ larin nyin.


Nitoripe ilẹkun nla ati aitase ṣi silẹ fun mi, ọ̀pọlọpọ si li awọn ọtá ti mbẹ.


Li akotan, ará, ohunkohun ti iṣe õtọ, ohunkohun ti iṣe ọ̀wọ, ohunkohun ti iṣe titọ́, ohunkohun ti iṣe mimọ́, ohunkohun ti iṣe fifẹ, ohunkohun ti o ni irohin rere; bi ìwa titọ́ kan ba wà, bi iyìn kan ba si wà, ẹ mã gbà nkan wọnyi rò.


Nitori eyi, lati ọjọ ti awa ti gbọ, awa pẹlu kò simi lati mã gbadura ati lati mã bẹ̀bẹ fun nyin pe ki ẹnyin ki o le kún fun ìmọ ifẹ rẹ̀ ninu ọgbọ́n ati imoye gbogbo ti iṣe ti Ẹmí;


Ẹ si ti gbé ọkunrin titun nì wọ̀, eyiti a sọ di titun si ìmọ gẹgẹ bi aworan ẹniti o da a:


Ki awọn enia wa pẹlu si kọ́ lati mã ṣe iṣẹ rere fun ohun ti a kò le ṣe alaini, ki nwọn ki o má ba jẹ alaileso.


Nitori Ọlọrun kì iṣe alaiṣododo ti yio fi gbagbé iṣẹ nyin ati ifẹ ti ẹnyin fihàn si orukọ rẹ̀, nipa iṣẹ iranṣẹ ti ẹ ti ṣe fun awọn enia mimọ́, ti ẹ si nṣe.


Ere kili o jẹ, ará mi, bi ẹnikan wipe on ni igbagbọ́, ṣugbọn ti kò ni iṣẹ? igbagbọ́ nì le gbà a là bi?


Bẹ̃ si ni igbagbọ́, bi kò ba ni iṣẹ, o kú ninu ara.


Ki ìwa nyin larin awọn Keferi kí o dara; pe, bi nwọn ti nsọ̀rọ nyin bi oluṣe buburu, nipa iṣẹ rere nyin, ti nwọn o mã kiyesi, ki nwọn ki o le mã yìn Ọlọrun logo li ọjọ ìbẹwo.


BẸ̃ gẹgẹ, ẹnyin aya, ẹ mã tẹriba fun awọn ọkọ nyin; pe, bi ẹnikẹni bá tilẹ nṣe aigbọran si ọ̀rọ na, ki a lè jere wọn li aisọrọ nipa ìwa awọn aya wọn,


Ki ẹ mã ni ẹri-ọkàn rere, bi nwọn ti nsọ̀rọ nyin ni ibi, ki oju ki o le ti awọn ti nkẹgan iwa rere nyin ninu Kristi.


Nitori bi ẹnyin bá ni nkan wọnyi ti nwọn bá si pọ̀, nwọn kì yio jẹ ki ẹ ṣe ọ̀lẹ tabi alaileso ninu ìmọ Oluwa wa Jesu Kristi.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan