Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Filemoni 1:24 - Bibeli Mimọ

24 Marku, Aristarku, Dema, Luku, awọn olubaṣiṣẹ mi kí ọ pẹlu.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

24 Bẹ́ẹ̀ ni Maku, ati Arisitakọsi, ati Demasi ati Luku, àwọn alábàáṣiṣẹ́ mi.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

24 Marku kí ọ pẹ̀lú Aristarku, Dema àti Luku, àwọn alábáṣiṣẹ́ mi.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Filemoni 1:24
15 Iomraidhean Croise  

Nigbati o si rò o, o lọ si ile Maria iya Johanu, ti apele rẹ̀ jẹ Marku; nibiti awọn enia pipọ pejọ si, ti nwọn ngbadura.


Barnaba on Saulu si pada ti Jerusalemu wá, nigbati nwọn si pari iṣẹ-iranṣẹ wọn, nwọn si mu Johanu wá pẹlu wọn, apele ẹniti ijẹ Marku.


Nigbati Paulu ati awọn ti o wà pẹlu rẹ̀ si ṣikọ̀ ni Pafo, nwọn wá si Perga ni Pamfilia: Johanu si fi wọn silẹ, o si pada lọ si Jerusalemu.


Gbogbo ilu na si kún fun irukerudò: nwọn fi ọkàn kan rọ́ sinu ile ibĩṣire, nwọn si mu Gaiu ati Aristarku ara Makedonia, awọn ẹgbẹ ajọrin Paulu.


Nigbati a si wọ̀ ọkọ̀ Adramittiu kan, ti nfẹ lọ si awọn ilu ti o wà leti okun Asia, awa ṣikọ̀: Aristarku, ara Makedonia ti Tessalonika, wà pẹlu wa.


Bi ẹnikẹni ba mbère ẹniti Titu iṣe, ẹlẹgbẹ ati olubaṣiṣẹ mi ni nitori nyin: tabi awọn arakunrin wa li ẹnikẹni mbère ni, iranṣẹ ijọ ni nwọn iṣe, ati ogo Kristi.


Mo ka a si pe n ko le ṣairan Epafroditu arakunrin mi si nyin, ati olubaṣiṣẹ mi ati ọmọ-ogun ẹgbẹ mi, ṣugbọn iranṣẹ nyin, ati ẹniti nṣe iranṣẹ fun mi ninu aini mi.


Mo si bẹ ọ pẹlu, bi alajọru-ajaga mi tõtọ, ran awọn obinrin wọnni lọwọ, nitori nwọn mba mi ṣiṣẹ pọ̀ ninu ihinrere, ati Klementi pẹlu, ati awọn olubaṣiṣẹ mi iyoku pẹlu, orukọ awọn ti mbẹ ninu iwe ìye.


Aristarku, ẹlẹgbẹ mi ninu tubu ki nyin, ati Marku, ọmọ arabinrin Barnaba (nipasẹ ẹniti ẹnyin ti gbà aṣẹ: bi o ba si wá sọdọ nyin, ẹ gbà a),


Luku, oniṣegun olufẹ, ati Dema ki nyin.


Ijọ ti mbẹ ni Babiloni, ti a yàn pẹlu nyin, kí nyin; bẹ̃ si ni Marku ọmọ mi pẹlu.


Njẹ o yẹ ki awa ki o gbà irú awọn wọnni, ki awa ki o le jẹ́ alabaṣiṣẹpọ pẹlu otitọ.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan