Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Filemoni 1:22 - Bibeli Mimọ

22 Ati pẹlu, pese ìbuwọ̀ silẹ dè mi; nitori mo gbẹkẹle pe nipa adura nyin, a ó fi mi fun nyin.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

22 Ó ku nǹkankan: Tọ́jú ààyè sílẹ̀ dè mí, nítorí mo ní ìrètí pé, nípa adura yín, Ọlọrun yóo jẹ́ kí wọ́n dá mi sílẹ̀ fun yín.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

22 Ó ku ohun kan: Ṣe ìtọ́jú iyàrá àlejò rẹ sílẹ̀ fún mi, nítorí mo ní ìgbàgbọ́ pé a óò tú mi sílẹ̀ fún yín ní ìdáhùn sí àdúrà yín.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Filemoni 1:22
13 Iomraidhean Croise  

O wipe, Má bẹ̀ru, Paulu; iwọ kò le ṣaima duro niwaju Kesari: si wo o, Ọlọrun ti fi gbogbo awọn ti o ba ọ wọkọ̀ pọ̀ fun ọ.


Nigbati nwọn dá ọjọ fun u, ọ̀pọlọpọ wọn li o tọ̀ ọ wá ni ile àgbawọ rẹ̀; awọn ẹniti o sọ asọye ọrọ ijọba Ọlọrun fun, o nyi wọn lọkàn pada sipa ti Jesu, lati inu ofin Mose ati awọn woli wá, lati owurọ̀ titi o fi di aṣalẹ.


Nigbakugba ti mo ba nlọ si Spania, ng ó tọ̀ nyin wá: nitori mo nireti pe emi o ri nyin li ọ̀na àjo mi, ati pe ẹ o mu mi já ọ̀na mi nibẹ̀ lati ọdọ nyin lọ, bi mo ba kọ kún fun ẹgbẹ nyin li apakan.


Ẹnyin pẹlu nfi adura nyin ṣe iranlọwọ fun wa, pe nitori ẹ̀bun ti a fifun wa lati ọwọ ọ̀pọlọpọ enia, ki ọ̀pọlọpọ ki o le mã dupẹ nitori wa.


Nitoriti mo mọ̀ pe eyi ni yio yọri si igbala fun mi lati inu adura nyin wá, ati ifikún Ẹmí Jesu Kristi,


Ṣugbọn mo gbẹkẹle Oluwa, pe emi tikarami pẹlu yio wá ni lọ̃lọ.


Ṣugbọn emi mbẹ̀ nyin gidigidi si i lati mã ṣe eyi, ki a ba le tète fi mi fun nyin pada.


Ẹ mọ̀ pé a dá Timotiu arakunrin wa silẹ; bi o ba tete de, emi pẹlu rẹ̀ yio ri nyin.


Ẹ jẹwọ ẹ̀ṣẹ nyin fun ara nyin, ki ẹ si mã gbadura fun ara nyin, ki a le mu nyin larada. Iṣẹ ti adura olododo nṣe li agbara pupọ.


Bi mo ti ni ohun pupọ̀ lati kọwe si nyin, emi kò fẹ lo tákàdá ati tàdãwa. Ṣugbọn emi ni ireti lati tọ nyin wá ati lati ba nyin sọrọ lojukoju, ki ayọ̀ nyin ki o le kún.


Ṣugbọn mo ni ireti lati ri ọ laipẹ, a o si sọrọ li ojukoju.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan