Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Filemoni 1:21 - Bibeli Mimọ

21 Bi mo ti ni igbẹkẹle ni igbọràn rẹ ni mo fi kọwe si ọ: nitori mo mọ̀ pe, iwọ ó tilẹ ṣe jù bi mo ti wi lọ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

21 Pẹlu ìdánilójú pé o óo ṣe bí mo ti wí ni mo fi kọ ìwé yìí sí ọ; mo sì mọ̀ pé o óo tilẹ̀ ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

21 Ìgbẹ́kẹ̀lé ti mo ní pé ìwọ yóò gbọ́rọ̀, ni mo fi kọ ìwé yìí ránṣẹ́ sí ọ. Mo mọ̀ dájú pé ìwọ yóò ṣe ju bí mo ti béèrè lọ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Filemoni 1:21
6 Iomraidhean Croise  

Ti o si gbé oju le ara rẹ̀ pe iwọ li amọ̀na awọn afọju, imọlẹ awọn ti o wà li òkunkun,


Emi si kọwe nitori eyi kanna si nyin pe, nigbati mo ba si de, ki emi ki o máṣe ni ibinujẹ lọdọ wọn, nitori awọn ti emi iba mã yọ̀: nitoriti mo ni igbẹkẹle ninu gbogbo nyin, nitori ayọ̀ mi li ayọ̀ fun gbogbo nyin.


Mo yọ̀ nitoripe li ohun gbogbo mo ni igbẹkẹle ninu nyin.


Awa si ti rán arakunrin wa pẹlu wọn, ẹniti awa ri daju nigba pipọ pe o ni itara ninu ohun pipọ, ṣugbọn nisisiyi ni itara rẹ̀ tubọ pọ si i nipa igbẹkẹle nla ti o ni si nyin.


Mo ni igbẹkẹle si nyin ninu Oluwa pe, ẹnyin kì yio ni ero ohun miran; ṣugbọn ẹniti nyọ nyin lẹnu yio rù idajọ tirẹ̀, ẹnikẹni ti o wù ki o jẹ.


Awa si ni igbẹkẹle ninu Oluwa niti nyin, pe nkan wọnni ti a palaṣẹ fun nyin li ẹnyin nṣe ti ẹ o si mã ṣe.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan