Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Filemoni 1:19 - Bibeli Mimọ

19 Emi Paulu li o fi ọwọ́ ara mi kọ ọ, emi ó san a pada: ki emi má sọ fun ọ, bi o ti jẹ mi nigbese ara rẹ pẹlu.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

19 Èmi, Paulu, ni mo fi ọwọ́ ara mi kọ ọ́ pé, n óo san án pada fún ọ. Kò tún nílò kí n sọ fún ọ pé ìwọ fúnrarẹ, o jẹ mí ní gbèsè ara rẹ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

19 Èmi Paulu, ni mo fi ọwọ́ ara mi kọ ìwé yìí; èmi yóò san án padà láì tilẹ̀ ní í sọ nípa pé ìwọ pàápàá jẹ mi ní gbèsè ara rẹ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Filemoni 1:19
14 Iomraidhean Croise  

Emi ni yio ṣe onigbọwọ rẹ̀: li ọwọ́ mi ni iwọ o bère rẹ̀; bi emi kò ba mú u pada fun ọ wá, ki nsi mu u duro niwaju rẹ, njẹ emi ni yio rù ẹbi na lailai.


Emi Tertiu ti nkọ Episteli yi, kí nyin ninu Oluwa.


Nitori bi ẹnyin tilẹ ni ẹgbarun olukọni ninu Kristi, ṣugbọn ẹnyin kò ni baba pipọ: nitoripe ninu Kristi Jesu ni mo ti fi ihinrere bí nyin.


ṢUGBỌN emi Paulu tikarami fi inu tutù ati ìwa pẹlẹ Kristi bẹ̀ nyin, emi ẹni irẹlẹ loju nyin nigbati mo wà larin nyin, ṣugbọn nigbati emi kò si, mo di ẹni igboiya si nyin.


Ẹnyin ni iwe wa, ti a ti kọ si wa li ọkàn, ti gbogbo enia ti mọ̀, ti nwọn sì ti kà:


Bi awọn ninu ará Makedonia ba bá mi wá, ti nwọn si bá nyin li aimura tẹlẹ, ki oju ki o máṣe tì wa (laiwipe ẹnyin,) niti igbẹkẹle yi.


Kiyesi i, emi Paulu li o wi fun nyin pe, bi a ba kọ nyin nila, Kristi ki yio li ère fun nyin li ohunkohun.


Ẹ wò bi mo ti fi ọwọ ara mi kọwe gàdàgbà-gàdàgbà si nyin.


Si Timotiu, ọmọ mi tõtọ ninu igbagbọ́: Ore-ọfẹ, ãnu, alafia lati ọdọ Ọlọrun Baba wá, ati Kristi Jesu Oluwa wa.


Si Titu, ọmọ mi nitõtọ nipa igbagbọ́ ti iṣe ti gbogbo enia: Ore-ọfẹ, ãnu, ati alafia, lati ọdọ Ọlọrun Baba wá ati Kristi Jesu Olugbala wa.


Ṣugbọn bi o ba ti ṣẹ̀ ọ rara, tabi ti o jẹ ọ nigbese kan, kà a si mi lọrùn.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan