Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Filemoni 1:17 - Bibeli Mimọ

17 Nitorina bi iwọ ba kà mi si ẹlẹgbẹ rẹ, gbà a bi emi tikarami.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

17 Nítorí náà bí o bá kà mí sí ẹni tí a jọ gba nǹkankan náà gbọ́, kí o gbà á pada tọwọ́-tẹsẹ̀ bí ẹni pé èmi alára ni o gbà.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

17 Nítorí náà bí ìwọ bá kà mí sí ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, tẹ́wọ́ gbà á bí ìwọ yóò ti tẹ́wọ́ gbà mí.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Filemoni 1:17
17 Iomraidhean Croise  

Ẹniti o ba gbà nyin, o gbà mi; ẹniti o ba si gbà mi, o gbà ẹniti o rán mi.


Ẹniti o ba si gbà irú ọmọ kekere yi kan, li orukọ mi, o gbà mi,


Ọba yio si dahùn yio si wi fun wọn pe, Lõtọ ni mo wi fun nyin, niwọn bi ẹnyin ti ṣe e fun ọkan ninu awọn arakunrin mi wọnyi ti o kere julọ ẹnyin ti ṣe e fun mi.


Nigbati a si baptisi rẹ̀, ati awọn ará ile rẹ̀, o bẹ̀ wa, wipe, Bi ẹnyin ba kà mi li olõtọ si Oluwa, ẹ wá si ile mi, ki ẹ si wọ̀ nibẹ̀. O si rọ̀ wa.


Bi ẹnikẹni ba mbère ẹniti Titu iṣe, ẹlẹgbẹ ati olubaṣiṣẹ mi ni nitori nyin: tabi awọn arakunrin wa li ẹnikẹni mbère ni, iranṣẹ ijọ ni nwọn iṣe, ati ogo Kristi.


Pe, awọn Keferi jẹ àjumọjogun ati ẹya-ara kanna, ati alabapin ileri ninu Kristi Jesu nipa ihinrere:


Gẹgẹ bi o ti tọ́ fun mi lati rò eyi fun gbogbo nyin, nitoriti ọkàn nyin wà lọdọ mi, niwọn bi o ti ṣepe gbogbo nyin ni iṣe alabapin ore-ọfẹ pẹlu mi ninu idè mi ati ninu idahùn-ẹjọ mi ati ifẹsẹmulẹ ihinrere.


Awọn ti o si ni oluwa onigbagbọ́, ki nwọn máṣe gàn wọn nitori arakunrin ni nwọn; ṣugbọn ki nwọn tubọ mã sìn wọn, nitori awọn ti iṣe alabapin iṣẹ rere wọn jẹ onigbagbọ́ ati olufẹ. Nkan wọnyi ni ki o mã kọ́ni ki o si mã fi gba-ni-niyanju.


Emi bẹ̀ ọ fun ọmọ mi, ti mo bí ninu ìde mi, Onesimu:


Ẹniti mo rán pada, ani on tikalarẹ̀, eyini ni olufẹ mi:


Ṣugbọn bi o ba ti ṣẹ̀ ọ rara, tabi ti o jẹ ọ nigbese kan, kà a si mi lọrùn.


NITORINA ẹnyin ará mimọ́, alabapín ìpe ọ̀run, ẹ gbà ti Aposteli ati Olori Alufa ijẹwọ wa ro, ani Jesu;


Nitori awa di alabapín pẹlu Kristi, bi awa ba dì ipilẹṣẹ igbẹkẹle wa mu ṣinṣin titi de opin;


Ẹ fi etí silẹ, ẹnyin ará mi olufẹ, Ọlọrun kò ha ti yàn awọn talakà aiye yi ṣe ọlọrọ̀ ni igbagbọ́, ati ajogun ijọba na, ti o ti ṣe ileri fun awọn ti o fẹ ẹ?


AWỌN alàgba ti mbẹ lãrin nyin ni mo bẹ̀, emi ẹniti iṣe alàgba bi ẹnyin, ati ẹlẹri ìya Kristi, ati alabapin ninu ogo ti a o fihàn:


Eyiti awa ti ri, ti awa si ti gbọ́ li awa nsọ fun nyin, ki ẹnyin pẹlu ki o le ní ìdapọ pẹlu wa: nitõtọ ìdapọ wa si mbẹ pẹlu Baba, ati pẹlu Ọmọ rẹ̀ Jesu Kristi.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan