Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Filemoni 1:12 - Bibeli Mimọ

12 Ẹniti mo rán pada, ani on tikalarẹ̀, eyini ni olufẹ mi:

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

12 Òun ni mò ń rán pada sí ọ. Ó wá dàbí ẹni pé mò ń fi ọkàn èmi pàápàá ranṣẹ sí ọ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

12 Èmi rán an nísinsin yìí, àní ẹni ọkàn mi padà sí ọ̀dọ̀ rẹ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Filemoni 1:12
10 Iomraidhean Croise  

Dafidi si wi fun Abiṣai, ati fun gbogbo awọn iranṣẹ rẹ̀ pe, Wõ, ọmọ mi ti o ti inu mi wá, nwá ẹmi mi kiri: njẹ melomelo ni ara Benjamini yi yio si ṣe? jọwọ rẹ̀, si jẹ ki o ma yan ẽbu; nitoripe Oluwa li o fi rán an.


Ọmọ ọ̀wọn ha ni Efraimu fun mi bi? ọmọ inu-didùn ha ni? nitori bi emi ti sọ̀rọ si i to, sibẹ emi ranti rẹ̀, nitorina ni ọkàn mi ṣe lù fun u; emi o ṣe iyọ́nu fun u nitõtọ, li Oluwa wi.


Nigbati ẹnyin ba si duro ngbadura, ẹ darijì, bi ẹnyin ba ni ohunkohun si ẹnikẹni: ki Baba nyin ti mbẹ li ọrun ba le dari ẹṣẹ nyin jì nyin pẹlu.


O si dide, o si tọ̀ baba rẹ̀ lọ. Ṣugbọn nigbati o si wà li òkere, baba rẹ̀ ri i, ãnu ṣe e, o si sure, o rọ̀mọ́ ọ li ọrùn, o si fi ẹnu kò o li ẹnu.


Ẹ mã ṣore fun ọmọnikeji nyin, ẹ ni iyọ́nu, ẹ mã darijì ara nyin, gẹgẹ bi Ọlọrun ninu Kristi ti darijì nyin.


Bi arakunrin rẹ, ọmọ iya rẹ, tabi ọmọ rẹ ọkunrin, tabi ọmọ rẹ obinrin, tabi aya õkan-àiya rẹ, tabi ọrẹ́ rẹ, ti o dabi ọkàn ara rẹ, bi o ba tàn ọ ni ìkọkọ, wipe, Jẹ ki a lọ ki a ma sìn ọlọrun miran, ti iwọ kò mọ̀ rí, iwọ, tabi awọn baba rẹ;


Nigbakan rí ẹniti o jẹ alailere fun ọ, ṣugbọn nisisiyi o lere fun ọ ati fun mi:


Ẹniti emi iba fẹ daduro pẹlu mi, ki o le mã ṣe iranṣẹ fun mi nipo rẹ ninu ìde ihinrere:


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan