Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Eksodu 2:3 - Bibeli Mimọ

3 Nigbati kò si le pa a mọ́ mọ́, o ṣe apoti ẽsu fun u, o si fi ọ̀da ilẹ ati oje igi ṣán a; o si tẹ́ ọmọ na sinu rẹ̀; o si gbé e sinu koriko odò li ẹba odò na.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

3 Nígbà tí kò lè gbé e pamọ́ mọ́, ó fi koríko kan tí ó dàbí èèsún ṣe apẹ̀rẹ̀ kan, ó fi oje igi ati ọ̀dà ilẹ̀ rẹ́ ẹ, ó gbé ọmọ náà sinu rẹ̀, ó sì gbé apẹ̀rẹ̀ náà sí ààrin koríko lẹ́bàá odò.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

3 Ṣùgbọ́n nígbà tí kò le è gbé e pamọ́ mọ́, ó fi ewé papirusi hun apẹ̀rẹ̀, ó sì fi ọ̀dà àti òjé igi sán apẹ̀rẹ̀ náà. Ó sì tẹ́ ọmọ náà sínú rẹ̀, ó sì gbe é sí inú eèsún ni etí odò Naili.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Eksodu 2:3
10 Iomraidhean Croise  

Nwọn si wi, ikini si ekeji pe, Ẹ wá na, ẹ jẹ ki a mọ briki, ki a si sun wọn jina. Briki ni nwọn ni li okuta, ọ̀da-ilẹ ni nwọn si nfi ṣe ọ̀rọ.


Afonifoji Siddimu si jẹ kìki kòto ọ̀da-ilẹ; awọn ọba Sodomu ati ti Gomorra sá, nwọn si ṣubu nibẹ̀; awọn ti o si kù sálọ si ori oke.


Iwọ fi igi goferi kàn ọkọ́ kan; ikele-ikele ni iwọ o ṣe ninu ọkọ́ na, iwọ o si fi ọ̀da kùn u ninu ati lode.


Farao si paṣẹ fun gbogbo awọn enia rẹ̀, wipe, Gbogbo ọmọkunrin ti a bí on ni ki ẹnyin gbé jù sinu odò, gbogbo awọn ọmọbinrin ni ki ẹnyin ki o dasi.


Ti o rán awọn ikọ̀ li ọ̀na okun, ani ninu ọkọ̀ koriko odò, li oju odò, wipe, Lọ, ẹnyin onṣẹ ti o yara kánkan, si orilẹ-ède ti a nà ká ti a si tẹju, si enia ti o ni ibẹ̀ru lati igbayi ati titi lọ; orilẹ-ède ti o ni ipá, ti o si tẹ̀ ni mọlẹ, ilẹ ẹniti odò pupọ̀ pinyà!


Odò yio si di rirùn; odò ãbo li a o sọ di ofo, ti a o si gbọ́n gbẹ; oko-odò ati iyè yio rọ.


Ilẹ yíyan yio si di àbata, ati ilẹ ongbẹ yio di isun omi; ni ibugbé awọn dragoni, nibiti olukuluku dubulẹ, ni o jẹ ọgbà fun ẽsú on iyè.


Nigbati nwọn si ti lọ, kiyesi i, angẹli Oluwa yọ si Josefu li oju alá, o wipe, Dide gbé ọmọ-ọwọ na pẹlu iya rẹ̀, ki o si sálọ si Egipti, ki iwọ ki o si gbé ibẹ̀ titi emi o fi sọ fun ọ; nitori Herodu yio wá ọmọ-ọwọ na lati pa a.


Nigbati Herodu ri pe, on di ẹni itanjẹ lọdọ awọn amoye, o binu gidigidi, o si ranṣẹ, o si pa gbogbo awọn ọmọ ti o wà ni Betlehemu ati ni ẹkùn rẹ̀, lati awọn ọmọ ọdún meji jalẹ gẹgẹ bi akokò ti o ti bere lẹsọlẹsọ lọwọ awọn amoye na.


On na li o ṣe àrekerekè si awọn ibatan wa, nwọn si hùwa buburu si awọn baba wa, tobẹ̃ ti nwọn fi já awọn ọmọ-ọwọ wọn kuro lọwọ wọn nitori ki nwọn ki o máṣe yè.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan