Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 9:7 - Bibeli Mimọ

7 Oluwa tirẹ li ododo, ṣugbọn tiwa ni itiju, gẹgẹ bi o ti ri loni; fun awọn enia Juda, ati fun awọn olugbe Jerusalemu, ati fun gbogbo Israeli, ti o sunmọ tosi, ati awọn ti o jina rére; ni gbogbo ilẹkilẹ, nibiti o gbe ti le wọn rè, nitori ẹ̀ṣẹ wọn ti nwọn ti ṣẹ̀ si ọ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

7 Olódodo ni ọ́, OLUWA, ṣugbọn lónìí yìí ojú ti gbogbo àwọn ará Juda ati Jerusalẹmu, ati gbogbo Israẹli; ati àwọn tí wọ́n wà nítòsí ati àwọn tí wọ́n wà ní ọ̀nà jíjìn, níbi gbogbo tí o fọ́n wọn káàkiri sí nítorí ìwà ọ̀dàlẹ̀ tí wọ́n hù sí ọ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

7 “Olúwa ìwọ ni olódodo, ṣùgbọ́n báyìí ìtìjú dé bá àwọn ènìyàn Juda, àwọn ènìyàn Jerusalẹmu àti gbogbo Israẹli ní gbogbo orílẹ̀-èdè tí ìwọ ti fọ́n wa ká sí nítorí àìṣòótọ́ ọ wa sí ọ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 9:7
34 Iomraidhean Croise  

Ati lẹhin gbogbo eyi ti o de si wa nitori iṣe buburu wa, ati nitori ẹbi wa nla, nitoripe iwọ Ọlọrun wa ti dá wa si ju bi o ti yẹ lọ fun aiṣedede wa, o si fi iru igbala bi eyi fun wa;


Olododo ni iwọ Oluwa Ọlọrun Israeli: awa ni iyokù ati asala gẹgẹ bi o ti ri li oni yi: wò o, awa duro niwaju rẹ ninu ẹbi wa, nitoripe awa ki o le duro niwaju rẹ nitori eyi.


Sibẹ, iwọ ṣe olododo ninu ohun gbogbo ti o de ba wa, iwọ si ti ṣe otitọ, ṣugbọn awa ti ṣe buburu:


Olododo ni iwọ, Oluwa, ati diduro-ṣinṣin ni idajọ rẹ.


Idamu mi mbẹ niwaju mi nigbagbogbo, itiju mi si bò mi mọlẹ.


Ọlọrun, gbà mi lọwọ ẹbi ẹ̀jẹ, iwọ Ọlọrun igbala mi: ahọn mi yio si ma kọrin ododo rẹ kikan.


Iwọ, iwọ nikanṣoṣo ni mo ṣẹ̀ si, ti mo ṣe buburu yi niwaju rẹ: ki a le da ọ lare, nigbati iwọ ba nsọ̀rọ, ki ara rẹ ki o le mọ́, nigbati iwọ ba nṣe idajọ.


Yio si ṣe li ọjọ na, ni Oluwa yio tun nawọ rẹ̀ lati gbà awọn enia rẹ̀ iyokù padà, ti yio kù, lati Assiria, ati lati Egipti, ati lati Patrosi, ati lati Kuṣi, ati lati Elamu, ati Ṣinari, ati lati Hamati, ati lati awọn erekùṣu okun wá.


Oju yio tì wọn, gbogbo wọn o si dãmu pọ̀; gbogbo awọn ti nṣe ere yio si jumọ lọ si idãmu.


ALARE ni iwọ, Oluwa, nigbati mo mba ọ wijọ: sibẹ, jẹ ki emi ba ọ sọ ti ọ̀ran idajọ: ẽtiṣe ti ãsiki mbẹ ni ọ̀na enia buburu, ti gbogbo awọn ti nṣe ẹ̀tan jẹ alailewu.


Li ọjọ rẹ̀ ni a o gba Juda là, Israeli yio si ma gbe li ailewu, ati eyi li orukọ ti a o ma pè e: OLUWA ODODO WA.


Emi o fi wọn fun iwọsi ati fun ibi ninu gbogbo ijọba aiye, lati di ìtiju, owe, ẹsin, ati ẹ̀gan ni ibi gbogbo, ti emi o le wọn si.


Awa dubulẹ ninu itiju wa, rudurudu wa bò wa mọlẹ, nitoriti awa ti ṣẹ̀ si Oluwa Ọlọrun wa, awa pẹlu awọn baba wa, lati igba ewe wa wá, titi di oni yi, awa kò gba ohùn Oluwa Ọlọrun wa gbọ́.


Nitori gbogbo ibi awọn ọmọ Israeli, ati awọn ọmọ Juda, ti nwọn ti ṣe lati mu mi binu, awọn, awọn ọba wọn, ijoye wọn, alufa wọn, ati woli wọn, ati awọn ọkunrin Juda, ati awọn olugbe Jerusalemu.


Li ọjọ wọnni li a o gbà Juda la, Jerusalemu yio si ma gbe li ailewu: orukọ yi li a o ma pè e: OLUWA ODODO WA.


Bi awọn ti nṣọ oko, bẹ̃ni nwọn wà yi i kakiri: nitori o ti ṣọtẹ̀ si mi, li Oluwa wi.


Ibinu mi ni nwọn ha ru soke bi? li Oluwa wi, kì ha ṣe si ara wọn fun rudurudu oju wọn?


Ki iwọ ki o le ranti, ki o si le dãmu, ki iwọ ki o má si le yà ẹnu rẹ mọ nitori itiju rẹ, nigbati inu mi ba tutù si ọ, nitori ohun ti iwọ ti ṣe, ni Oluwa Ọlọrun wi.


Nigbana li ẹnyin o ranti ọ̀na buburu nyin, ati iṣe nyin ti kò dara, ẹ o si sú ara nyin li oju ara nyin fun aiṣedẽde nyin, ati fun irira nyin.


Nitorina awọn baba yio jẹ awọn ọmọ li ãrin rẹ, ati awọn ọmọ yio si jẹ awọn baba wọn; emi o si ṣe idajọ ninu rẹ, ati gbogbo iyokù rẹ li emi o tuka si gbogbo ẹfũfù.


Ẹniti o jina rere yio kú nipa ajakalẹ àrun; ati ẹniti o sunmọ tosí yio ṣubu nipa idà; ati ẹniti o kù ti a si do tì yio kú nipa iyàn: bayi li emi o mu irunu mi ṣẹ lori wọn.


Nitorina li Oluwa ṣe fiyesi ibi na, ti o si mu u wá sori wa; nitoripe olododo li Oluwa Ọlọrun wa ni gbogbo iṣẹ rẹ̀ ti o nṣe: ṣugbọn awa kò gbà ohùn rẹ̀ gbọ́.


Tẹ eti rẹ silẹ, Ọlọrun mi, ki o si gbọ́: ṣi oju rẹ, ki o si wò idahoro wa, ati ilu ti a nfi orukọ rẹ pè: nitoriti awa kò gbé ẹ̀bẹ wa kalẹ niwaju rẹ nitori ododo wa, ṣugbọn nitori ọ̀pọlọpọ ãnu rẹ nla.


Oluwa, tiwa ni itiju, ti awọn ọba wa, ati awọn olori wa, ati ti awọn baba wa, nitori ti awa ti ṣọ̀tẹ si ọ.


Wò o, nitori emi o paṣẹ, emi o si kù ile Israeli ninu awọn orilẹ-ède, bi ã ti kù ọkà ninu kọ̀nkọsọ, ṣugbọn woro kikini kì yio bọ́ sori ilẹ.


Njẹ eso kili ẹnyin ha ni nigbana ninu ohun ti oju ntì nyin si nisisiyi? nitori opin nkan wọnni ikú ni.


Apata na, pipé ni iṣẹ rẹ̀; nitoripe idajọ ni gbogbo ọ̀na rẹ̀: Ọlọrun otitọ ati alàiṣegbe, ododo ati otitọ li on.


OLUWA yio si tú nyin ká ninu awọn orilẹ-ède, diẹ ni ẹnyin o si kù ni iye ninu awọn orilẹ-ède, nibiti OLUWA yio darí nyin si.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan