Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 9:5 - Bibeli Mimọ

5 Awa ti ṣẹ̀, awa si ti nda ẹ̀ṣẹ, awa si ti ṣe buburu gidigidi, awa si ti ṣọ̀tẹ, ani nipa kikuro ninu ẹkọ́ rẹ, ati idajọ rẹ:

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

5 “A ti ṣẹ̀, a ti ṣe burúkú; a ti ṣìṣe, a ti ṣọ̀tẹ̀, nítorí pé a ti kọ òfin ati àṣẹ rẹ sílẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

5 Àwa ti ṣẹ̀, a sì ti ṣe búburú. Àwa ti hu ìwà búburú, a sì ti ṣe ọ̀tẹ̀, a ti yí padà kúrò nínú àwọn àṣẹ àti àwọn ìlànà rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 9:5
31 Iomraidhean Croise  

Nitoriti nwọn kò gbà ohùn Oluwa Ọlọrun wọn gbọ́, ṣugbọn nwọn dà majẹmu rẹ̀, ati ohun gbogbo ti Mose iranṣẹ Oluwa pa li aṣẹ, nwọn kò si fi eti si wọn, bẹ̃ni nwọn kò si ṣe wọn.


Nitori nwọn ti ṣe eyiti o buru li oju mi, ti nwọn si ti mu mi binu, lati ọjọ ti awọn baba wọn ti jade kuro ni Egipti, ani titi di oni yi.


Mo si wipe, Ọlọrun mi, oju tì mi, iṣãju si ṣe mi lati gbe oju mi soke si ọdọ rẹ, Ọlọrun mi, nitoriti ẹ̀ṣẹ wa di pupọ li ori wa, ẹbi wa si tobi titi de awọn ọrun.


Awa ti ṣẹ̀ pẹlu awọn baba wa, awa ti dẹṣẹ, awa ti ṣe buburu.


Emi kò yà kuro ni idajọ rẹ: nitoripe iwọ li o kọ́ mi.


Emi ti ṣina kiri bi agutan ti o nù; wá iranṣẹ rẹ nitori ti emi kò gbagbe aṣẹ rẹ.


Nitori mo ti nkiye si ọ̀na Oluwa, emi kò fi ìka yà kuro lọdọ Ọlọrun mi.


Gbogbo wa ti ṣina kirikiri bi agutan, olukuluku wa tẹ̀le ọ̀na ara rẹ̀; Oluwa si ti mu aiṣedede wa gbogbo pade lara rẹ̀.


Ni rirekọja ati ṣiṣeke si Oluwa, ifaṣẹhin kuro lọdọ Ọlọrun wa, isọrọ inilara ati ìṣọtẹ, liloyun ati sisọrọ eke lati inu jade wá.


Nitori lati ipilẹṣẹ aiye wá, a kò ti igbọ́, bẹ̃ni eti kò ti gbọ́ ọ, bẹ̃ni oju kò ti iri Ọlọrun kan lẹhin rẹ, ti o ti pèse fun ẹniti o duro dè e.


Awa jẹwọ iwa buburu wa, Oluwa, ati aiṣedede awọn baba wa: nitori awa ti ṣẹ̀ si ọ.


Oluwa, bi ẹ̀ṣẹ wa ti jẹri si wa to nì, ṣe atunṣe nitori orukọ rẹ: nitoriti ipẹhinda wa pọ̀; si ọ li awa ti ṣẹ̀.


Awa dubulẹ ninu itiju wa, rudurudu wa bò wa mọlẹ, nitoriti awa ti ṣẹ̀ si Oluwa Ọlọrun wa, awa pẹlu awọn baba wa, lati igba ewe wa wá, titi di oni yi, awa kò gba ohùn Oluwa Ọlọrun wa gbọ́.


Gbogbo awọn olufẹ rẹ ti gbagbe rẹ; nwọn kò tẹle ọ; nitori ìlù ọta li emi o lù ọ, ni inà alaini ãnu, nitori ọ̀pọlọpọ aiṣedede rẹ, nitori ẹ̀ṣẹ rẹ pọ si i,


Nitori ìwa-buburu wọn ti nwọn ti hú lati mu mi binu, ni lilọ lati sun turari ati lati sìn awọn ọlọrun miran, ti nwọn kò mọ̀, awọn, tabi ẹnyin, tabi awọn baba nyin.


Oluwa ṣe olododo; nitoriti emi ti ṣọ̀tẹ si aṣẹ ẹnu rẹ̀: gbọ́, (emi bẹ nyin,) gbogbo orilẹ-ède, ẹ si wò ikãnu mi; awọn wundia mi ati awọn ọdọmọkunrin mi lọ si igbekun.


Wò o, Oluwa: nitoriti emi wà ninu ipọnju: inu mi nhó; ọkàn mi yipada ninu mi; nitoriti emi ti ṣọ̀tẹ gidigidi: lode, idà sọni di alailọmọ, ni ile, o dabi ikú!


Awa ti dẹṣẹ, a si ti ṣọtẹ: iwọ kò ti dariji.


O si ti pa idajọ mi dà si buburu ju awọn orilẹ-ède lọ, ati ilana mi ju ilẹ ti o yi i kakiri: nitori nwọn ti kọ̀ idajọ ati ilana mi, nwọn kò rìn ninu wọn.


Awọn ti o bọ́ ninu nyin yio si ranti mi, lãrin awọn orilẹ-ède nibiti nwọn o gbe dì wọn ni igbekun lọ, nitoriti mo ti fọ́ ọkàn agbere wọn ti o ti lọ kuro lọdọ mi, ati pẹlu oju wọn, ti nṣagbere lọ sọdọ oriṣa wọn: nwọn o si sú ara wọn nitori ìwa ibi ti nwọn ti hù ninu gbogbo irira wọn.


Bẹ̃ni gbogbo Israeli ti ṣẹ̀ si ofin rẹ, ani nipa kikuro, ki nwọn ki o máṣe gbà ohùn rẹ gbọ́; nitorina li a ṣe yi egún dà si ori wa, ati ibura na ti a kọ sinu ofin Mose, iranṣẹ Ọlọrun, nitori ti awa ti ṣẹ̀ si i.


Njẹ nisisiyi, Oluwa Ọlọrun wa, iwọ ti o ti fi ọwọ agbara mu awọn enia rẹ jade lati Egipti wá, ti iwọ si ti gba orukọ fun ara rẹ gẹgẹ bi o ti wà loni: awa ti ṣẹ̀, awa si ti ṣe buburu gidigidi.


Sibẹ ti Oluwa Ọlọrun wa li ãnu ati idariji bi awa tilẹ ṣọ̀tẹ si i;


Ibẹ̀rẹ ọ̀rọ Oluwa si Hosea. Oluwa si wi fun Hosea, pe, Lọ, fẹ́ agbère obinrin kan fun ara rẹ, ati awọn ọmọ agbère; nitori ilẹ yi ti ṣe agbère gidigidi, kuro lẹhin Oluwa.


Lati ọjọ awọn baba nyin wá li ẹnyin tilẹ ti yapa kuro ni ilàna mi, ti ẹ kò si pa wọn mọ. Ẹ yipada si ọdọ mi, Emi o si yipada si ọdọ nyin, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi. Ṣugbọn ẹnyin wipe, nipa bawo li awa o yipada?


Ẹ kiyesara, ará, ki ọkàn buburu ti aigbagbọ́ ki o máṣe wà ninu ẹnikẹni nyin, ni lilọ kuro lọdọ Ọlọrun alãye.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan