Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 9:2 - Bibeli Mimọ

2 Li ọdun kini ijọba rẹ̀ li emi Danieli fiyesi lati inu iwe, iye ọdun, nipa eyi ti ọ̀rọ Oluwa tọ Jeremiah, woli wá, pe adọrin ọdun li on o mu pé lori idahoro Jerusalemu.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

2 èmi, Daniẹli bẹ̀rẹ̀ sí ka ọ̀rọ̀ OLUWA, mò ń ronú lórí ohun tí Jeremaya, wolii sọ, pé Jerusalẹmu yóo dahoro fún aadọrin ọdún.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

2 Ní ọdún kìn-ín-ní ìjọba rẹ̀, èmi Daniẹli fi iyè sí i láti inú ìwé, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Olúwa tí wòlíì Jeremiah, wá pé, àádọ́rin ọdún ni Jerusalẹmu yóò fi wà ní ahoro.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 9:2
32 Iomraidhean Croise  

Lati mu ọ̀rọ Oluwa ṣẹ lati ẹnu Jeremiah wá, titi ilẹ na yio fi san ọdun isimi rẹ̀; ani ni gbogbo ọjọ idahoro on nṣe isimi titi ãdọrin ọdun yio fi pé.


LI ọdun ekini Kirusi, ọba Persia, ki ọ̀rọ OLUWA lati ẹnu Jeremiah wá ki o le ṣẹ, OLUWA rú ẹmi Kirusi, ọba Persia soke, ti o mu ki a kede yi gbogbo ijọba rẹ̀ ka, a si kọwe rẹ̀ pẹlu wipe,


Ẹri rẹ pẹlu ni didùn-inu mi ati ìgbimọ mi.


Awọn ilu mimọ́ rẹ di aginju, Sioni dí aginju, Jerusalemu di ahoro.


Ọ̀RỌ Jeremiah, ọmọ Hilkiah, ọkan ninu awọn alufa ti o wà ni Anatoti, ni ilẹ Benjamini.


Ani Jerusalemu ati ilu Juda wọnni, ati awọn ọba wọn pẹlu awọn ijoye, lati sọ wọn di ahoro, idãmu, ẹsin, ati egún, gẹgẹ bi o ti ri loni.


Mikah, ara Moraṣi, ṣe woli li ọjọ Hesekiah, ọba Juda, o si wi fun gbogbo enia Juda pe: Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi: a o tulẹ Sioni fun oko, Jerusalemu yio di òkiti alapa, ati oke ile yi gẹgẹ bi ibi giga igbo.


Emi o si ṣe ile yi bi Ṣilo, emi o si ṣe ilu yi ni ifibu si gbogbo orilẹ-ède aiye.


Ati orilẹ-ède gbogbo ni yio sin on, ati ọmọ rẹ̀ ati ọmọ-ọmọ rẹ̀, titi di ìgba ti akoko ilẹ tirẹ̀ yio de; lara rẹ̀ ni orilẹ-ède pupọ ati awọn ọba nla yio jẹ.


Nitori bayi li Oluwa wi pe, Lẹhin ti ãdọrin ọdun ba pari ni Babeli, li emi o bẹ̀ nyin wò, emi o si mu ọ̀rọ rere mi ṣẹ si nyin, ni mimu nyin pada si ibi yi.


Emi o si mu ki ohùn inu-didun ki o da kuro ni ilu Juda ati kuro ni ita Jerusalemu, ohùn ayọ̀, ohùn ọkọ iyawo, ati ti iyawo; nitori ilẹ na yio di ahoro.


BAWO ni ilu ṣe joko nikan, eyi ti o ti kún fun enia! o wà bi opó! on ti iṣe ẹni-nla lãrin awọn orilẹ-ède! ọmọ-alade obinrin lãrin igberiko, on di ẹrú!


Ẹsẹ enia kì yio kọja li ãrin rẹ̀, bẹ̃ni ẹsẹ ẹrankẹran kì yio kọja li ãrin rẹ̀, bẹ̃ni a kì yio tẹ̀ ẹ dó li ogoji ọdun.


Emi si kọju mi si Oluwa Ọlọrun, lati ma ṣafẹri nipa adura ati ẹ̀bẹ, pẹlu àwẹ, ninu aṣọ-ọ̀fọ, ati ẽru.


Nitorina nitori nyin ni a o ṣe ro Sioni bi oko, Jerusalemu yio si di okìti, ati oke-nla ile bi ibi giga igbo.


Nigbana ni angeli Oluwa na dahùn o si wipe, Oluwa awọn ọmọ-ogun, yio ti pẹ to ti iwọ kì yio fi ṣãnu fun Jerusalemu, ati fun awọn ilu-nla Juda, ti iwọ ti binu si li ãdọrin ọdun wọnyi?


Sọ fun gbogbo awọn enia ilẹ na, ati fun awọn alufa, wipe, Nigbati ẹnyin gbawẹ̀ ti ẹ si ṣọ̀fọ li oṣù karun ati keje, ani fun ãdọrin ọdun wọnni, ẹnyin ha gbawẹ̀ si mi rara, ani si emi?


Nitorina nigbati ẹnyin ba ri irira isọdahoro, ti a ti ẹnu wolĩ Danieli sọ, ti o ba duro ni ibi mimọ́, (ẹniti o ba kà a, ki òye ki o yé e:)


Ṣugbọn nigbati ẹnyin ba ri irira isọdahoro nì, ti o duro nibiti ko tọ́, ti a ti ẹnu woli Danieli ṣọ, (ẹnikẹni ti o ba kà a, ki o yé e,) nigbana ni ki awọn ti mbẹ ni Judea sálọ si ori òke:


Iwẹfa si da Filippi lohùn, o ni, Mo bẹ̀ ọ, ti tani woli na sọ ọ̀rọ yi? ti ara rẹ̀, tabi ti ẹlomiran?


Titi emi o fi de, mã tọju iwe kikà ati igbaniyanju ati ikọ́ni.


Olubukún li ẹniti nkà, ati awọn ti o ngbọ́ ọ̀rọ isọtẹlẹ yi, ti o si npa nkan wọnni ti a kọ sinu rẹ̀ mọ́: nitori igba kù si dẹ̀dẹ.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan