Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 9:16 - Bibeli Mimọ

16 Oluwa, gẹgẹ bi gbogbo ododo rẹ, lõtọ, jẹ ki ibinu ati irunu rẹ yi kuro lori Jerusalemu, ilu rẹ, òke mimọ́ rẹ: nitori ẹ̀ṣẹ wa, ati ẹ̀ṣẹ awọn baba wa ni Jerusalemu, ati awọn enia rẹ fi di ẹ̀gan si gbogbo awọn ti o yi wa ka.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

16 OLUWA, gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ òdodo rẹ, dáwọ́ ibinu ati ìrúnú rẹ dúró lórí Jerusalẹmu, ìlú rẹ, òkè mímọ́ rẹ; nítorí pé ẹ̀ṣẹ̀ ati àìdára àwọn baba wa, ti sọ Jerusalẹmu ati àwọn eniyan rẹ, di àmúpòwe láàrin àwọn tí ó yí wa ká.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

16 Olúwa, ní ìbámu pẹ̀lú ìwà òdodo rẹ, yí ìbínú àti ìrunú rẹ padà kúrò ní Jerusalẹmu ìlú u rẹ, òkè mímọ́ rẹ. Ẹ̀ṣẹ̀ wa àti àìṣedéédéé àwọn baba wa ti mú Jerusalẹmu àti ènìyàn rẹ di ẹ̀gàn fún gbogbo àwọn tí ó yí wọn ká.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 9:16
33 Iomraidhean Croise  

Iwọ si ri pe ọkàn rẹ̀ jẹ olõtọ niwaju rẹ, iwọ si ba a dá majẹmu lati fi ilẹ awọn ara Kenaani, awọn ara Hitti, awọn ara Amori, ati awọn ara Perisi, ati awọn ara Jebusi, ati awọn ara Girgasi fun u, lati fi fun iru-ọmọ rẹ̀, iwọ si ti mu ọ̀rọ rẹ ṣẹ; nitori olododo ni iwọ:


OLUWA, gbọ́ adura mi, fi eti si ẹ̀bẹ mi; ninu otitọ rẹ dá mi lohùn ati ninu ododo rẹ.


OLUWA, iwọ ni mo gbẹkẹ mi le: máṣe jẹ ki oju ki o tì mi: gbà mi ninu ododo rẹ.


Olubukún ni Oluwa, Ọlọrun Israeli, lailai titi lai. Amin, Amin.


Gbà mi nipa ododo rẹ, ki o si mu mi yọ̀: dẹ eti rẹ si mi, ki o si gbà mi.


Awa di ẹ̀gan si awọn aladugbo wa, ẹlẹya ati iyọṣuti si awọn ti o yi wa ka.


Yi wa pada, Ọlọrun igbala wa, ki o si mu ibinu rẹ si wa ki o dá.


Ti awọn ọta rẹ fi kẹgàn, Oluwa: ti nwọn fi ngàn ipasẹ Ẹni-ororo rẹ.


Iwọ kò gbọdọ tẹ̀ ori ara rẹ ba fun wọn, bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ sìn wọn: nitori emi li OLUWA Ọlọrun rẹ, Ọlọrun owú ni mi, ti mbẹ̀ ẹ̀ṣẹ awọn baba wò lara awọn ọmọ, lati irandiran kẹta ati ẹkẹrin ninu awọn ti o korira mi;


Nitorina ni ibinu Oluwa fi ràn si enia rẹ̀, o si ti na ọwọ́ rẹ̀ si wọn, o si ti lù wọn: awọn òke si warìri, okú wọn si wà bi igbẹ li ãrin igboro. Ni gbogbo eyi ibinu rẹ̀ kò yi kuro, ṣugbọn ọwọ́ rẹ̀ nà jade sibẹ.


Emi o fi wọn fun iwọsi ati fun ibi ninu gbogbo ijọba aiye, lati di ìtiju, owe, ẹsin, ati ẹ̀gan ni ibi gbogbo, ti emi o le wọn si.


Emi o si fi idà, ìyan, ati àjakalẹ-arun lepa wọn; emi o si fi wọn fun iwọsi ni gbogbo ijọba aiye, fun egún, ati iyanu, ati ẹsin, ati ẹ̀gan, lãrin gbogbo orilẹ-ède, nibiti emi o le wọn si.


Nitori ilu yi ti jẹ ohun ibinu ati irunu fun mi lati ọjọ ti nwọn ti kọ ọ wá titi di oni yi; tobẹ̃ ti emi o mu u kuro niwaju mi.


Nitori gbogbo ibi awọn ọmọ Israeli, ati awọn ọmọ Juda, ti nwọn ti ṣe lati mu mi binu, awọn, awọn ọba wọn, ijoye wọn, alufa wọn, ati woli wọn, ati awọn ọkunrin Juda, ati awọn olugbe Jerusalemu.


Iwọ ti di ẹlẹbi niti ẹjẹ rẹ ti iwọ ti ta silẹ; iwọ si ti sọ ara rẹ di aimọ́ niti òriṣa rẹ ti iwọ ti ṣe, iwọ si ti mu ọjọ rẹ summọ tosí, iwọ si ti dé ọdun rẹ: nitorina ni mo ṣe sọ ọ di ẹgàn si awọn keferi, ati ẹsín si gbogbo ilẹ.


Emi o si fi ọ ṣòfo, emi o si sọ ọ di ẹ̀gan lãrin awọn orilẹ-ède ti o yi ọ ka kiri, li oju gbogbo awọn ti nkọja.


On o si pagọ ãfin rẹ̀ lãrin omi kọju si òke mimọ́ ologo nì; ṣugbọn on o si de opin rẹ̀, kì yio si si ẹniti yio ràn a lọwọ.


Bi emi si ti nwi, ti emi ngbadura, ati bi emi si ti njẹwọ ẹṣẹ mi, ati ẹ̀ṣẹ Israeli awọn enia mi, ti emi si ngbé ẹbẹ mi kalẹ niwaju Oluwa, Ọlọrun mi, nitori òke mimọ́ Ọlọrun mi.


Bẹ̃li ẹnyin o mọ̀ pe, Emi li Oluwa Ọlọrun nyin, ti ngbe Sioni oke mimọ́ mi: nigbana ni Jerusalemu yio jẹ mimọ́, awọn alejo kì yio si là a kọja mọ.


Bayi li Oluwa wi; Mo ti yipada si Sioni emi o si gbe ãrin Jerusalemu: a o si pè Jerusalemu ni ilu nla otitọ; ati oke nla Oluwa awọn ọmọ-ogun, okenla mimọ́ nì.


Bi o ti jẹ pe ohun ododo ni fun Ọlọrun lati fi ipọnju gbẹsan lara awọn ti npọ́n nyin loju,


Bi awa ba jẹwọ ẹ̀ṣẹ wa, olõtọ ati olododo li on lati dari ẹṣẹ wa jì wa, ati lati wẹ̀ wa nù kuro ninu aiṣododo gbogbo.


Oluwa sọ di talaka, o si sọ di ọlọrọ̀: o rẹ̀ silẹ, o si gbe soke.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan