Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 9:11 - Bibeli Mimọ

11 Bẹ̃ni gbogbo Israeli ti ṣẹ̀ si ofin rẹ, ani nipa kikuro, ki nwọn ki o máṣe gbà ohùn rẹ gbọ́; nitorina li a ṣe yi egún dà si ori wa, ati ibura na ti a kọ sinu ofin Mose, iranṣẹ Ọlọrun, nitori ti awa ti ṣẹ̀ si i.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

11 Gbogbo Israẹli ti rú òfin rẹ, wọ́n ti pada lẹ́yìn rẹ, wọ́n kọ̀, wọn kò gbọ́ tìrẹ. Nítorí náà, ègún ati ìbúra tí Mose, iranṣẹ rẹ kọ sinu ìwé òfin ti ṣẹ mọ́ wa lára.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

11 Gbogbo Israẹli ti ṣẹ̀ sí òfin rẹ, wọ́n ti yípadà kúrò ní ọ̀dọ̀ rẹ, wọ́n kọ̀ láti ṣe ìgbọ́ràn sí ọ. “Nígbà náà ni ègún àti ìdájọ́ tí a kọ sílẹ̀ pẹ̀lú ìbúra nínú òfin Mose ìránṣẹ́ Ọlọ́run dà sórí i wa, nítorí tí àwa ti sẹ̀ sí ọ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 9:11
30 Iomraidhean Croise  

Nitoriti nwọn kò gbà ohùn Oluwa Ọlọrun wọn gbọ́, ṣugbọn nwọn dà majẹmu rẹ̀, ati ohun gbogbo ti Mose iranṣẹ Oluwa pa li aṣẹ, nwọn kò si fi eti si wọn, bẹ̃ni nwọn kò si ṣe wọn.


Bayi li Oluwa wi, Kiyesi i, emi o mu ibi bá ibiyi, ati bá awọn ara ilu na, ani gbogbo ọ̀rọ iwe na ti ọba Juda ti kà.


Malũ mọ̀ oluwa rẹ̀, kẹtẹ́kẹtẹ si mọ̀ ibujẹ oluwa rẹ̀: ṣugbọn Israeli kò mọ̀, awọn enia mi kò ronu.


Nitorina mo ti sọ awọn olori ibi mimọ́ na di aimọ́, mo si ti fi Jakobu fun egún, ati Israeli fun ẹ̀gan.


Nigbana ni iwọ o wi fun wọn pe, Nitoripe awọn baba nyin ti kọ̀ mi silẹ, li Oluwa wi, ti nwọn si rìn tọ̀ ọlọrun miran lọ, ti nwọn si sìn wọn, ti nwọn si foribalẹ fun wọn, ti nwọn kọ̀ mi silẹ, ti nwọn kò pa ofin mi mọ;


Ẽṣe ti ẹnyin o ba mi jà? gbogbo nyin li o ti rufin mi, li Oluwa wi.


Gbogbo awọn olufẹ rẹ ti gbagbe rẹ; nwọn kò tẹle ọ; nitori ìlù ọta li emi o lù ọ, ni inà alaini ãnu, nitori ọ̀pọlọpọ aiṣedede rẹ, nitori ẹ̀ṣẹ rẹ pọ si i,


Nwọn si wá, nwọn si ni i; ṣugbọn nwọn kò gbà ohùn rẹ gbọ́, bẹ̃ni nwọn kò rìn ninu ofin rẹ, nwọn kò ṣe gbogbo eyiti iwọ paṣẹ fun wọn lati ṣe: iwọ si pè gbogbo ibi yi wá sori wọn:


Oluwa si ti mu u wá, o si ṣe gẹgẹ bi o ti wi: nitoripe ẹnyin ti ṣẹ̀ si Oluwa, ẹ kò si gbọ́ ohùn rẹ̀, nitorina ni nkan yi ṣe de ba nyin.


Tobẹ̃ ti Oluwa kò le rọju pẹ mọ, nitori buburu iṣe nyin, ati nitori ohun irira ti ẹnyin ti ṣe; bẹ̃ni ilẹ nyin di ahoro, ati iyanu ati ègun, laini olugbe, bi o ti ri li oni yi.


Nitori ti ẹnyin ti sun turari, ati nitori ti ẹnyin ṣẹ̀ si Oluwa, ti ẹnyin kò gbà ohùn Oluwa gbọ́, ti ẹ kò rin ninu ofin rẹ̀, ati ninu ilana rẹ̀, ati ninu ọ̀rọ ẹri rẹ̀; nitorina ni ibi yi ṣe de si nyin, bi o ti ri li oni yi.


Gbọ́, iwọ ilẹ! wò o, emi o mu ibi wá si ori enia yi, ani eso iro inu wọn, nitori nwọn kò fi eti si ọ̀rọ mi, ati ofin mi ni nwọn kọ̀ silẹ.


Egipti ati Juda ati Edomu, ati awọn ọmọ Ammoni ati Moabu, pẹlu gbogbo awọn ti ndá òṣu, ti ngbe aginju: nitori alaikọla ni gbogbo orilẹ-ède yi, ṣugbọn gbogbo ile Israeli jẹ alaikọla ọkàn.


Gẹgẹ bi a ti kọ ọ ninu ofin Mose, gbogbo ibi wọnyi wá sori wa: bẹ̃li awa kò si wá ojurere niwaju Oluwa, Ọlọrun wa, ki awa ki o le yipada kuro ninu ẹ̀ṣẹ wa, ki a si moye otitọ rẹ.


Awa ti ṣẹ̀, awa si ti nda ẹ̀ṣẹ, awa si ti ṣe buburu gidigidi, awa si ti ṣọ̀tẹ, ani nipa kikuro ninu ẹkọ́ rẹ, ati idajọ rẹ:


Ṣugbọn ọ̀rọ mi ati ilàna mi, ti mo pa li aṣẹ fun awọn iranṣẹ mi woli, nwọn kò ha fi mu awọn baba nyin? nwọn si padà nwọn wipe, Gẹgẹ bi Oluwa awọn ọmọ-ogun ti rò lati ṣe si wa, gẹgẹ bi ọ̀na wa, ati gẹgẹ bi iṣe wa, bẹ̃ni o ti ṣe si wa.


Ani nwọn ṣe aiya wọn bi okuta adamanti, ki nwọn ki o má ba gbọ́ ofin, ati ọ̀rọ ti Ọluwa awọn ọmọ-ogun ti fi ẹmi rẹ̀ rán nipa ọwọ awọn woli iṣãju wá: ibinu nla si de lati ọdọ Ọluwa awọn ọmọ-ogun wá.


Yio si ṣe, gẹgẹ bi ẹnyin ti jẹ egún lãrin awọn keferi, ẹnyin ile Juda, ati ile Israeli, bẹ̃li emi o gbà nyin silẹ; ẹnyin o si jẹ ibukún: ẹ má bẹ̀ru, ṣugbọn jẹ ki ọwọ nyin ki o le.


Bi awọn orilẹ-ède ti OLUWA run kuro niwaju nyin, bẹ̃li ẹnyin o run; nitoripe ẹnyin ṣe àigbọran si ohùn OLUWA Ọlọrun nyin.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan