Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 9:1 - Bibeli Mimọ

1 LI ọdun kini Dariusi, ọmọ Ahasuerusi, lati iru-ọmọ awọn ara Media wá, ti a fi jọba lori ilẹ-ọba awọn ara Kaldea;

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

1 Ní ọdún kinni tí Dariusi, ọmọ Ahasu-erusi, ará Mede, jọba ní Babiloni,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

1 Ní ọdún kìn-ín-ní Dariusi ọmọ Ahaswerusi, ẹni tí a bí ní Media, òun ló jẹ ọba lórí ìjọba Babeli.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 9:1
9 Iomraidhean Croise  

Ati ni ijọba Ahasuerusi, ni ibẹ̀rẹ ijọba rẹ̀, ni nwọn kọwe ẹ̀sun lati fi awọn ara Juda ati Jerusalemu sùn.


O si ṣe li ọjọ Ahaswerusi, (eyi ni Ahaswerusi ti o jọba lati India, ani titi o fi de Etiopia, lori ẹtadiladoje ìgberiko:)


Danieli si wà sibẹ titi di ọdun ikini ti Kirusi, ọba.


Awọn ọmọ ti kò lẹgan lara, ṣugbọn awọn ti o ṣe arẹwa, ti o si ni ìmọ ninu ọgbọ́n gbogbo, ti o mọ̀ oye, ti o si ni iyè ninu, ati iru awọn ti o yẹ lati duro li ãfin ọba ati awọn ti a ba ma kọ́ ni iwe ati ede awọn ara Kaldea.


PẸLUPẸLU li ọdun kini Dariusi ara Media, emi pãpa duro lati mu u lọkàn le, ati lati fi idi rẹ̀ kalẹ.


Dariusi, ara Media si gba ijọba na, o si jẹ bi ẹni iwọn ọdun mejilelọgọta.


O ṣe didùn inu Dariusi lati fi ọgọfa arẹ bãlẹ sori ijọba na, ti yio wà lori gbogbo ijọba;


Bẹ̃ni Danieli yi si nṣe rere ni igba ijọba Dariusi, ati ni igba ijọba Kirusi, ara Persia.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan