Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 8:8 - Bibeli Mimọ

8 Nigbana ni obukọ na nṣe ohun nla pupọpupọ, nigbati o si di alagbara tan, iwo nla na ṣẹ́; ati nipò rẹ̀ iwo mẹrin miran ti iṣe afiyesi si yọ jade si ọ̀na afẹfẹ mẹrẹrin ọrun.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

8 Òbúkọ náà bẹ̀rẹ̀ sí tóbi sí i, ṣugbọn nígbà tí agbára rẹ̀ dé góńgó, ìwo ńlá iwájú rẹ̀ bá kán. Ìwo ńlá mẹrin mìíràn sì hù dípò rẹ̀. Wọ́n kọjú sí ọ̀nà mẹrẹẹrin tí afẹ́fẹ́ ti ń fẹ́ wá.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

8 Òbúkọ náà sì di alágbára púpọ̀, ṣùgbọ́n nígbà tí ó dé góńgó, agbára rẹ̀ ru sókè, ìwo ńlá a rẹ̀ sì ṣẹ́ dànù, ní ipò o rẹ̀, ìwo mẹ́rin mìíràn hù, ó sì yọrí sí ìhà igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ọ̀run.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 8:8
19 Iomraidhean Croise  

Ṣugbọn nigbati o li agbara tan, ọkàn rẹ̀ gbé ga soke si iparun; nitoriti o ṣe irekọja si Oluwa Ọlọrun rẹ̀, o si lọ sinu tempili Oluwa, lati sun turari lori pẹpẹ turari.


Nitori Mordekai tobi ni ile ọba, okiki rẹ̀ si kàn ja gbogbo ìgberiko: nitori ọkunrin yi Mordekai ntobi siwaju ati siwaju.


Ati sori Elamu ni emi o mu afẹfẹ mẹrin lati igun mẹrẹrin ọrun wá, emi o si tú wọn ka si gbogbo ọ̀na afẹfẹ wọnni, kì o si sí orilẹ-ède kan, nibiti awọn ãsá Elamu kì yio de.


Bi àgo ti o kún fun ẹiyẹ, bẹ̃ni ile wọn kún fun ẹ̀tan, nitorina ni nwọn ṣe di nla, nwọn si di ọlọrọ̀.


Emi ti mu ọ bi si i bi irudi itàna ìgbẹ; iwọ si ti pọ̀ si i, o si ti di nla, iwọ si gbà ohun ọṣọ́ ti o ti inu ọṣọ́ wá: a ṣe ọmú rẹ yọ, irun rẹ si dagba, nigbati o jẹ pe iwọ ti wà nihoho ti o si wà goloto.


Iwọ ha le sọ sibẹ niwaju ẹni ti npa ọ, pe, Emi li Ọlọrun? ṣugbọn enia ni iwọ, o kì yio si jẹ Ọlọrun, lọwọ ẹniti npa ọ.


Nigbati on ba dide tan, ijọba rẹ̀ yio fọ́, a o si pin i si orígun mẹrẹrin ọrun; kì si iṣe fun ọmọ rẹ̀, pẹlupẹlu kì si iṣe ninu agbara rẹ̀ ti on fi jọba, nitoriti a o fa ijọba rẹ̀ tu, ani fun ẹlomiran lẹhin awọn wọnyi.


Bi ọ̀rọ na si ti wà lẹnu ọba, ohùn kan fọ̀ lati ọrun wá, pe, Nebukadnessari, ọba, iwọ li a sọ fun; pe, a gba ijọba kuro lọwọ rẹ.


Ṣugbọn nigbati ọkàn rẹ̀ gbega, ti inu rẹ̀ si le nipa igberaga, a mu u kuro lori itẹ rẹ̀, nwọn si gba ogo rẹ̀ lọwọ rẹ̀:


Danieli dahùn, o si wipe, Mo ri ni iran mi li oru, si kiyesi i, afẹfẹ mẹrẹrin ọrun njà loju okun nla.


Lẹhin eyi, mo ri, si kiyesi i, ẹranko miran, gẹgẹ bi ẹkùn, ti o ni iyẹ-apa ẹiyẹ mẹrin li ẹhin rẹ̀; ẹranko na ni ori mẹrin pẹlu; a si fi agbara ijọba fun u.


Njẹ bi eyini si ti ṣẹ́, ti iwo mẹrin miran si dide duro nipò rẹ̀, ijọba mẹrin ni yio dide ninu orilẹ-ède na, ṣugbọn kì yio ṣe ninu agbara rẹ̀.


Bi mo si ti nwoye, kiyesi i, obukọ kan ti iha iwọ-õrùn jade wá sori gbogbo aiye, kò si fi ẹsẹ kan ilẹ: obukọ na si ni iwo nla kan lãrin oju rẹ̀.


Mo si ri i, o sunmọ ọdọ́-àgbo na, o si fi ikoro ibinu sare si i, o lu àgbo na bolẹ, o si ṣẹ́ iwo rẹ̀ mejeji: kò si si agbara ninu àgbo na, lati duro niwaju rẹ̀, ṣugbọn o lù u bolẹ o si tẹ̀ ẹ mọlẹ: kò si si ẹniti o le gbà àgbo na lọwọ rẹ̀.


Yio si rán awọn angẹli rẹ̀ ti awọn ti ohùn ipè nla, nwọn o si kó gbogbo awọn ayanfẹ rẹ̀ lati ori igun mẹrẹrin aiye jọ, lati ikangun ọrun kan lọ de ikangun keji.


Nigbana ni yio si rán awọn angẹli rẹ̀, yio si kó gbogbo awọn ayanfẹ rẹ̀ lati ori igun mẹrẹrin aiye jọ, lati ikangun aiye titi de ikangun ọrun.


Nitoripe nigbati emi ba mú wọn wá si ilẹ na, ti mo bura fun awọn baba wọn, ilẹ ti nṣàn fun warà ati fun oyin; ti nwọn ba si jẹ ajẹyo tán, ti nwọn si sanra; nigbana ni nwọn o yipada si oriṣa, nwọn a si ma sìn wọn, nwọn a si kẹ́gan mi, nwọn a si dà majẹmu mi.


LẸHIN eyi ni mo ri angẹli mẹrin duro ni igun mẹrẹrin aiye, nwọn di afẹfẹ mẹrẹrin aiye mu, ki o máṣe fẹ́ sori ilẹ, tabi sori okun, tabi sara igikigi.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan