Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 8:5 - Bibeli Mimọ

5 Bi mo si ti nwoye, kiyesi i, obukọ kan ti iha iwọ-õrùn jade wá sori gbogbo aiye, kò si fi ẹsẹ kan ilẹ: obukọ na si ni iwo nla kan lãrin oju rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

5 Bí mo tí ń ronú nípa rẹ̀, mo rí i tí òbúkọ kan ti ìhà ìwọ̀ oòrùn la gbogbo ayé kọjá wá láìfi ẹsẹ̀ kan ilẹ̀, ó sì ní ìwo ńlá kan láàrin ojú rẹ̀ mejeeji.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

5 Bí mo ṣe ń ronú nípa èyí, lójijì ni òbúkọ kan tí ó ní ìwo láàrín ojú u rẹ̀ méjèèjì jáde láti ìhà ìwọ̀-oòrùn, ó la gbogbo ayé kọjá láìfi ara kan ilẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 8:5
7 Iomraidhean Croise  

Ọba alagbara kan yio si dide, yio si fi agbara nla ṣe akoso, yio si ma ṣe gẹgẹ bi ifẹ inu rẹ̀.


Eyi ni ere na; ori rẹ̀ jẹ wura daradara, aiya ati apa rẹ̀ jẹ fadaka, inu ati ẹ̀gbẹ rẹ̀ jẹ idẹ,


Lẹhin rẹ ni ijọba miran yio si dide ti yio rẹ̀hin jù ọ, ati ijọba kẹta miran ti iṣe ti idẹ, ti yio si ṣe alakoso lori gbogbo aiye.


Lẹhin eyi, mo ri, si kiyesi i, ẹranko miran, gẹgẹ bi ẹkùn, ti o ni iyẹ-apa ẹiyẹ mẹrin li ẹhin rẹ̀; ẹranko na ni ori mẹrin pẹlu; a si fi agbara ijọba fun u.


Obukọ onirun nì li ọba Hellene: iwo nla ti o wà lãrin oju rẹ̀ mejeji li ọba ekini.


O si tọ̀ àgbo ti o ni iwo meji na wá, eyi ti mo ti ri ti o duro lẹba odò na, o si fi irunu agbara sare si i.


Nigbana ni obukọ na nṣe ohun nla pupọpupọ, nigbati o si di alagbara tan, iwo nla na ṣẹ́; ati nipò rẹ̀ iwo mẹrin miran ti iṣe afiyesi si yọ jade si ọ̀na afẹfẹ mẹrẹrin ọrun.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan