Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 8:4 - Bibeli Mimọ

4 Mo si ri àgbo na o nkàn siha iwọ-õrùn, ati si ariwa, ati si gusu; tobẹ ti gbogbo ẹranko kò fi le duro niwaju rẹ̀, bẹ̃ni kò si ẹniti o le gbani lọwọ rẹ̀: ṣugbọn o nṣe gẹgẹ bi ifẹ inu rẹ̀, o si nṣe ohun nlanla.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

4 Mo rí i tí àgbò náà bẹ̀rẹ̀ sí kàn sí ìhà ìwọ̀ oòrùn, ati sí ìhà àríwá ati sí ìhà gúsù, kò sí ẹranko tí ó lè dúró níwájú rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ẹni tí ó lè gbani sílẹ̀ lọ́wọ́ rẹ̀. Ó bẹ̀rẹ̀ sí ṣe bí ó ti wù ú, ó sì ń gbéraga.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

4 Mo rí àgbò náà ó ń kàn sí ìhà ìwọ̀-oòrùn, sí àríwá, àti sí gúúsù, kò sí ẹranko kankan tí ó le è dojúkọ ọ́, kò sí ẹnìkan tí ó le è yọ ọ́ kúrò lọ́wọ́ agbára rẹ̀, ó ń ṣe bí ó ti wù ú, ó sì di alágbára.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 8:4
18 Iomraidhean Croise  

Sedekiah, ọmọ Kenaana si ṣe iwo irin fun ara rẹ̀, o si wipe: Bayi li Oluwa wi, Wọnyi ni iwọ o fi kàn ara Siria titi iwọ o fi run wọn.


Iwọ mọ̀ pe emi kì iṣe oniwa-buburu, kò si sí ẹniti igbà kuro li ọwọ rẹ.


Nipasẹ̀ rẹ li awa o bì awọn ọta wa ṣubu: nipasẹ orukọ rẹ li awa o tẹ̀ awọn ti o dide si wa mọlẹ.


Njẹ rò eyi, ẹnyin ti o gbagbe Ọlọrun, ki emi ki o má ba fà nyin ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ, ti kò si olugbala.


Ki o má ba fa ọkàn mi ya bi kiniun, a yà a pẹrẹpẹrẹ, nigbati kò si oluranlọwọ.


Nitoriti ẹnyin ti fi ẹgbẹ́ ati ejiká gbún, ti ẹ si ti fi iwo nyin kàn gbogbo awọn ti o li àrun titi ẹ fi tú wọn kakiri.


Ṣugbọn ẹniti o tọ̀ ọ wá yio mã ṣe gẹgẹ bi ifẹ inu ara rẹ̀, kì yio si si ẹniti yio duro niwaju rẹ̀; on o si duro ni ilẹ daradara nì, ti yio si fi ọwọ rẹ̀ parun.


Ọba na yio si ma ṣe gẹgẹ bi ifẹ inu rẹ̀; on o si gbé ara rẹ̀ ga, yio si gbéra rẹ̀ ga jù gbogbo ọlọrun lọ, yio si ma sọ̀rọ ohun iyanu si Ọlọrun awọn ọlọrun, yio si ma ṣe rere titi a o fi pari ibinu: nitori a o mu eyi ti a ti pinnu rẹ̀ ṣẹ.


Ati nitori ọlanla ti o fi fun u, gbogbo enia, orilẹ, ati ède gbogbo nwariri, nwọn si mbẹ̀ru niwaju rẹ̀: ẹniti o wù u, a pa, ẹniti o si wù u, a da si lãye; ẹniti o wù u, a gbé ga; ẹniti o si wú u, a rẹ̀ silẹ.


Loru ijọ kanna li a pa Belṣassari, ọba awọn ara Kaldea.


Sa si kiyesi, ẹranko miran, ekeji, ti o dabi ẹranko beari, o si gbé ara rẹ̀ soke li apakan, o si ni egungun-ìha mẹta lẹnu rẹ̀ larin ehin rẹ̀: nwọn si wi fun u bayi pe, Dide ki o si jẹ ẹran pipọ.


Mo si ri i, o sunmọ ọdọ́-àgbo na, o si fi ikoro ibinu sare si i, o lu àgbo na bolẹ, o si ṣẹ́ iwo rẹ̀ mejeji: kò si si agbara ninu àgbo na, lati duro niwaju rẹ̀, ṣugbọn o lù u bolẹ o si tẹ̀ ẹ mọlẹ: kò si si ẹniti o le gbà àgbo na lọwọ rẹ̀.


Iyokù Jakobu yio si wà lãrin awọn Keferi, lãrin ọ̀pọ enia bi kiniun, lãrin awọn ẹranko igbo, bi ọmọkiniun lãrin agbo agutan; eyiti, bi o ba là a ja, ti itẹ̀ mọlẹ, ti isi ifa ya pẹrẹpẹrẹ, kò si ẹniti yio gbalà.


Akọ́bi akọmalu rẹ̀, tirẹ̀ li ọlánla; iwo rẹ̀ iwo agbanrere ni: on ni yio fi tì awọn enia, gbogbo wọn, ani opin ilẹ: awọn si ni ẹgbẹgbãrun Efraimu, awọn si ni ẹgbẹgbẹrun Manasse.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan