Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 8:21 - Bibeli Mimọ

21 Obukọ onirun nì li ọba Hellene: iwo nla ti o wà lãrin oju rẹ̀ mejeji li ọba ekini.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

21 Ìjọba Giriki ni òbúkọ onírun jákujàku tí o rí. Ọba àkọ́kọ́ tí yóo jẹ níbẹ̀ ni ìwo ńlá tí ó wà láàrin ojú rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

21 Òbúkọ onírun náà ni ọba Giriki, ìwo ńlá ti ó wà láàrín ojú u rẹ̀ ni ọba àkọ́kọ́.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 8:21
9 Iomraidhean Croise  

Nigbana ni o wipe, Iwọ, ha mọ̀ idi ohun ti mo tọ̀ ọ wá si? nisisiyi li emi o si yipada lọ iba balogun Persia jà: nigbati emi ba si jade lọ, kiyesi i, balogun Hellene yio wá.


Njẹ nisisiyi li emi o fi otitọ hàn ọ, Kiyesi i, ọba mẹta pẹlu ni yio dide ni Persia; ẹkẹrin yio si ṣe ọlọrọ̀ jù gbogbo wọn lọ: ati nipa agbara rẹ̀ ni yio fi fi ọrọ̀ rú gbogbo wọn soke si ijọba Hellene.


Ọba alagbara kan yio si dide, yio si fi agbara nla ṣe akoso, yio si ma ṣe gẹgẹ bi ifẹ inu rẹ̀.


Lẹhin rẹ ni ijọba miran yio si dide ti yio rẹ̀hin jù ọ, ati ijọba kẹta miran ti iṣe ti idẹ, ti yio si ṣe alakoso lori gbogbo aiye.


Lẹhin eyi, mo ri, si kiyesi i, ẹranko miran, gẹgẹ bi ẹkùn, ti o ni iyẹ-apa ẹiyẹ mẹrin li ẹhin rẹ̀; ẹranko na ni ori mẹrin pẹlu; a si fi agbara ijọba fun u.


Agbò na ti iwọ ri ti o ni iwo meji nì, awọn ọba Media ati Persia ni nwọn.


Njẹ bi eyini si ti ṣẹ́, ti iwo mẹrin miran si dide duro nipò rẹ̀, ijọba mẹrin ni yio dide ninu orilẹ-ède na, ṣugbọn kì yio ṣe ninu agbara rẹ̀.


Nitori mo fa Juda le bi ọrun mi, mo si fi Efraimu kún u, mo si gbe awọn ọmọ rẹ ọkunrin dide, iwọ Sioni, si awọn ọmọ rẹ ọkunrin, iwọ ilẹ Griki, mo ṣe ọ bi idà alagbara.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan