Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 8:2 - Bibeli Mimọ

2 Emi si ri loju iran, o si ṣe nigbati mo ri, ti mo si wà ni Ṣuṣani, li ãfin, ti o wà ni igberiko Elamu, mo si ri loju iran, mo si wà leti odò Ulai.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

2 Ninu ìran náà, mo rí i pé mo wà ní Susa, olú-ìlú tí ó wà ní agbègbè Elamu. Mo rí i pé mo wà létí odò Ulai.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

2 Nínú ìran náà, mo rí ara mi nínú ilé ìṣọ́ ní Susa ní agbègbè ìjọba Elamu: nínú ìran náà mo wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ odò Ulai.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 8:2
24 Iomraidhean Croise  

Awọn ọmọ Ṣemu: Elamu, ati Aṣṣuri, ati Arfaksadi, ati Ludi, ati Aramu.


O SI ṣe li ọjọ́ Amrafeli ọba Ṣinari, Arioku ọba Ellasari, Kedorlaomeri ọba Elamu, ati Tidali ọba awọn orilẹ-ède;


Ọ̀RỌ Nehemiah ọmọ Hakaliah. O si ṣe ninu oṣu Kisleu, ni ogún ọdun, nigba tí mo wà ni Ṣuṣani ãfin.


Li ọjọ wọnni, nigbati Ahaswerusi, ọba, joko lori itẹ ijọba rẹ̀, ti o wà ni Ṣuṣani, ãfin.


O si ṣe, nigbati a gbọ́ ofin ọba, ati aṣẹ rẹ̀, nigbati a si ṣà ọ̀pọlọpọ wundia jọ si Ṣuṣani ãfin, si ọwọ Hegai, a si mu Esteri wá si ile ọba pẹlu si ọwọ Hegai, olutọju awọn obinrin.


Awọn ojiṣẹ na jade lọ, nwọn si yara, nitori aṣẹ ọba ni, a si pa aṣẹ na ni Ṣuṣani ãfin. Ati ọba ati Hamani joko lati mu ọti; ṣugbọn ilu Ṣuṣani dãmu.


Esteri si wi pe, ọlọtẹ enia ati ọta na ni Hamani, ẹni buburu yi. Nigbana ni ẹ̀ru ba Hamani niwaju ọba ati ayaba.


Mordekai si jade kuro niwaju ọba, ninu aṣọ ọba, alaro ati funfun, ati ade wura nla, ati ẹ̀wu okùn ọ̀gbọ kikuná, ati elese aluko; ayọ̀ ati inu didùn si wà ni ilu Ṣuṣani.


Li ọjọ na a mu iye awọn ti a pa ni Ṣuṣani ãfin wá siwaju ọba.


Nitorina awọn Ju ti o wà ni Ṣuṣani kó ara wọn jọ li ọjọ kẹrinla oṣù Adari pẹlu, nwọn si pa ọ̃durun ọkunrin ni Ṣuṣani; ṣugbọn nwọn kò fi ọwọ kàn nkan wọn.


Yio si ṣe li ọjọ na, ni Oluwa yio tun nawọ rẹ̀ lati gbà awọn enia rẹ̀ iyokù padà, ti yio kù, lati Assiria, ati lati Egipti, ati lati Patrosi, ati lati Kuṣi, ati lati Elamu, ati Ṣinari, ati lati Hamati, ati lati awọn erekùṣu okun wá.


Iran lile li a fi hàn mi; ọ̀dalẹ dalẹ, akoni si nkoni. Goke lọ, iwọ Elamu: dotì, iwọ Media; gbogbo ìmí-ẹ̀dùn inu rẹ̀ li emi ti mu da.


Ati gbogbo awọn ọba Simri, ati gbogbo awọn ọba Elamu, ati gbogbo awọn ọba Medea.


O si ṣe ọgbọ̀n ọdun, ni oṣu ẹkẹrin, li ọjọ ẹkarun oṣu, bi mo ti wà lãrin awọn igbekùn leti odo Kebari, ọrun ṣi, mo si ri iran Ọlọrun.


Elamu wà nibẹ, ati gbogbo ọ̀pọlọpọ enia rẹ̀ yi ibojì rẹ̀ ka, gbogbo wọn li a pa, nwọn ti ipa idà ṣubu, ti nwọn sọkalẹ li alaikọla si ìsalẹ aiye, ti o da ẹ̀ru wọn silẹ ni ilẹ alãye; sibẹ nwọn ti rù itiju wọn pẹlu awọn ti o sọkalẹ lọ si ihò.


Nigbati o di ọjọ kẹrinlelogun oṣu kini, bi mo ti wà li eti odò nla, ti ijẹ Hiddekeli;


Ẹmi emi Danieli si rẹwẹsi ninu ara mi, iran ori mi si mu mi dãmu.


Danieli dahùn, o si wipe, Mo ri ni iran mi li oru, si kiyesi i, afẹfẹ mẹrẹrin ọrun njà loju okun nla.


LI ọdun kẹta ijọba Belṣassari ọba, iran kan fi ara hàn fun mi, ani emi Danieli, lẹhin iran ti emi ri ni iṣaju.


Mo si gbé oju mi soke, mo si ri, si kiye si i, àgbo kan ti o ni iwo meji duro lẹba odò na: iwo mejeji na si ga, ṣugbọn ekini ga jù ekeji lọ, eyiti o ga jù li o jade kẹhin.


O si wipe, Ẹ gbọ́ ọ̀rọ mi nisisiyi: bi wolĩ OLUWA ba mbẹ ninu nyin, emi OLUWA yio farahàn fun u li ojuran, emi o si bá a sọ̀rọ li oju-alá.


ỌLỌRUN, ẹni, ni igba pupọ̀ ati li onirũru ọna, ti o ti ipa awọn woli ba awọn baba sọ̀rọ nigbãni.


Bayi ni mo si ri awọn ẹṣin na li ojuran, ati awọn ti o gùn wọn; nwọn ni awo ìgbaiya iná, ati ti jakinti, ati ti imí ọjọ: ori awọn ẹṣin na si dabi ori awọn kiniun; ati lati ẹnu wọn ni iná, ati ẹ̃fin, ati imí ọjọ ti njade.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan