Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 8:16 - Bibeli Mimọ

16 Emi si gbọ́ ohùn enia kan lãrin odò Ulai, ti o pè, ti o si wi pe, Gabrieli, mu ki eleyi moye iran na.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

16 Mo gbóhùn ẹnìkan láàrin bèbè kinni keji odò Ulai tí ó wí pé, “Geburẹli, sọ ìtumọ̀ ìran tí ọkunrin yìí rí fún un.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

16 Mo gbọ́ ohùn ènìyàn ní ẹ̀gbẹ́ Ulai, tí ó ń ké pé “Gebrieli, sọ ìtumọ̀ ìran náà fún ọkùnrin yìí.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 8:16
16 Iomraidhean Croise  

Njẹ nisisiyi, mo de lati mu ọ moye ohun ti yio ba awọn enia rẹ ni ikẹhin ọjọ: nitori ti ọjọ pipọ ni iran na iṣe.


Ṣugbọn emi o fi eyi ti a kọ sinu iwe otitọ hàn ọ: kò si si ẹniti o ràn mi lọwọ si awọn wọnyi, bikoṣe Mikaeli balogun nyin.


Mo sunmọ ọkan ninu awọn ti o duro lapakan, mo si bi i lere otitọ gbogbo nkan wọnyi. Bẹ̃li o sọ fun mi, o si fi itumọ nkan wọnyi hàn fun mi.


Emi si ri loju iran, o si ṣe nigbati mo ri, ti mo si wà ni Ṣuṣani, li ãfin, ti o wà ni igberiko Elamu, mo si ri loju iran, mo si wà leti odò Ulai.


Nigbana ni mo wipe, Kini wọnyi oluwa mi? Angeli ti mba mi sọ̀rọ si wi fun mi pe, emi o fi ohun ti wọnyi jẹ hàn ọ.


O si wi fun u pe, Sare, sọ fun ọdọmọkunrin yi wipe, a o gbe inu Jerusalemu bi ilu ti kò ni odi nitori ọ̀pọ enia ati ohun-ọsìn inu rẹ̀:


Angẹli na si dahùn o wi fun u pe, Emi ni Gabrieli, ti ima duro niwaju Ọlọrun; emi li a rán wá lati sọ fun ọ, ati lati mu ìhin ayọ̀ wọnyi fun ọ wá.


Li oṣù kẹfa a si rán angẹli Gabrieli lati ọdọ Ọlọrun lọ si ilu kan ni Galili, ti a npè ni Nasareti,


Ohùn kan si fọ̀ si i pe, Dide, Peteru; mã pa ki o si mã jẹ.


Awọn ọkunrin ti nwọn si mba a re àjo duro, kẹ́kẹ pa mọ́ wọn li ẹnu, nwọn gbọ́ ohùn na, ṣugbọn nwọn kò ri ẹnikan.


Ẹmí ti njiṣẹ ki gbogbo wọn iṣe, ti a nran lọ lati mã jọsin nitori awọn ti yio jogun igbala?


Mo si yipada lati wò ohùn ti mba mi sọ̀rọ. Nigbati mo yipada, mo ri ọpá fitila wura meje;


Emi Jesu li o rán angẹli mi lati jẹri nkan wọnyi fun nyin niti awọn ijọ. Emi ni gbòngbo ati iru-ọmọ Dafidi, ati irawọ owurọ̀ ti ntàn.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan