Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 8:12 - Bibeli Mimọ

12 A si fi ogun le e lọwọ pẹlu ẹbọ ojojumọ nitori irekọja, o si ja otitọ lulẹ, o si nṣe eyi, o si nri rere.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

12 A fi ogun náà ati ẹbọ sísun ojoojumọ lé e lọ́wọ́ nítorí ẹ̀ṣẹ̀, a sì já òtítọ́ lulẹ̀. Gbogbo ohun tí ìwo náà ń ṣe, ni ó ṣe ní àṣeyọrí.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

12 A fún un ní ẹgbẹ́ ogun ọ̀run àti ẹbọ ojoojúmọ́ nítorí ìwà ọlọ̀tẹ̀ ẹ rẹ̀: ó sọ òtítọ́ nù nínú gbogbo ohun tó ṣe.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 8:12
14 Iomraidhean Croise  

Agọ awọn igara ngberú, awọn ti o si nmu Ọlọrun binu wà lailewu, awọn ẹniti o si gbá oriṣa mu li ọwọ wọn.


Ododo rẹ ododo lailai ni, otitọ si li ofin rẹ.


Lõtọ máṣe gbà ọ̀rọ otitọ kuro li ẹnu mi rara; nitori ti mo ti nṣe ireti ni idajọ rẹ.


Nitori ti nwọn kò kà iṣẹ Oluwa si, tabi iṣẹ ọwọ rẹ̀; on o run wọn, kì yio si gbé wọn ró.


A dá idajọ pada, ẹtọ́ si duro lokerè rére: otitọ ṣubu ni igboro, aiṣègbe kò le wọ ile.


ALARE ni iwọ, Oluwa, nigbati mo mba ọ wijọ: sibẹ, jẹ ki emi ba ọ sọ ti ọ̀ran idajọ: ẽtiṣe ti ãsiki mbẹ ni ọ̀na enia buburu, ti gbogbo awọn ti nṣe ẹ̀tan jẹ alailewu.


Nigbana ni yio pada lọ si ilẹ ontikararẹ̀ ti on ti ọrọ̀ pupọ: ọkàn rẹ̀ yio si lodi si majẹmu mimọ́ nì, yio ṣe e, yio si pada lọ si ilẹ ontikararẹ̀.


Mo ri iwo kanna si mba awọn enia-mimọ́ jagun, o si bori wọn.


Mo si ri àgbo na o nkàn siha iwọ-õrùn, ati si ariwa, ati si gusu; tobẹ ti gbogbo ẹranko kò fi le duro niwaju rẹ̀, bẹ̃ni kò si ẹniti o le gbani lọwọ rẹ̀: ṣugbọn o nṣe gẹgẹ bi ifẹ inu rẹ̀, o si nṣe ohun nlanla.


A si fi fun u lati mã ba awọn enia mimọ́ jagun, ati lati ṣẹgun wọn: a si fi agbara fun u lori gbogbo ẹya, ati enia, ati ède, ati orilẹ.


Dafidi si mọ̀ pe Saulu ti gbèro buburu si on; o si wi fun Abiatari alufa na pe, Mu efodu na wá nihinyi.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan