Daniẹli 8:11 - Bibeli Mimọ11 Ani o gbé ara rẹ̀ ga titi de ọdọ olori awọn ogun na pãpa, a si ti mu ẹbọ ojojumọ kuro lọdọ rẹ̀, a si wó ibujoko ìwa-mimọ́ rẹ̀ lulẹ. Faic an caibideilYoruba Bible11 Ó gbé ara rẹ̀ ga, títí dé ọ̀dọ̀ olórí àwọn ogun ọ̀run. Ó gbé ẹbọ sísun ojoojumọ kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì gba ibi mímọ́ rẹ̀. Faic an caibideilBíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní11 ó sì gbé ara rẹ̀ ga gẹ́gẹ́ bí ọmọ-aládé ẹgbẹ́ ogun ọ̀run; ó sì mú ẹbọ ojoojúmọ́ kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì gba ààyè ibi mímọ́ rẹ̀. Faic an caibideil |
Ṣugbọn iwọ gbé ara rẹ ga si Oluwa ọrun, nwọn si ti mu ohun-elo ile rẹ̀ wá siwaju rẹ, iwọ ati awọn ijoye rẹ, ati awọn aya rẹ, ati awọn àle rẹ si ti nmu ọti-waini ninu wọn; iwọ si ti nkọrin iyìn si oriṣa fadaka, ati ti wura, ti idẹ, ti irin, ti igi, ati ti okuta, awọn ti kò riran, ti kò gbọran, bẹ̃ni nwọn kò si mọ̀: ṣugbọn Ọlọrun na, lọwọ ẹniti ẹmi rẹ wà, ati ti ẹniti gbogbo ọ̀na rẹ iṣe on ni iwọ kò bu ọlá fun.