Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 8:10 - Bibeli Mimọ

10 O si di alagbara, titi de ogun ọrun, o si bì ṣubu ninu awọn ogun ọrun, ati ninu awọn irawọ si ilẹ, o si tẹ̀ wọn mọlẹ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

10 Ó tóbi pupọ tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi ń bá àwọn ogun ọ̀run jà, ó já àwọn kan ninu àwọn ìràwọ̀ lulẹ̀, ó sì fi ẹsẹ̀ tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

10 Ó sì dàgbà títí ó fi kan ẹgbẹ́ ogun ọ̀run, ó sì jù lára àwọn ẹgbẹ́ ogun ọ̀run sí ayé ó sì tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 8:10
9 Iomraidhean Croise  

Nitori iwọ ti wi li ọkàn rẹ pe, Emi o goke lọ si ọrun, emi o gbe itẹ mi ga kọja iràwọ Ọlọrun: emi o si joko lori oke ijọ enia ni iha ariwa:


Ẹ mu u yo bi ọmuti: nitori o gberaga si Oluwa: Moabu yio si ma pàfọ ninu ẽbi rẹ̀; on pẹlu yio si di ẹni-ẹ̀gan.


Nigbana ni yio pada lọ si ilẹ ontikararẹ̀ ti on ti ọrọ̀ pupọ: ọkàn rẹ̀ yio si lodi si majẹmu mimọ́ nì, yio ṣe e, yio si pada lọ si ilẹ ontikararẹ̀.


Nitoripe ọkọ̀ awọn ara Kittimu yio tọ̀ ọ wá, nitorina ni yio ṣe dãmu, yio si yipada, yio si ni ibinu si majẹmu mimọ́ nì; bẹ̃ni yio ṣe; ani on o yipada, yio si tun ni idapọ pẹlu awọn ti o kọ̀ majẹmu mimọ́ na silẹ.


Lẹhin eyi, mo ri ni iran oru, si kiyesi i, ẹranko kẹrin ti o burujù, ti o si lẹrù, ti o si lagbara gidigidi; o si ni ehin irin nla: o njẹ o si nfọ tũtu, o si fi ẹsẹ rẹ̀ tẹ̀ iyokù mọlẹ: o si yatọ si gbogbo awọn ẹranko ti o ṣiwaju rẹ̀; o si ni iwo mẹwa.


Mo si ri i, o sunmọ ọdọ́-àgbo na, o si fi ikoro ibinu sare si i, o lu àgbo na bolẹ, o si ṣẹ́ iwo rẹ̀ mejeji: kò si si agbara ninu àgbo na, lati duro niwaju rẹ̀, ṣugbọn o lù u bolẹ o si tẹ̀ ẹ mọlẹ: kò si si ẹniti o le gbà àgbo na lọwọ rẹ̀.


Ìru rẹ̀ si wọ́ idamẹta awọn irawọ, o si ju wọn si ilẹ aiye, dragoni na si duro niwaju obinrin na ti o fẹ bímọ, pe nigbati o ba bí, ki o le pa ọmọ rẹ̀ jẹ.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan