Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 8:1 - Bibeli Mimọ

1 LI ọdun kẹta ijọba Belṣassari ọba, iran kan fi ara hàn fun mi, ani emi Danieli, lẹhin iran ti emi ri ni iṣaju.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

1 Ní ọdún kẹta tí Beṣasari jọba ni èmi Daniẹli rí ìran kan lẹ́yìn ti àkọ́kọ́.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

1 Nígbà tí ó di ọdún kẹta ìjọba Belṣassari ọba, èmi Daniẹli rí ìran kan èyí tí mo ti rí tẹ́lẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 8:1
11 Iomraidhean Croise  

O si ṣe ọgbọ̀n ọdun, ni oṣu ẹkẹrin, li ọjọ ẹkarun oṣu, bi mo ti wà lãrin awọn igbekùn leti odo Kebari, ọrun ṣi, mo si ri iran Ọlọrun.


Bi o ṣe ti awọn ọmọ mẹrẹrin wọnyi ni, Ọlọrun fun wọn ni ìmọ ati oye ni gbogbo iwe ati ọgbọ́n: Danieli si li oye ni gbogbo iran ati alá.


Li ọjọ wọnni li emi Danieli fi ikãnu ṣọ̀fọ li ọ̀sẹ mẹta gbako.


Emi Danieli nikanṣoṣo li o si ri iran na, awọn ọkunrin ti o si wà pẹlu mi kò ri iran na; ṣugbọn ìwariri nlanla dà bò wọn, tobẹ̃ ti nwọn fi sá lọ lati fi ara wọn pamọ́.


Nigbati on ba dide tan, ijọba rẹ̀ yio fọ́, a o si pin i si orígun mẹrẹrin ọrun; kì si iṣe fun ọmọ rẹ̀, pẹlupẹlu kì si iṣe ninu agbara rẹ̀ ti on fi jọba, nitoriti a o fa ijọba rẹ̀ tu, ani fun ẹlomiran lẹhin awọn wọnyi.


LI ọdun kini Belṣassari, ọba Babeli, ni Danieli lá alá, ati iran ori rẹ̀ lori akete rẹ̀: nigbana ni o kọwe alá na, o si sọ gbogbo ọ̀rọ na.


Ẹmi emi Danieli si rẹwẹsi ninu ara mi, iran ori mi si mu mi dãmu.


Titi de ihinyi li opin ọ̀ran na. Bi o ṣe ti emi Danieli ni, igbero inu mi dãmu mi gidigidi, oju mi si yipada lori mi: ṣugbọn mo pa ọran na mọ́ li ọkàn mi.


O si ṣe ti emi, ani emi Danieli si ti ri iran na, ti mo si nfẹ imọ̀ idi rẹ̀, si kiyesi i, ẹnikan duro niwaju mi, gẹgẹ bi aworan ọkunrin.


Emi si ri loju iran, o si ṣe nigbati mo ri, ti mo si wà ni Ṣuṣani, li ãfin, ti o wà ni igberiko Elamu, mo si ri loju iran, mo si wà leti odò Ulai.


Li ọdun kini ijọba rẹ̀ li emi Danieli fiyesi lati inu iwe, iye ọdun, nipa eyi ti ọ̀rọ Oluwa tọ Jeremiah, woli wá, pe adọrin ọdun li on o mu pé lori idahoro Jerusalemu.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan