Daniẹli 7:9 - Bibeli Mimọ9 Mo si wò titi a fi sọ̀ itẹ́ wọnni kalẹ titi Ẹni-àgba ọjọ na fi joko, aṣọ ẹniti o fún gẹgẹ bi ẹ̀gbọn owu, irun ori rẹ̀ si dabi irun agutan ti o mọ́: itẹ rẹ̀ jẹ ọwọ iná, ayika-kẹkẹ rẹ̀ si jẹ jijo iná. Faic an caibideilYoruba Bible9 “Bí mo ti ń wo ọ̀kánkán, mo rí àwọn ìtẹ́ kan tí a tẹ́. Ẹni Ayérayé sì jókòó lórí ìtẹ́ tirẹ̀, aṣọ rẹ̀ funfun bíi ẹ̀gbọ̀n òwú. Irun orí rẹ̀ náà dàbí irun aguntan funfun, ìtẹ́ rẹ̀ ń jó bí ahọ́n iná, kẹ̀kẹ́ abẹ́ ìtẹ́ rẹ̀ sì dàbí iná. Faic an caibideilBíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní9 “Bí mo ṣe ń wò, “a gbé ìtẹ́ ọba kan kalẹ̀, ẹni ìgbàanì jókòó sórí ìtẹ́ rẹ̀, Aṣọ rẹ̀ funfun bí ẹ̀gbọ̀n òwú; irun orí rẹ̀ funfun bí òwú, ìtẹ́ ọba rẹ̀ rí bí ọwọ́ iná. Àwọn kẹ̀kẹ́ rẹ ń jó bí i iná. Faic an caibideil |
Mo si ri awọn ìtẹ́, nwọn si joko lori wọn, a si fi idajọ fun wọn: mo si ri ọkàn awọn ti a ti bẹ́ lori nitori ẹrí Jesu, ati nitori ọ̀rọ Ọlọrun, ati awọn ti kò si foribalẹ fun ẹranko na, ati fun aworan rẹ̀, tabi ti kò si gbà àmi rẹ̀ ni iwaju wọn ati li ọwọ́ wọn; nwọn si wà lãye, nwọn si jọba pẹlu Kristi li ẹgbẹrun ọdún.