Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 7:7 - Bibeli Mimọ

7 Lẹhin eyi, mo ri ni iran oru, si kiyesi i, ẹranko kẹrin ti o burujù, ti o si lẹrù, ti o si lagbara gidigidi; o si ni ehin irin nla: o njẹ o si nfọ tũtu, o si fi ẹsẹ rẹ̀ tẹ̀ iyokù mọlẹ: o si yatọ si gbogbo awọn ẹranko ti o ṣiwaju rẹ̀; o si ni iwo mẹwa.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

7 “Lẹ́yìn èyí, ninu ìran tí mo rí ní òru náà, ẹranko kẹrin tí mo rí jáni láyà, ó bani lẹ́rù, ó sì lágbára pupọ. Ó tóbi, irin sì ni eyín rẹ̀. A máa fọ́ nǹkan túútúú, á jẹ ẹ́ ní àjẹrun, á sì fi ẹsẹ̀ tẹ àjẹkù rẹ̀ mọ́lẹ̀. Ó yàtọ̀ sí gbogbo àwọn ẹranko tí ó ti wà ṣáájú rẹ̀, ìwo mẹ́wàá ni ó ní.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

7 “Lẹ́yìn èyí, nínú ìran mi ní òru mo tún rí ẹranko kẹrin, ó dẹ́rùbà ni, ó dáyà fo ni, ó sì lágbára gidigidi. Ó ní eyín irin ńlá; ó ń jẹ, ó sì ń fọ́ túútúú, ó sì fi ẹsẹ̀ tẹ èyí tókù mọ́lẹ̀. Ó yàtọ̀ sí gbogbo àwọn ẹranko ti ìṣáájú, ó sì ní ìwo mẹ́wàá.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 7:7
17 Iomraidhean Croise  

Nigbana ni emi si gun wọn wẹwẹ bi erupẹ ilẹ, emi si tẹ̀ wọn mọlẹ bi ẹrẹ̀ ita, emi si tẹ wọn gbọrọ.


Tani o le iṣi ilẹkun iwaju rẹ̀? ayika ehin rẹ̀ ni ìbẹru nla.


Ninu iran Ọlọrun li o mu mi wá si ilẹ Israeli, o si gbe mi ka oke giga kan, lori eyiti kikọ ilu wà ni iha gusu.


Nigbana ni a fi aṣiri na hàn fun Danieli ni iran li oru, Danieli si fi ibukún fun Ọlọrun, Oluwa ọrun.


Mo ri ni iran oru, si kiyesi i, ẹnikan bi Ọmọ enia wá pẹlu awọsanma ọrun, o si wá sọdọ Ẹni-Àgba ọjọ na, nwọn si mu u sunmọ iwaju rẹ̀.


Danieli dahùn, o si wipe, Mo ri ni iran mi li oru, si kiyesi i, afẹfẹ mẹrẹrin ọrun njà loju okun nla.


O si di alagbara, titi de ogun ọrun, o si bì ṣubu ninu awọn ogun ọrun, ati ninu awọn irawọ si ilẹ, o si tẹ̀ wọn mọlẹ.


Njẹ bi eyini si ti ṣẹ́, ti iwo mẹrin miran si dide duro nipò rẹ̀, ijọba mẹrin ni yio dide ninu orilẹ-ède na, ṣugbọn kì yio ṣe ninu agbara rẹ̀.


MO si tun gbe oju mi soke, mo si wò, si kiyesi i, ọkunrin kan ti on ti okùn-iwọ̀n lọwọ rẹ̀.


Àmi miran si hàn li ọrun; si kiyesi i, dragoni pupa nla kan, ti o ni ori meje ati iwo mẹwa, ati adé meje li ori rẹ̀.


O si duro lori iyanrìn okun, mo si ri ẹranko kan nti inu okun jade wá, o ni ori meje ati iwo mẹwa, ati ade mẹwa lori awọn iwo na, ati li awọn ori rẹ̀ na ni orukọ ọrọ-odi.


Iwo mẹwa ti iwọ si ri nì ọba mẹwa ni nwọn, ti nwọn kò iti gba ijọba; ṣugbọn nwọn gba ọla bi ọba pẹlu ẹranko na fun wakati kan.


Angẹli si wi fun mi pe, Nitori kili ẹnu ṣe yà ọ? emi o sọ ti ijinlẹ obinrin na fun ọ, ati ti ẹranko ti o gùn, ti o ni ori meje ati iwo mẹwa.


Ẹranko ti iwọ ri nì, o ti wà, kò si sí mọ́: yio si ti inu ọgbun gòke wá, yio si lọ sinu egbé: ẹnu yio si yà awọn ti ngbé ori ilẹ aiye, orukọ awọn ẹniti a kò ti kọ sinu iwe ìye lati ipilẹṣẹ aiye, nigbati nwọn nwò ẹranko ti o ti wà, ti kò si sí mọ́, ti o si mbọ̀wá.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan