Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 7:5 - Bibeli Mimọ

5 Sa si kiyesi, ẹranko miran, ekeji, ti o dabi ẹranko beari, o si gbé ara rẹ̀ soke li apakan, o si ni egungun-ìha mẹta lẹnu rẹ̀ larin ehin rẹ̀: nwọn si wi fun u bayi pe, Dide ki o si jẹ ẹran pipọ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

5 “Ẹranko keji dàbí àmọ̀tẹ́kùn, ó gbé ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ kan sókè. Ó gbé egungun ìhà mẹta há ẹnu, ó wa eyín mọ́ ọn. Mo sì gbọ́ tí ẹnìkan sọ fún un pé, ‘Dìde, kí o sì máa jẹ ẹran sí i.’

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

5 “Mo sì tún rí ẹranko kejì, ó rí bí irú ẹranko ńlá beari kan tí ó ń gbé ilẹ̀ òtútù; o gbé ara sókè ní apá kan, ó sì ní egungun ìhà mẹ́ta láàrín ẹ̀yìn in rẹ̀, wọ́n sì sọ fún un pé, ‘Dìde kí o sì jẹ ẹran tó pọ̀!’

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 7:5
14 Iomraidhean Croise  

O si yipada, o si wò wọn, o si fi wọn bú li orukọ Oluwa. Abo-beari meji si jade lati inu igbó wá, nwọn si fà mejilelogoji ya ninu wọn.


O yá ki ẹranko beari ti a kó li ọmọ ki o pade enia, jù aṣiwère lọ ninu wère rẹ̀.


Gbogbo ẹnyin ẹranko igbẹ, ẹ wá lati pajẹ ani gbogbo ẹranko igbẹ.


Njẹ nisisiyi li emi o fi otitọ hàn ọ, Kiyesi i, ọba mẹta pẹlu ni yio dide ni Persia; ẹkẹrin yio si ṣe ọlọrọ̀ jù gbogbo wọn lọ: ati nipa agbara rẹ̀ ni yio fi fi ọrọ̀ rú gbogbo wọn soke si ijọba Hellene.


Lẹhin rẹ ni ijọba miran yio si dide ti yio rẹ̀hin jù ọ, ati ijọba kẹta miran ti iṣe ti idẹ, ti yio si ṣe alakoso lori gbogbo aiye.


PERESINI; A pin ijọba rẹ, a si fi fun awọn ara Media, ati awọn ara Persia.


Ẹranko kini dabi kiniun, o si ni iyẹ-apa idì: mo si wò titi a fi fà iyẹ-apa rẹ̀ wọnni tu, a si gbé e soke kuro ni ilẹ, a mu ki o fi ẹsẹ duro bi enia, a si fi aiya enia fun u.


Lẹhin eyi, mo ri, si kiyesi i, ẹranko miran, gẹgẹ bi ẹkùn, ti o ni iyẹ-apa ẹiyẹ mẹrin li ẹhin rẹ̀; ẹranko na ni ori mẹrin pẹlu; a si fi agbara ijọba fun u.


Emi o pade wọn bi beari ti a gbà li ọ̀mọ, emi o si fà àwọn ọkàn wọn ya, nibẹ̀ ni emi o si jẹ wọn run bi kiniun, ẹranko igbẹ ni yio fà wọn ya.


Ẹranko ti mo ri na si dabi ẹkùn, ẹsẹ rẹ̀ si dabi ti beari, ẹnu rẹ̀ si dabi ti kiniun: dragoni na si fun u li agbara rẹ̀, ati itẹ rẹ̀, ati ọlá nla.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan