Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 7:4 - Bibeli Mimọ

4 Ẹranko kini dabi kiniun, o si ni iyẹ-apa idì: mo si wò titi a fi fà iyẹ-apa rẹ̀ wọnni tu, a si gbé e soke kuro ni ilẹ, a mu ki o fi ẹsẹ duro bi enia, a si fi aiya enia fun u.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

4 Ekinni dàbí kinniun, ó sì ní ìyẹ́ bíi ti idì. Mò ń wò ó títí tí ìyẹ́ rẹ̀ fi fà tu. A gbé e dìde lórí ẹsẹ̀ rẹ̀ mejeeji bí eniyan. Ó sì ń ronú bí eniyan.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

4 “Ẹranko kìn-ín-ní dàbí i kìnnìún, ó sì ní ìyẹ́ apá a idì: mo sì wò títí a fi fa ìyẹ́ apá rẹ̀ náà tu, a sì gbé e sókè kúrò ní ilẹ̀, a mú kí ó fi ẹsẹ̀ dúró bí ènìyàn, a sì fi àyà ènìyàn fún un.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 7:4
27 Iomraidhean Croise  

Saulu ati Jonatani ni ifẹni si ara wọn, nwọn si dùn li ọjọ aiye wọn, ati ni ikú wọn, nwọn kò ya ara wọn: nwọn yara ju idì lọ, nwọn si li agbara ju kiniun lọ.


Ambọtori enia ti iṣe idin, ati ọmọ enia, ti iṣe kòkoro!


Dẹru ba wọn, Oluwa: ki awọn orilẹ-ède ki o le mọ̀ ara wọn pe, enia ṣa ni nwọn.


O ti fi pantiri rẹ̀ silẹ bi kiniun nitori ti ilẹ wọn di ahoro, niwaju ibinu idà aninilara, ati niwaju ibinu kikan rẹ̀.


Sa wò o, on o dide bi awọsanma, kẹ̀kẹ rẹ̀ yio dabi ìji: ẹṣin rẹ̀ yara jù idì lọ. Egbe ni fun wa! nitori awa di ijẹ.


Kiniun jade wá lati inu pantiri rẹ̀, ati olubajẹ awọn orilẹ-ède dide: o jade kuro ninu ipo rẹ̀ lati sọ ilẹ rẹ di ahoro; ati ilu rẹ di ofo, laini olugbe.


Nitori bayi li Oluwa wi; Wò o, on o fò gẹgẹ bi idi, yio si nà iyẹ rẹ̀ lori Moabu.


Wò o, yio goke wá bi kiniun lati igberaga Jordani si ibugbe okuta; nitori lojiji ni emi o lé wọn jade kuro nibẹ, ati tani ayanfẹ na ti emi o yàn sori rẹ̀, nitori tani dabi emi, tani yio si pè mi ṣe ẹlẹri? ati tani oluṣọ-agutan na, ti yio le duro niwaju mi?


Awọn ti nlepa wa yara jù idì ọrun lọ: nwọn nlepa wa lori oke wọnni, nwọn bà dè wa li aginju.


Si wipe, Bayi ni Oluwa Ọlọrun wi; Idì nla kan, pẹlu apá nla, alapá gigùn, o kún fun iyẹ́; ti o ni àwọ alaràbarà wá si Lebanoni, o si mu ẹka igi Kedari ti o ga julọ.


Ọmọ enia, sọ fun ọmọ-alade Tire pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Nitori ti ọkàn rẹ gbe soke, ati ti iwọ si wipe, Ọlọrun li emi, emi joko ni ibujoko Ọlọrun, larin okun; ṣugbọn enia ni iwọ, iwọ kì isi ṣe Ọlọrun, bi o tilẹ gbe ọkàn rẹ soke bi ọkàn Ọlọrun.


Iwọ ha le sọ sibẹ niwaju ẹni ti npa ọ, pe, Emi li Ọlọrun? ṣugbọn enia ni iwọ, o kì yio si jẹ Ọlọrun, lọwọ ẹniti npa ọ.


Ati nibikibi ti ọmọ enia wà, ẹranko igbẹ ati ẹiyẹ oju-ọrun li o si fi le ọ lọwọ, o si ti fi ọ ṣe alakoso lori gbogbo wọn. Iwọ li ori wura yi.


Lakoko kanna oye mi pada tọ̀ mi wá; ati niti ogo ijọba mi, ọlá ati ogo didan mi si pada wá sọdọ mi: awọn ìgbimọ ati awọn ijoye mi si ṣafẹri mi; a si fi ẹsẹ mi mulẹ ninu ijọba mi, emi si ni ọlanla agbara jù ti iṣaju lọ.


Bi o ṣe ti awọn ẹranko iyokù ni, a ti gba agbara wọn kuro: nitori a ti yàn akokò ati ìgba fun wọn bi olukulùku yio ti pẹ tó.


Sa si kiyesi, ẹranko miran, ekeji, ti o dabi ẹranko beari, o si gbé ara rẹ̀ soke li apakan, o si ni egungun-ìha mẹta lẹnu rẹ̀ larin ehin rẹ̀: nwọn si wi fun u bayi pe, Dide ki o si jẹ ẹran pipọ.


Nitori ibikibi ti oku ba gbé wà, ibẹ̀ li awọn igúnnugún ikojọ pọ̀ si.


OLUWA yio gbé orilẹ-ède kan dide si ọ lati ọ̀na jijìn, lati opin ilẹ wa bi idì ti ifò; orilẹ-ède ti iwọ ki yio gbọ́ ède rẹ̀;


Ẹranko ti mo ri na si dabi ẹkùn, ẹsẹ rẹ̀ si dabi ti beari, ẹnu rẹ̀ si dabi ti kiniun: dragoni na si fun u li agbara rẹ̀, ati itẹ rẹ̀, ati ọlá nla.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan