Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 7:25 - Bibeli Mimọ

25 On o si ma sọ̀rọ nla si Ọga-ogo, yio si da awọn enia-mimọ́ ti Ọga-ogo lagara, yio si rò lati yi akokò ati ofin pada; a o si fi wọn le e lọwọ titi fi di igba akokò kan, ati awọn akokò, ati idaji akokò.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

25 Yóo sọ̀rọ̀ òdì sí Ẹni Gíga Jùlọ, yóo sì dá àwọn eniyan mímọ́, ti Ẹni Gíga Jùlọ lágara. Yóo gbìyànjú láti yí àkókò ati òfin pada. A óo sì fi wọ́n lé e lọ́wọ́ fún ọdún mẹta ati ààbọ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

25 Yóò sọ̀rọ̀ odi sí Ọ̀gá-ògo, yóò sì pọ́n ẹni mímọ́ lójú, yóò sì gbèrò láti yí ìgbà àti òfin padà. A ó fi àwọn ẹni mímọ́ lé e lọ́wọ́ fún ìgbà díẹ̀, ní ọdún méjì àti ààbọ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 7:25
36 Iomraidhean Croise  

Tani iwọ kẹgàn ti o si sọ̀rọ buburu si? tani iwọ si gbe oju rẹ ga si, ti o si gbe oju rẹ soke gangan? si Ẹni-Mimọ́ Israeli ni.


Nigbana ni yio pada lọ si ilẹ ontikararẹ̀ ti on ti ọrọ̀ pupọ: ọkàn rẹ̀ yio si lodi si majẹmu mimọ́ nì, yio ṣe e, yio si pada lọ si ilẹ ontikararẹ̀.


Emi si gbọ́, ọkunrin na ti o wọ̀ aṣọ àla, ti o duro loju omi odò na, o gbé ọwọ ọtún ati ọwọ òsi rẹ̀ si ọrun, o si fi Ẹniti o wà titi lai nì bura pe, yio jẹ akokò kan, awọn akokò, ati ãbọ akokò; nigbati yio si ti ṣe aṣepe ifunka awọn enia mimọ́, gbogbo nkan wọnyi li a o si pari.


O si nyi ìgba ati akokò pada: o nmu ọba kuro, o si ngbe ọba leke: o si nfi ọgbọ́n fun awọn ọlọgbọ́n, ati ìmọ fun awọn ti o mọ̀ oye:


Nigbana ni Nebukadnessari sunmọ ẹnu-ọ̀na ileru na o dahùn o si wipe, Ṣadraki, Meṣaki, ati Abednego, ẹnyin iranṣẹ Ọlọrun Ọga-ogo, ẹ jade ki ẹ si wá. Nigbana ni Ṣadraki, Meṣaki, ati Abednego, jade lati ãrin iná na wá.


Nipa ọ̀rọ lati ọdọ awọn oluṣọ li ọ̀ran yi, ati aṣẹ nipa ọ̀rọ awọn ẹni mimọ́ nì; nitori ki awọn alàye ki o le mọ̀ pe Ọga-ogo li o nṣe olori ni ijọba enia, on a si fi fun ẹnikẹni ti o wù u, on a si gbé onirẹlẹ julọ leke lori rẹ̀.


O tọ loju mi lati fi àmi ati iṣẹ iyanu ti Ọlọrun, Ọga-ogo, ti ṣe si mi hàn.


Nwọn o le ọ kuro larin enia, ibugbe rẹ yio si wà pẹlu awọn ẹranko igbẹ nwọn o si mu ki iwọ ki o jẹ koriko bi malu, nwọn o si mu ki iri ọrun sẹ̀ si ọ lara, igba meje yio si kọja lori rẹ, titi iwọ o fi mọ̀ pe Ọga-ogo ni iṣe olori ni ijọba enia, on a si fi i fun ẹnikẹni ti o wù u.


A o si le ọ kuro larin enia, ibugbe rẹ yio si wà pẹlu awọn ẹranko igbẹ: nwọn o si mu ọ jẹ koriko bi malu, igba meje yio si kọja lori rẹ, titi iwọ o fi mọ̀ pe, Ọga-ogo ni iṣe olori ninu ijọba enia, on a si fi i fun ẹnikẹni ti o wù u.


Ṣugbọn awọn enia-mimọ́ ti Ọga-ogo julọ yio gbà ijọba, nwọn o si jogun ijọba na lai, ani titi lailai.


Ati niti iwo mẹwa ti o wà li ori rẹ̀, ati omiran na ti o yọ soke, niwaju eyiti mẹta si ṣubu; ani iwo na ti o ni oju, ati ẹnu ti nsọ̀rọ ohun nlanla, eyi ti oju rẹ̀ si koro jù ti awọn ẹgbẹ rẹ̀ lọ.


Mo si kiyesi awọn iwo na, si wò o, iwo kekere miran kan si jade larin wọn, niwaju eyiti a fa mẹta tu ninu awọn iwo iṣaju: si kiyesi i, oju gẹgẹ bi oju enia wà lara iwo yi, ati ẹnu ti nsọ ohun nlanlà.


Ani o gbé ara rẹ̀ ga titi de ọdọ olori awọn ogun na pãpa, a si ti mu ẹbọ ojojumọ kuro lọdọ rẹ̀, a si wó ibujoko ìwa-mimọ́ rẹ̀ lulẹ.


O si wi fun mi pe, titi fi di ọgbọnkanla le ọgọrun ti alẹ ti owurọ: nigbana ni a o si yà ibi-mimọ́ si mimọ́.


Ati lati inu ọkan ninu wọn ni iwo kekere kan ti jade, ti o si di alagbara gidigidi, si iha gusu, ati si iha ila-õrùn, ati si iha ilẹ ogo.


On o si fi idi majẹmu kan mulẹ fun ọ̀pọlọpọ niwọn ọ̀sẹ kan: ati lãrin ọ̀sẹ na ni yio mu ki a dẹkun ẹbọ, ati ọrẹ-ẹbọ, irira isọdahoro yio si duro lori ibi-mimọ́ titi idajọ ti a pinnu yio túdà sori asọnidahoro.


Nwọn yipadà, ṣugbọn kì iṣe si Ọga-ogo: nwọn dàbi ọrun ẹtàn; awọn ọmọ-alade wọn yio tipa idà ṣubu, nitori irúnu ahọn wọn: eyi ni yio ṣe ẹsín wọn ni ilẹ Egipti.


Ẹ máṣe jẹ ki ẹnikẹni tàn nyin jẹ lọnakọna; nitoripe ọjọ na ki yio de, bikoṣepe ìyapa nì ba kọ́ de, ki a si fi ẹni ẹ̀ṣẹ nì hàn, ti iṣe ọmọ ègbé;


Ẹniti nṣòdì, ti o si ngbé ara rẹ̀ ga si gbogbo ohun ti a npè li Ọlọrun, tabi ti a nsin; tobẹ ti o joko ni tẹmpili Ọlọrun, ti o nfi ara rẹ̀ hàn pe Ọlọrun li on.


Nigbana li a ó si fi ẹ̀ṣẹ nì hàn, ẹniti Oluwa yio fi ẽmi ẹnu rẹ̀ pa, ti yio si fi ifihan wíwa rẹ̀ sọ di asan:


A si fi apá iyẹ́ meji ti idì nla na fun obinrin na, pe ki o fò lọ si aginjù, si ipò rẹ̀, nibiti a gbé bọ́ ọ fun akoko kan ati fun awọn akoko, ati fun idaji akoko kuro lọdọ ejò na.


Obinrin na si sá lọ si aginjù, nibiti a gbé ti pèse àye silẹ dè e lati ọwọ́ Ọlọrun wá, pe ki nwọn ki o mã bọ́ ọ nibẹ̀ li ẹgbẹfa ọjọ o le ọgọta.


Nihin ni sũru awọn enia mimọ́ gbé wà: awọn ti npa ofin Ọlọrun ati igbagbọ́ Jesu mọ́.


Nitoriti nwọn ti ta ẹ̀jẹ awọn enia mimọ́ ati ti awọn woli silẹ, iwọ si fi ẹ̀jẹ fun wọn mu; eyiyi li o yẹ wọn.


Mo si ri obinrin na mu ẹ̀jẹ awọn enia mimọ́, ati ẹ̀jẹ awọn ajẹrikú Jesu li amuyo: nigbati mo si ri i, ẹnu yà mi gidigidi.


Ati ninu rẹ̀ li a gbé ri ẹ̀jẹ awọn woli, ati ti awọn enia mimọ́, ati ti gbogbo awọn ti a pa lori ilẹ aiye.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan