Daniẹli 7:22 - Bibeli Mimọ22 Titi Ẹni-àgba ọjọ nì fi de, ti a si fi idalare fun awọn enia-mimọ ti Ọga-ogo; titi akokò si fi de ti awọn enia-mimọ́ jogun ijọba na. Faic an caibideilYoruba Bible22 títí tí Ẹni Ayérayé fi dé, tí ó dá àwọn ẹni mímọ́ ti Ẹni Gíga Jùlọ láre; tí ó sì tó àkókò fún àwọn ẹni mímọ́ láti gba ìjọba. Faic an caibideilBíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní22 títí ẹni ìgbàanì fi dé, ó sì ṣe ìdájọ́ ìdáláre fún àwọn ẹni mímọ́ Ọ̀gá-ògo, àsìkò náà sì dé nígbà tí àwọn ẹni mímọ́ náà jogún ìjọba. Faic an caibideil |
Mo si ri awọn ìtẹ́, nwọn si joko lori wọn, a si fi idajọ fun wọn: mo si ri ọkàn awọn ti a ti bẹ́ lori nitori ẹrí Jesu, ati nitori ọ̀rọ Ọlọrun, ati awọn ti kò si foribalẹ fun ẹranko na, ati fun aworan rẹ̀, tabi ti kò si gbà àmi rẹ̀ ni iwaju wọn ati li ọwọ́ wọn; nwọn si wà lãye, nwọn si jọba pẹlu Kristi li ẹgbẹrun ọdún.