Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 7:16 - Bibeli Mimọ

16 Mo sunmọ ọkan ninu awọn ti o duro lapakan, mo si bi i lere otitọ gbogbo nkan wọnyi. Bẹ̃li o sọ fun mi, o si fi itumọ nkan wọnyi hàn fun mi.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

16 Mo bá súnmọ́ ọ̀kan ninu àwọn tí wọ́n dúró níbẹ̀, mo bèèrè ìtumọ̀ ohun tí mo rí, ó sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀ fún mi, ó ní,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

16 Mo lọ bá ọ̀kan nínú àwọn tí ó dúró níbẹ̀, mo sì bi í léèrè òtítọ́ ìtumọ̀ nǹkan wọ̀nyí. “Ó sọ fún mi, ó sì túmọ̀ àwọn nǹkan wọ̀nyí fún mi:

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 7:16
14 Iomraidhean Croise  

Iṣàn iná nṣẹyọ, o si ntu jade lati iwaju rẹ̀ wá; awọn ẹgbẹ̃gbẹrun nṣe iranṣẹ fun u, ati awọn ẹgbẹgbarun nigba ẹgbarun duro niwaju rẹ̀: awọn onidajọ joko, a si ṣi iwe wọnni silẹ.


Awọn ẹranko nla wọnyi, ti o jẹ mẹrin, li awọn ọba mẹrin ti yio dide li aiye.


Bẹ̃li o si wá sibi ti mo duro: nigbati o si de, ẹ̀ru bà mi, mo si da oju mi bolẹ: ṣugbọn o wi fun mi pe, Kiyesi i, ọmọ enia: nitoripe ti akokò igba ikẹhin ni iran na iṣe.


O mu mi mọ̀, o si mba mi sọ̀rọ wipe, Danieli, mo jade wá nisisiyi lati fi oye fun ọ.


Mo si sọ fun angeli ti o ba mi sọ̀rọ pe, Kini wọnyi? O si da mi lohùn pe, Awọn wọnyi ni iwo ti o ti tú Juda, Israeli, ati Jerusalemu ka.


Si kiyesi i, angeli ti o mba mi sọ̀rọ jade lọ, angeli miran si jade lọ ipade rẹ̀.


Bayi ni Oluwa awọn ọmọ-ogun wi; bi iwọ o ba rìn li ọ̀na mi, bi iwọ o ba si pa aṣẹ mi mọ, iwọ o si ṣe idajọ ile mi pẹlu, iwọ o si pa ãfin mi mọ pẹlu, emi o si fun ọ li àye ati rìn lãrin awọn ti o duro yi.


Ọkan ninu awọn àgba na si wi fun mi pe, Máṣe sọkun: kiyesi i, Kiniun ẹ̀ya Juda, Gbòngbo Dafidi, ti bori lati ṣí iwe na, ati lati tú èdidi rẹ̀ mejẽje.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan