Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 7:13 - Bibeli Mimọ

13 Mo ri ni iran oru, si kiyesi i, ẹnikan bi Ọmọ enia wá pẹlu awọsanma ọrun, o si wá sọdọ Ẹni-Àgba ọjọ na, nwọn si mu u sunmọ iwaju rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

13 “Ninu ìran, lóru, mo rí ẹnìkan tí ó rí bí Ọmọ Eniyan ninu awọsanma, ó lọ sí ọ̀dọ̀ Ẹni Ayérayé náà, ó sì fi ara rẹ̀ hàn níwájú rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

13 “Nínú ìran mi ní òru mo wò, mo rí ẹnìkan tí ó dúró sí iwájú u mi, ó rí bí Ọmọ ènìyàn, ó ń bọ̀ wá nínú àwọsánmọ̀ ọ̀run, ó ń bọ̀ wá sí ọ̀dọ̀ ẹni ìgbàanì, a sì mú u wá sí iwájú rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 7:13
39 Iomraidhean Croise  

Oluwa yio nà ọpá agbara rẹ lati Sioni wá: iwọ jọba larin awọn ọta rẹ.


Bère lọwọ mi, emi o si fi awọn orilẹ-ède fun ọ ni ini rẹ, ati iha opin ilẹ li ọrọ̀-ilẹ rẹ.


Ọlọrun gòke lọ ti on ti ariwo, Oluwa, ti on ti iró ipè.


Wò o, yio goke wá bi kiniun lati igberaga Jordani si ibugbe okuta; nitori lojiji ni emi o lé wọn jade kuro nibẹ, ati tani ayanfẹ na ti emi o yàn sori rẹ̀, nitori tani dabi emi, tani yio si pè mi ṣe ẹlẹri? ati tani oluṣọ-agutan na, ti yio le duro niwaju mi?


Ati lori ofurufu ti o wà lori wọn, aworan itẹ kan wà, bi irí okuta safire: ati loke aworan itẹ na li aworan kan bi ori enia wà.


Li ọjọ awọn ọba wọnyi li Ọlọrun ọrun yio gbe ijọba kan kalẹ, eyi ti a kì yio le parun titi lai: a kì yio si fi ijọba na le orilẹ-ède miran lọwọ, yio si fọ tutu, yio si pa gbogbo ijọba wọnyi run, ṣugbọn on o duro titi lailai.


Bi o ṣe ti awọn ẹranko iyokù ni, a ti gba agbara wọn kuro: nitori a ti yàn akokò ati ìgba fun wọn bi olukulùku yio ti pẹ tó.


Danieli dahùn, o si wipe, Mo ri ni iran mi li oru, si kiyesi i, afẹfẹ mẹrẹrin ọrun njà loju okun nla.


Titi Ẹni-àgba ọjọ nì fi de, ti a si fi idalare fun awọn enia-mimọ ti Ọga-ogo; titi akokò si fi de ti awọn enia-mimọ́ jogun ijọba na.


Mo si wò titi a fi sọ̀ itẹ́ wọnni kalẹ titi Ẹni-àgba ọjọ na fi joko, aṣọ ẹniti o fún gẹgẹ bi ẹ̀gbọn owu, irun ori rẹ̀ si dabi irun agutan ti o mọ́: itẹ rẹ̀ jẹ ọwọ iná, ayika-kẹkẹ rẹ̀ si jẹ jijo iná.


O si ṣe ti emi, ani emi Danieli si ti ri iran na, ti mo si nfẹ imọ̀ idi rẹ̀, si kiyesi i, ẹnikan duro niwaju mi, gẹgẹ bi aworan ọkunrin.


Ọmọ-enia yio rán awọn angẹli rẹ̀, nwọn o si kó gbogbo ohun ti o mu-ni-kọsẹ̀ ni ijọba rẹ̀ kuro, ati awọn ti o ndẹṣẹ.


Nigbana li àmi Ọmọ-enia yio si fi ara hàn li ọrun; nigbana ni gbogbo ẹya aiye yio kãnu, nwọn o si ri Ọmọ-enia ti yio ma ti oju ọrun bọ̀ ti on ti agbara ati ogo nla.


Nigbati Ọmọ-enia yio wá ninu ogo rẹ̀, ati gbogbo awọn angẹli mimọ́ pẹlu rẹ̀, nigbana ni yio joko lori itẹ́ ogo rẹ̀:


Jesu wi fun u pe, Iwọ wi i: ṣugbọn mo wi fun nyin, Lẹhin eyi li ẹnyin o ri Ọmọ-enia ti yio joko li ọwọ́ ọtún agbara, ti yio si ma ti inu awọsanma ọrun wá.


Jesu si wá, o si sọ fun wọn, wipe, Gbogbo agbara li ọrun ati li aiye li a fifun mi.


Jesu si wi fun u pe, Awọn kọ̀lọkọlọ ni ihò, ati awọn ẹiyẹ oju ọrun ni itẹ́; ṣugbọn Ọmọ-enia kò ni ibi ti yio gbé fi ori rẹ̀ le.


Nigbana ni nwọn o si ri Ọmọ-enia ti yio ma ti oju ọrun bọ̀ ti on ti agbara nla ati ogo.


Nigbana ni nwọn o si ri Ọmọ-enia ti yio ma ti oju ọrun bọ̀ ti on ti agbara ati ogo nla.


Njẹ ki ẹ mã ṣọna, ki ẹ si mã gbadura nigbagbogbo, ki ẹ ba le là gbogbo nkan wọnyi ti mbọ̀ wá iṣẹ, ki ẹ si le duro niwaju Ọmọ-enia.


O si bẹ̀rẹ lati Mose ati gbogbo awọn woli wá, o si tumọ̀ nkan fun wọn ninu iwe-mimọ gbogbo nipa ti ara rẹ̀.


Nitorina awọn ijọ enia da a lohùn wipe, Awa gbọ́ ninu ofin pe, Kristi wà titi lailai: iwọ ha ṣe wipe, A kò le ṣaima gbé Ọmọ-enia soke? Tani iṣe Ọmọ-enia yi?


Ko si si ẹniti o gòke re ọrun, bikoṣe ẹniti o ti ọrun sọkalẹ wá, ani Ọmọ-enia ti mbẹ li ọrun.


O si fun u li aṣẹ lati mã ṣe idajọ pẹlu, nitoriti on iṣe Ọmọ-enia.


O si wipe, Wò o, mo ri ọrun ṣí silẹ, ati Ọmọ-enia nduro li ọwọ́ ọtún Ọlọrun.


Nigbana li a ó si gbà awa ti o wà lãye ti o si kù lẹhin soke pẹlu wọn sinu awọsanma, lati pade Oluwa li oju ọrun: bẹ̃li awa ó si ma wà titi lai lọdọ Oluwa.


Ẹnikanṣoṣo ti o ni aikú, ti ngbe inu imọlẹ ti a kò le sunmọ, ẹniti enia kan kò ri rí ti kò si le ri: ẹniti ọla ati agbara titi lai iṣe tirẹ. Amin.


Njẹ niwọn bi awọn ọmọ ti ṣe alabapin ara on ẹ̀jẹ, bẹ̃ gẹgẹ li on pẹlu si ṣe alabapin ninu ọkanna; ki o le ti ipa ikú pa ẹniti o ni agbara ikú run, eyini ni Eṣu;


Nitori Kristi kò wọ̀ ibi mimọ́ ti a fi ọwọ́ ṣe lọ ti iṣe apẹrẹ ti otitọ; ṣugbọn o lọ si ọ̀run pãpã, nisisiyi lati farahan ni iwaju Ọlọrun fun wa:


Ati lãrin awọn ọpá fitila na, ẹnikan ti o dabi Ọmọ enia, ti a wọ̀ li aṣọ ti o kanlẹ̀ de ẹsẹ, ti a si fi àmure wura dì li ẹgbẹ.


Emi li ẹniti o mbẹ lãye, ti o si ti kú; si kiyesi i, emi si mbẹ lãye si i titi lai, Amin; mo si ní kọkọrọ ikú ati ti ipo-oku.


Kiyesi i, o mbọ̀ ninu awọsanma; gbogbo oju ni yio si ri i, ati awọn ti o gún u li ọ̀kọ pẹlu; ati gbogbo orilẹ-ede aiye ni yio si mã pohùnrere ẹkún niwaju rẹ̀. Bẹ̃na ni. Amin.


Mo si wò, si kiyesi i, awọsanma funfun kan, ati lori awọsanma na ẹnikan joko ti o dabi Ọmọ-enia, ti on ti ade wura li ori rẹ̀, ati dòjé mimú li ọwọ́ rẹ̀.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan