Daniẹli 6:8 - Bibeli Mimọ8 Njẹ nisisiyi, ọba, fi aṣẹ na lelẹ, ki o si fi ọwọ rẹ sinu iwe ki o máṣe yipada, gẹgẹ bi ofin awọn ara Media ati Persia, eyi ti a kò gbọdọ pada. Faic an caibideilYoruba Bible8 Nisinsinyii, kabiyesi, ẹ fi ọwọ́ sí òfin yìí, kí ó lè fi ìdí múlẹ̀, gẹ́gẹ́ bí òfin Mede ati Pasia tí kò gbọdọ̀ yipada.” Faic an caibideilBíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní8 Nísinsin yìí, ìwọ ọba, gbé òfin yìí jáde, kí o sì kọ ọ́ sínú ìwé kí a má ba à yí i padà ní ìbámu pẹ̀lú òfin àwọn Media àti Persia, èyí tí kò ní le è parẹ́.” Faic an caibideil |
Nigbana li a pè awọn akọwe ọba ni ọjọ kẹtala, oṣù kini, a si kọwe gẹgẹ bi gbogbo ohun ti Hamani ti pa li aṣẹ fun awọn bãlẹ ọba, ati fun awọn onidajọ ti o njẹ olori gbogbo ìgberiko, ati fun awọn olori olukuluku enia ìgberiko gbogbo, gẹgẹ bi ikọwe rẹ̀, ati fun olukuluku enià gẹgẹ bi ède rẹ̀, li orukọ Ahaswerusi ọba li a kọ ọ, a si fi oruka ọba ṣe edidi rẹ̀.
Nigbana ni nwọn wá, nwọn si wi niwaju ọba niti aṣẹ ọba pe, Kò ṣepe iwọ fi ọwọ sinu iwe pe, ẹnikan ti o ba bère ohunkohun lọwọ Ọlọrun tabi lọwọ enia kan niwọn ọgbọ̀n ọjọ, bikoṣe lọwọ rẹ, ọba, pe a o gbé e sọ sinu iho kiniun? Ọba si dahùn o wipe, Otitọ li ọ̀ran na, gẹgẹ bi ofin awọn ara Media ati Persia, ti a kò gbọdọ pada.