Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 6:6 - Bibeli Mimọ

6 Nigbana ni awọn alakoso ati awọn arẹ bãlẹ wọnyi pejọ pọ̀ lẹsẹkanna lọdọ ọba, nwọn si wi bayi pe ki Dariusi ọba, ki o pẹ́.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

6 Nítorí náà, àwọn alabojuto ati àwọn gomina gbìmọ̀ pọ̀, wọ́n kó ara wọn jọ sọ́dọ̀ ọba, wọ́n wí fún un pé “Dariusi ọba, kí ọba pẹ́,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

6 Nígbà náà ni àwọn alákòóso àti àwọn baálẹ̀ lọ gẹ́gẹ́ bí ikọ̀ sí ọ̀dọ̀ ọba, wọ́n wí pé: “Ìwọ Dariusi ọba, kí o pẹ́!

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 6:6
13 Iomraidhean Croise  

Mo si wi fun ọba pe, Ki ọba ki o pẹ: ẽṣe ti oju mi kì yio fi faro, nigbati ilu, ile iboji awọn baba mi dahoro, ti a si fi iná sun ilẹkun rẹ̀?


Nwọn kó ara wọn jọ, nwọn ba, nwọn kiyesi ìrin mi, nwọn ti nṣọ̀na ọkàn mi.


Ẹnyin o ti ma rọlu enia kan pẹ to? gbogbo nyin li o fẹ pa a: bi ogiri ti o bìwó ati bi ọgbà ti nwó lọ.


Nigbana ni awọn Kaldea wi fun ọba li ede awọn ara Siria pe, Ki ọba ki o pẹ́: rọ́ alá na fun awọn ọmọ-ọdọ rẹ, awa o si fi itumọ̀ na hàn.


Nwọn dahùn, nwọn si wi fun Nebukadnessari ọba, pe, Ki ọba ki o pẹ́.


Nitorina ni ayaba ṣe wọ ile-àse wá, nitori ọ̀ran ọba, ati ti awọn ijoye rẹ̀; ayaba dahùn o si wipe, Ki ọba ki o pẹ́: má ṣe jẹ ki ìro-inu rẹ ki o dãmu rẹ, má si jẹ ki oju rẹ ki o yipada.


Nigbana ni awọn ọkunrin wọnyi rìn wọle, nwọn si ri Danieli ngbadura, o si mbẹbẹ niwaju Ọlọrun rẹ̀.


Nigbana ni Danieli wi fun ọba pe, ki ọba ki o pẹ.


Nigbati a si ti pè e jade, Tertulu bẹ̀rẹ si ifi i sùn wipe, Bi o ti jẹ pe nipasẹ rẹ li awa njẹ alafia pipọ, ati pe nipasẹ itọju rẹ a nṣe atunṣe fun orilẹ yi.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan