Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 6:5 - Bibeli Mimọ

5 Nigbana ni awọn ọkunrin wọnyi wipe, Awa kì yio le ri ẹ̀sùn kan si Danieli bikoṣepe a ba ri i si i nipasẹ ofin Ọlọrun rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

5 Wọ́n sọ fún ara wọn pé, “A kò ní rí ẹ̀sùn kà sí Daniẹli lẹ́sẹ̀, àfi ohun tí ó bá jẹmọ́ òfin Ọlọrun rẹ̀.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

5 Nígbẹ̀yìn ni àwọn ọkùnrin wọ̀nyí sọ wí pé, “Àwa kò ní rí ìdí kankan láti kà ẹ̀ṣẹ̀ sí Daniẹli lọ́rùn, àfi èyí tí ó bá ní í ṣe pẹ̀lú òfin Ọlọ́run rẹ̀.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 6:5
8 Iomraidhean Croise  

Hamani si sọ fun Ahaswerusi ọba pe, awọn enia kan fọn kakiri, nwọn si tuka lãrin awọn enia ni gbogbo ìgberiko ijọba rẹ, ofin wọn si yatọ si ti gbogbo enia; bẹ̃ni nwọn kò si pa ofin ọba mọ́; nitorina kò yẹ fun ọba lati da wọn si.


Ẹni buburu nṣọ olododo, o si nwá ọ̀na lati pa a.


Ki ẹ si mã wá alafia ilu na, nibiti emi ti mu ki a kó nyin lọ ni igbekun, ẹ si mã gbadura si Oluwa fun u: nitori ninu alafia rẹ̀ li ẹnyin o ni alafia.


O si wi fun Dafidi pe, Iwọ ṣe olododo jù mi lọ: nitoripe iwọ ti fi ire san fun mi, emi fi ibi san fun ọ.


Awọn ijoye Filistini si bere wipe, Kini awọn Heberu nṣe nihinyi? Akiṣi si wi fun awọn ijoye Filistini pe, Dafidi kọ yi, iranṣẹ Saulu ọba Israeli, ti o wà lọdọ mi lati ọjọ wọnyi tabi lati ọdun wọnyi, emi ko iti ri iṣiṣe kan li ọwọ́ rẹ̀ lati ọjọ ti o ti de ọdọ mi titi di oni yi.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan