Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 6:3 - Bibeli Mimọ

3 Danieli yi si bori gbogbo awọn alakoso ati arẹ bãlẹ wọnyi, nitoripe ẹmi titayọ wà lara rẹ̀: ọba si ngbiro lati fi i ṣe olori gbogbo ijọba.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

3 Ṣugbọn Daniẹli tún ta gbogbo àwọn alámòójútó ati gomina náà yọ nítorí ẹ̀mí tí kò lẹ́gbẹ́ tí ó wà ninu rẹ̀. Ọba sì ń gbèrò láti fi gbogbo ọ̀rọ̀ ìjọba lé e lọ́wọ́.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

3 Daniẹli ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ láàrín àwọn alákòóso àti àwọn baálẹ̀ nítorí ẹ̀mí tí ó tayọ wà lára rẹ̀ dé bi pé ọba sì ń gbèrò láti fi ṣe olórí i gbogbo ìjọba.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 6:3
12 Iomraidhean Croise  

Ẹ kiyesi ara nyin, ki ẹnyin ki o má jafara lati ṣe eyi: ẽṣe ti ìbajẹ yio fi ma dàgba si ipalara awọn ọba?


Mo si fun Hanani arakunrin mi, ati Hananiah ijòye ãfin, li aṣẹ lori Jerusalemu: nitori olododo enia li o ṣe, o si bẹ̀ru Ọlọrun jù enia pupọ lọ.


Nitori Mordekai ara Juda li o ṣe igbakeji Ahaswerusi ọba, o si tobi ninu awọn Ju, o si ṣe itẹwọgbà lọdọ ọ̀pọlọpọ ninu awọn arakunrin rẹ̀, o nwá ire awọn enia rẹ̀, o si nsọ̀rọ alafia fun gbogbo awọn iru-ọmọ rẹ̀.


Ẹniti o ni ìmọ, a ṣẹ́ ọ̀rọ rẹ̀ kù: ọlọkàn tutu si li amoye enia.


Iwọ ri enia ti o nfi aiṣemẹlẹ ṣe iṣẹ rẹ̀? on o duro niwaju awọn ọba; on kì yio duro niwaju awọn enia lasan.


Nigbana ni mo ri pe ọgbọ́n ta wère yọ, to iwọn bi imọlẹ ti ta òkunkun yọ.


Niwọnbi ẹmi titayọ ati ìmọ, ati oye itumọ alá, oye ati já alọ́, ati lati ma ṣe itumọ ọ̀rọ ti o diju, gbogbo wọnyi li a ri lara Danieli na, ẹniti ọba fi orukọ Belteṣassari fun, njẹ nisisiyi jẹ ki a pè Danieli wá, on o si fi itumọ rẹ̀ hàn.


Emi ti gburo rẹ pe ẹmi Ọlọrun mbẹ lara rẹ, ati pe, a ri imọlẹ, ati oye, ati ọgbọ́n titayọ lara rẹ,


Ọba si kigbe kikan pe, ki a mu awọn amoye, awọn Kaldea, ati awọn alafọṣẹ wá. Ọba dahùn o si wi fun awọn ọlọgbọ́n Babeli, pe, Ẹnikan ti o ba kà iwe yi, ti o ba si fi itumọ rẹ̀ hàn fun mi, on li a o fi aṣọ ododó wọ̀, a o si fi ẹ̀wọn wura kọ̀ ọ li ọrùn, on o si jẹ ẹkẹta olori ni ijọba.


Ni ipilẹṣẹ ẹ̀bẹ rẹ li ọ̀rọ ti jade wá, emi si wá lati fi hàn fun ọ, nitoriti iwọ iṣe ayanfẹ gidigidi: nitorina, moye ọ̀ran na, ki o si kiyesi iran na.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan