Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 5:8 - Bibeli Mimọ

8 Nigbana ni gbogbo awọn amoye ọba wọle; ṣugbọn nwọn kò le kà iwe na, nwọn kò si le fi itumọ rẹ̀ hàn fun ọba.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

8 Gbogbo àwọn amòye ọba wá, wọn kò lè ka àwọn àkọsílẹ̀ náà, wọn kò sì lè sọ ìtumọ̀ rẹ̀ fún ọba.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

8 Nígbà náà ni gbogbo àwọn amòye ọba wọ ilé, ṣùgbọ́n, wọn kò le è ka àkọsílẹ̀ náà tàbí sọ ìtumọ̀ rẹ̀ fún ọba.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 5:8
9 Iomraidhean Croise  

O si ṣe li owurọ̀, ti ọkàn rẹ̀ kò lelẹ; o si ranṣẹ o si pè gbogbo awọn amoye Egipti, ati gbogbo awọn ọ̀mọran ibẹ̀ wá: Farao si rọ́ alá rẹ̀ fun wọn: ṣugbọn kò sí ẹnikan ti o le tumọ wọn fun Farao.


Ṣugbọn nkan meji wọnyi ni yio deba ọ li ojiji, li ọjọ kan, òfo ọmọ ati opo: nwọn o ba ọ perepere, nitori ọpọlọpọ iṣẹ́ ajẹ́ rẹ, ati nitori ọpọlọpọ iṣẹ́ afọṣẹ rẹ.


Ida lori awọn ara Kaldea, li Oluwa wi, ati lori awọn olugbe Babeli, ati lori awọn ijoye rẹ̀, ati lori awọn ọlọgbọn rẹ̀?


Danieli si dahùn niwaju ọba, o si wipe, Aṣiri ti ọba mbère, awọn ọlọgbọ́n, awọn oṣó, awọn amoye, ati awọn alafọṣẹ, kò le fi hàn fun ọba.


Alá yi li emi Nebukadnessari lá, njẹ nisisiyi, iwọ Belteṣassari, sọ itumọ rẹ̀ fun mi, bi gbogbo awọn ọlọgbọ́n ijọba mi kò ti le fi itumọ rẹ̀ hàn fun mi: ṣugbọn iwọ le ṣe e; nitori ẹmi Ọlọrun mimọ́ mbẹ lara rẹ.


Emi Nebukadnessari wà li alafia ni ile mi, mo si ngbilẹ li ãfin mi:


Nigbana ni awọn amoye, ọlọgbọ́n, awọn Kaldea, ati awọn alafọṣẹ wá siwaju mi: emi si rọ́ alá na fun wọn, ṣugbọn nwọn kò le fi ìtumọ rẹ̀ hàn fun mi.


Njẹ nisisiyi, a ti mu awọn amoye, ati awọn ọlọgbọ́n wá siwaju mi, ki nwọn ki o le ka iwe yi, ati lati fi itumọ rẹ̀ hàn fun mi: ṣugbọn nwọn kò le fi itumọ ọ̀ran na hàn:


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan