Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 5:6 - Bibeli Mimọ

6 Nigbana ni oju ọba yipada, ìro-inu rẹ̀ si dãmu rẹ̀, tobẹ̃ ti amure ẹ̀gbẹ rẹ̀ tu, ẽkunsẹ̀ rẹ̀ mejeji si nlù ara wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

6 Ojú ọba yipada, ẹ̀rù bà á, ara rẹ̀ ń gbọ̀n, orúnkún rẹ̀ sì ń lu ara wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

6 Ojú ọba sì yí padà, ẹ̀rù sì bà á, tó bẹ́ẹ̀ tí orúnkún ẹsẹ̀ rẹ̀ méjèèjì rẹ̀ fi ń gbá ara wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 5:6
21 Iomraidhean Croise  

A tú mi danu bi omi, gbogbo egungun mi si yẹ̀ lori ike: ọkàn mi dabi ida; o yọ́ larin inu mi.


Jẹ ki oju wọn ki o ṣú, ki nwọn ki o má riran, ki o si ma mu ẹgbẹ́ wọn gbọn nigbagbogbo.


Ẹ mu ọwọ́ ailera le, ẹ si mu ẽkun ailera lokun.


Kò si ẹniti yio rẹ̀, tabi ti yio kọsẹ ninu wọn, kò si ẹniti yio tõgbe tabi ti yio sùn: bẹ̃ni amùre ẹgbẹ wọn kì yio tu, bẹ̃ni okùn bàta wọn kì yio ja.


Ọba Babeli ti gbọ́ iró wọn, ọwọ rẹ̀ si rọ: ẹ̀dun dì i mu, ati irora gẹgẹ bi obinrin ti nrọbi.


Yio si ṣe, nigbati nwọn ba wi fun ọ pe, Ẽṣe ti iwọ fi nkerora? iwọ o dahùn wipe, Nitori ihìn na; nitoripe o de: olukuluku ọkàn ni yio yọ́, gbogbo ọwọ́ ni yio si ṣe ailokun, olukuluku ẹmi yio si dakú, gbogbo ẽkún ni yio ṣe ailagbara bi omi: kiyesi i, o de, a o si mu u ṣẹ, ni Oluwa Ọlọrun wi.


Gbogbo ọwọ́ ni yio rọ, gbogbo ẽkun ni yio si di ailera bi omi.


ATI li ọdun keji ijọba Nebukadnessari, Nebukadnessari lá alá nipa eyi ti ọkàn rẹ̀ kò fi le ilẹ ninu rẹ̀, ti orun si dá loju rẹ̀.


Nigbana ni Nebukadnessari kún fun ibinu, àwọ oju rẹ̀ si yipada si Ṣadraki, Meṣaki, ati Abednego: o dahùn, o si paṣẹ pe, ki nwọn ki o da iná ileru na ki õru rẹ̀ gboná niwọn igba meje jù bi a ti imu u gboná ri lọ.


Nigbana ni Danieli, ẹniti a npè ni Belteṣassari wà ni ìwariri niwọn wakati kan, ìro-inu rẹ̀ si dãmu rẹ̀. Ọba si dahùn wipe, Belteṣassari, máṣe jẹ ki alá na, tabi itumọ rẹ̀ ki o dãmu rẹ̀. Belteṣassari si dahùn wipe, oluwa mi! ti awọn ẹniti o korira rẹ li alá yi, ki itumọ rẹ̀ ki o si jẹ ti awọn ọta rẹ.


Mo si lá alá kan ti o dẹ̀ruba mi, ati ìro ọkàn mi lori akete mi, ati iran ori mi dãmu mi.


Ni wakati kanna ni awọn ika ọwọ enia kan jade wá, a si kọwe sara ẹfun ogiri niwaju ọpa-fitila li ãfin ọba: ọba si ri ọwọ ti o kọwe na.


Titi de ihinyi li opin ọ̀ran na. Bi o ṣe ti emi Danieli ni, igbero inu mi dãmu mi gidigidi, oju mi si yipada lori mi: ṣugbọn mo pa ọran na mọ́ li ọkàn mi.


On ti sòfo, o ti di asan, o si di ahoro: aiyà si yọ́, ẽkún nlù ara wọn, irora pupọ̀ si wà ninu gbogbo ẹgbẹ́, ati oju gbogbo wọn si kó dudu jọ.


Nitorina ẹ na ọwọ́ ti o rọ, ati ẽkun ailera;


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan