Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 5:16 - Bibeli Mimọ

16 Emi si gburo rẹ pe, iwọ le ṣe itumọ, iwọ si le tu ọ̀rọ ti o diju: njẹ nisisiyi, bi iwọ ba le ka iwe na, ti iwọ ba si le fi itumọ rẹ̀ hàn fun mi, a o wọ̀ ọ li aṣọ ododó, a o si fi ẹ̀wọn wura kọ́ ọ lọrun, a o si fi ọ jẹ olori ẹkẹta ni ijọba.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

16 Mo ti gbọ́ nípa rẹ pé o lè túmọ̀ ohun ìjìnlẹ̀, o sì lè yanjú ọ̀rọ̀ tí ó bá díjú; nisinsinyii, bí o bá lè ka àkọsílẹ̀ yìí, kí o sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀ fún mi, wọn óo wọ̀ ọ́ ní aṣọ elése àlùkò, wọn óo sì fi ẹ̀gbà wúrà sí ọ lọ́rùn, o óo sì wà ní ipò kẹta sí ọba ní ìjọba mi.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

16 Ṣùgbọ́n mo ti gbọ́ wí pé, ìwọ lè sọ ìtumọ̀, àti wí pé o lè yanjú àwọn ìṣòro tó lágbára. Tí o bá lè ka àkọsílẹ̀ ìwé yìí kí o sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀, a ó fi aṣọ elése àlùkò wọ̀ ọ́ pẹ̀lú ẹ̀gbà wúrà ni a ó fi sí ọ lọ́rùn, a ó sì fi ọ́ ṣe olórí kẹta ní ìjọba mi.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 5:16
9 Iomraidhean Croise  

Nwọn si wi fun u pe, Awa lá alá, kò si sí onitumọ̀ rẹ̀. Josefu si wi fun wọn pe, Ti Ọlọrun ki itumọ̀ iṣe ndan? emi bẹ̀ nyin, ẹ rọ́ wọn fun mi.


Farao sí wi fun Josefu pe, Emi lá alá, kò si si ẹnikan ti o le tumọ̀ rẹ̀: emi si gburó rẹ pe, bi iwọ ba gbọ́ alá, iwọ le tumọ̀ rẹ̀.


Farao si bọ́ oruka ọwọ́ rẹ̀ kuro, o si fi bọ̀ Josefu li ọwọ́, o si wọ̀ ọ li aṣọ ọ̀gbọ daradara, o si fi ẹ̀wọn wurà si i li ọrùn;


Nigbana li ọba sọ Danieli di ẹni-nla, o si fun u li ẹ̀bun nla pupọ, o si fi i jẹ olori gbogbo igberiko Babeli, ati olori onitọju gbogbo awọn ọlọgbọ́n Babeli.


Ṣugbọn bi ẹnyin ba fi alá na hàn, ati itumọ̀ rẹ̀ pẹlu, ẹnyin o gba ẹ̀bun ati ọrẹ ati ọlá nla li ọwọ mi: nitorina, ẹ fi alá na hàn fun mi, ati itumọ̀ rẹ̀ pẹlu.


Nigbana ni Belṣassari paṣẹ, nwọn si wọ̀ Danieli li aṣọ ododó, a si fi ẹ̀wọn wura kọ́ ọ lọrun, a si ṣe ikede niwaju rẹ̀ pe, ki a fi i ṣe olori ẹkẹta ni ijọba.


Ọba si kigbe kikan pe, ki a mu awọn amoye, awọn Kaldea, ati awọn alafọṣẹ wá. Ọba dahùn o si wi fun awọn ọlọgbọ́n Babeli, pe, Ẹnikan ti o ba kà iwe yi, ti o ba si fi itumọ rẹ̀ hàn fun mi, on li a o fi aṣọ ododó wọ̀, a o si fi ẹ̀wọn wura kọ̀ ọ li ọrùn, on o si jẹ ẹkẹta olori ni ijọba.


Ati lori awọn wọnyi ni alakoso mẹta: Danieli si jẹ ọkan ninu wọn: ki awọn arẹ bãlẹ ki o le ma jiyin fun wọn, ki ọba ki o má ṣe ni ipalara.


Nigbati Simoni ri pe nipa gbigbe ọwọ́ leni li a nti ọwọ́ awọn aposteli fi Ẹmí Mimọ́ funni, o fi owo lọ̀ wọn.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan