Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 5:10 - Bibeli Mimọ

10 Nitorina ni ayaba ṣe wọ ile-àse wá, nitori ọ̀ran ọba, ati ti awọn ijoye rẹ̀; ayaba dahùn o si wipe, Ki ọba ki o pẹ́: má ṣe jẹ ki ìro-inu rẹ ki o dãmu rẹ, má si jẹ ki oju rẹ ki o yipada.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

10 Nígbà tí ayaba gbọ́ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí ọba ati àwọn ìjòyè rẹ̀, ó wọ inú gbọ̀ngàn àsè náà, ó sọ fún ọba pé, “Kabiyesi, kí ọba kí ó pẹ́, má jẹ́ kí ọ̀rọ̀ yìí dààmú rẹ tabi kí ó mú kí ojú rẹ fàro.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

10 Nígbà tí ayaba gbọ́ ohùn ọba àti àwọn ọlọ́lá rẹ̀, ó wá ilé àsè wá. Ó wí pé, “Kí ọba kí ó pẹ́! Má ṣe jẹ́ kí inú rẹ bàjẹ́, má sì ṣe jẹ́ kí ojú u rẹ fàro.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 5:10
10 Iomraidhean Croise  

Batṣeba si foribalẹ, o si bọ̀wọ fun ọba, o si wipe, Ki oluwa mi, Dafidi ọba ki o pẹ titi lai.


Ẹnyin ni onihumọ eke, oniṣegun lasan ni gbogbo nyin.


E ha ti ṣe ti ẹnyin fi ntù mi ninu lasan! bi o ṣepe ni idahùn nyin eké kù nibẹ.


Nigbana ni awọn Kaldea wi fun ọba li ede awọn ara Siria pe, Ki ọba ki o pẹ́: rọ́ alá na fun awọn ọmọ-ọdọ rẹ, awa o si fi itumọ̀ na hàn.


Nwọn dahùn, nwọn si wi fun Nebukadnessari ọba, pe, Ki ọba ki o pẹ́.


Nigbana ni oju ọba yipada, ìro-inu rẹ̀ si dãmu rẹ̀, tobẹ̃ ti amure ẹ̀gbẹ rẹ̀ tu, ẽkunsẹ̀ rẹ̀ mejeji si nlù ara wọn.


Nigbana ni Danieli wi fun ọba pe, ki ọba ki o pẹ.


Nigbana ni awọn alakoso ati awọn arẹ bãlẹ wọnyi pejọ pọ̀ lẹsẹkanna lọdọ ọba, nwọn si wi bayi pe ki Dariusi ọba, ki o pẹ́.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan