Daniẹli 4:26 - Bibeli Mimọ26 Ati gẹgẹ bi nwọn si ti paṣẹ pe ki nwọn ki o fi kukute gbòngbo igi na silẹ, ijọba rẹ yio jẹ tirẹ, lẹhin igbati o ba ti mọ̀ pe, ọrun ni iṣe olori. Faic an caibideilYoruba Bible26 Olùṣọ́ náà pàṣẹ pé kí á fi gbòǹgbò igi náà sílẹ̀ ninu ilẹ̀; ìtumọ̀ rẹ̀ ni pé, dájúdájú, o óo tún pada wá jọba, nígbà tí o bá gbà pé Ọlọrun ni ọba gbogbo ayé. Faic an caibideilBíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní26 Bí wọ́n ṣe pàṣẹ pé kí wọn fi kùkùté àti gbòǹgbò igi náà sílẹ̀, èyí túmọ̀ sí wí pé a ó dá ìjọba rẹ padà fún ọ lẹ́yìn ìgbà tí o bá ti mọ̀ wí pé, Ọ̀run jẹ ọba. Faic an caibideil |
Ati gẹgẹ bi ọba si ti ri oluṣọ́ kan ani ẹni mimọ́ ti o sọkalẹ lati ọrun wá, ti o si wipe, Ke igi na lulẹ, ki o si pa a run: ṣugbọn fi kukute gbòngbo rẹ̀ silẹ lãye, ani ti on ti ìde irin ati ti idẹ, ninu koriko tutu igbẹ; ki a si jẹ ki ìri ọrun sẹ̀ si i lara, ki ipin rẹ̀ si wà pẹlu awọn ẹranko igbẹ, titi ìgba meje yio fi kọja lori rẹ̀,