Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 4:25 - Bibeli Mimọ

25 Nwọn o le ọ kuro larin enia, ibugbe rẹ yio si wà pẹlu awọn ẹranko igbẹ nwọn o si mu ki iwọ ki o jẹ koriko bi malu, nwọn o si mu ki iri ọrun sẹ̀ si ọ lara, igba meje yio si kọja lori rẹ, titi iwọ o fi mọ̀ pe Ọga-ogo ni iṣe olori ni ijọba enia, on a si fi i fun ẹnikẹni ti o wù u.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

25 A óo lé ọ jáde kúrò láàrin àwọn eniyan, o óo sì máa bá àwọn ẹranko inú igbó gbé; o óo máa jẹ koríko bíi mààlúù, ìrì yóo sì sẹ̀ sí ọ lára fún ọdún meje, títí tí o óo fi mọ̀ pé Ẹni Gíga Jùlọ ní àṣẹ lórí ìjọba eniyan, ẹni tí ó bá wù ú níí sì í gbé e lé lọ́wọ́.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

25 A ó lé ọ jáde kúrò láàrín ènìyàn, ìwọ yóò sì máa gbé láàrín ẹranko búburú: ìwọ yóò jẹ koríko bí i màlúù, ìrì ọ̀run yóò sì sẹ̀ sára rẹ. Ìgbà méje yóò sì kọjá lórí rẹ, títí ìwọ yóò fi mọ̀ wí pé Ọ̀gá-ògo ń jẹ ọba lórí ìjọba ènìyàn, ó sì ń fi fún ẹni tí ó bá wù ú.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 4:25
15 Iomraidhean Croise  

Oluwa ti pèse itẹ́ rẹ̀ ninu ọrun; ijọba rẹ̀ li o si bori ohun gbogbo;


Bayi ni nwọn pa ogo wọn dà si àworan malu ti njẹ koriko.


Ṣugbọn Ọlọrun li onidajọ: o sọ ọkan kalẹ, o gbé ẹlomiran leke.


Ki awọn enia ki o le mọ̀ pe iwọ, orukọ ẹni-kanṣoṣo ti ijẹ Jehofah, iwọ li Ọga-ogo lori aiye gbogbo.


Emi ti dá aiye, enia ati ẹranko ti o wà lori ilẹ aiye, nipa agbara nla mi, ati nipa ọwọ ninà mi, emi si fi i fun ẹnikẹni ti o wù mi.


O si nyi ìgba ati akokò pada: o nmu ọba kuro, o si ngbe ọba leke: o si nfi ọgbọ́n fun awọn ọlọgbọ́n, ati ìmọ fun awọn ti o mọ̀ oye:


Iwọ ọba, li ọba awọn ọba: nitori Ọlọrun ọrun ti fi ijọba, agbara, ati ipá, ati ogo fun ọ.


Ọba da Danieli lohùn, o si wipe, Lõtọ ni, pe Ọlọrun nyin li Ọlọrun awọn ọlọrun ati Oluwa awọn ọba, ati olufihàn gbogbo aṣiri, nitori ti iwọ le fi aṣiri yi hàn.


Ki a si pa aiya rẹ̀ da kuro ni ti enia, ki a si fi aiya ẹranko fun u, ki igba meje ki o si kọja lori rẹ̀.


Nipa ọ̀rọ lati ọdọ awọn oluṣọ li ọ̀ran yi, ati aṣẹ nipa ọ̀rọ awọn ẹni mimọ́ nì; nitori ki awọn alàye ki o le mọ̀ pe Ọga-ogo li o nṣe olori ni ijọba enia, on a si fi fun ẹnikẹni ti o wù u, on a si gbé onirẹlẹ julọ leke lori rẹ̀.


O tọ loju mi lati fi àmi ati iṣẹ iyanu ti Ọlọrun, Ọga-ogo, ti ṣe si mi hàn.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan